Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àwọn ti Ààrẹ Tinubu fẹ́ yàn sípò Mínísítà

Aworan awọn ti aarẹ Tinubu fẹ yan sipo Minisita

Ko jẹ iroyin tuntun mọ wi pe aarẹ Bola Tinubu ti forukọ awọn ti yoo baa ṣiṣẹ gẹgẹ bi Minisita ranṣẹ si ile asofin agba Naijiria.

Ọpọ araalu lo ti n gbẹ oungbẹ mimọ awọn ti yoo jijọ ba aarẹ ṣiṣẹ.

LỌjọbọ, aarẹ ile aṣofin agba Godswill Akpabio ka orukọ mejidinlọgbọn si etiigbọ araye lasiko ijoko ile.

O ṣeeṣe ki ẹti ri awọn orukọ wọnyi ṣugbọn bawo lẹṣe mọ awọn ti aarẹ forukọ wọn ranṣẹ yi.

  • Abubakar Momoh
  • Amb Yusuf Maitama Sule
  • Arc Ahmad Dangiwa
  • Barr Hannatu Musawa
  • Chief Uche Nnaji
  • Dr Beta Edu
  • Dr Doris Uzoka
  • David Umahi
  • Ezenwo Nyesom Wike
  • Mohammed Badaru Abubakar
  • Nasir El-Rufai
  • Ekperipe Ekpo
  • Hon. Nkiru Onyejeocha
  • Hon. Olubunmi Tunji-Ojo
  • Hon. Stella Okotete
  • Hon. Uju Kennedy-Ohanenye
  • Bello Mohammed Goronyo
  • Dele Alake
  • Lateef Fagbemi
  • Mohammed Idris
  • Olawale Edun
  • Waheed Adebayo Adelabu
  • Mrs Iman Suleiman Ibrahim
  • Prof. Ali Pate
  • Prof. Joseph Utsev
  • Sen. Abubakar Kyari
  • John Enoh
  • Sani Abubakar Sani Danladi

BBC Yoruba ṣe atupalẹ taa si gbe iroyin nipa awọn ti aarẹ yan wọnyii.

Die ree ninu wọn:

Adebayo Adelabu

Aworan Adebayo Adelabu

Agbo ile Oke Oluokun ni adugbo Kudẹti nilu Ibadan ni wọn ti bi Adebayọ Adelabu lọjọ kejidinlọgbọn osu Kẹsan ọdun 1970.

Aderibigbe Adelabu ni orukọ baba rẹ, ti baba rẹ agba, Adegoke Adelabu, ti gbogbo eeyan mọ si ‘Pẹnkẹlẹmẹsi’ nigba aye rẹ, si jẹ gbaju-gbaja agba oselu nilẹ Ibadan.

Yatọ si pe gbaju-gbaja olokoowo ni Adebayọ, to si ni ileesẹ aje kaakiri ilu Ibadan, o tun jẹ eekan ti ko ṣe fi ọwọ rọ sẹyin lagbo oṣelu nipinlẹ Ọyọ.

Ogunjọ oṣu Kẹfa ọdun 2018 lo si yọju sita bii oloselu lasiko to fi erongba rẹ han nileesẹ ẹgbe oṣelu APC lati dije ninu ibo abẹle ẹgbẹ naa fun ipo gomina ipinlẹ Ọyọ.

Adebayọ jawe olubori ninu ibo abẹle ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọyọ amọ o fidi rẹmi ninu idibo to waye.

O pada ni ọdun 2023 labẹ asia ẹgbẹ APC ṣugbọn ko ribi gba tikẹẹti ẹgbẹ nitori pe o fidirẹmi lọwọ Teslim Folarin.

O tẹsiwaju lọ gba tikẹẹti oludije labẹ asia ẹgbẹ Accord ṣugbọn ko rọwọ mu ninu idibo.

O ṣeeṣe ki iyansipo minisita yi jẹ gba ma binu lẹyin toi padanu tikẹẹti ẹgbẹ APC.

Nyesom Wike

Aworan Nyesom Wike

Oríṣun àwòrán, GovernorNyesomEzenwoWikeCON

Odu ni Nyesom Wike jẹ lagbo oṣelu Naijriia kii ṣe aimọ.

O jẹ Gomina tẹlẹ ri to si lo ọdun mẹjọ lori ipo nipinlẹ Rivers.

Ogbontarigi oloṣelu yi jẹ ọkan lara awọn eekan ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ti a ko si tii gbọ pe o kuro ninu ẹgbẹ naa titi di igba ti wọn fikede rẹ gẹgẹ bi Minisita.

Nyesom Wike ti fi igba kan dipo Commissioner mu nipinlẹ Rivers ṣaaju ki ijọba Aarẹ tẹlẹ Goodluck Jonathan to yan sipo Minisita feto ẹkọ.

Iyansipo Minisita Nyesom Wike yi jẹ eleyi ti yoo lapa lagbo oṣelu nitori ipo to dimu ninu ẹgbẹ rẹ,iyẹn Peoples Democratic Party.

Ko daju boya yoo yi jẹ ọmọ ẹgbẹ PDP tabi yoo si fi ẹgbẹ naa silẹ lọ si APC nitori pe o gba ipo Minisita labẹ wọn.

Lọpọ igba lo ti n tẹnumọ wi pe oun ko le kuro ni PDP lọ si APC.

O ba ọrọ naa debi pe o ṣapejuwe ẹgbẹ APC gẹgẹ bi ẹgbẹ to ni aisan jejere.

Lọpọ igba Minisita a maa jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu ijọba to yan si ipo.

Dr Betta Edu

Aworan Dr Betta Edu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Dr Betta Edu

Olori awọn obinrin ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ni Dr Betta Edu jẹ lọwọlọwọ bayii.

Ṣaaju ko to di ipo yi mu,wọn fi jẹ Kọmiṣana feto ilera labẹ ijọba Gomina Ben Ayade ni ipinlẹ Cross River.

Bakan naa lo ti jẹ alaga fẹgbẹ awọn kọmiṣana ilera jake jado Naijiria.

A ko tii mọ ọjọ ori gbogbo awọn iyoku ti wọn yan sipo Minisita ṣugbọn yoo wa lara awọn ti ọjọ ori wọn kere julọ lẹni ọdun mẹrindinlogoji.

Oun ṣi ni olori awọn obinrin ẹgbẹ oṣelu APC ti ọjọ ori rẹ kere julọ.

Nasir El Rufai

Aworan Nasir El Rufai

Oríṣun àwòrán, nasirelrufai

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gomina tẹlẹ ri, Minisita tẹlẹ ri fun olu ilẹ wa Abuja,bi eeyan ba n sọrọ oloṣelu to jẹ ilumọọka, ọkan ni Nasir El Rufai jẹ.

Eekan lo si jẹ ninu ẹgbẹ oṣelu AllProgressives Congress,APC.

Ninu awọn to fi taratara kopa ninu ipolongo Aarẹ Bola Tinubu lariwa Naijiria si ni El Rufai wa.

Yala to ba n sọrọ tabi to ba n hu iwa, ko fẹẹ si igba ti awuyewuye kii tẹle Nasir El Rufai.

Ki wọn to kede orukọ rẹ ninu awọn ti aarẹ fẹ yyan sipo yi, El Rufai a maa sọ pe oun ti ṣe e to atipe oun fẹ lọ sinmi lẹyin ọpọ ọdun ni ijọba.

Minisita FCT lo jẹ ti okiki rẹ fi kan kaakiri Naijiria nitori atunto ati iyipada to mu ba olu ilu Naijiria labẹ ijọba Olusegun Obasanjo.

Nigba to jẹ Gomina ni Kaduna awọn alatilẹyin rẹ sọ pe o ṣiṣẹ daada nipa idagbasokle ipinlẹ rẹ amọ awọn alatako ni o ku diẹ kaato nibi ọrọ ẹlẹyamẹya ati aabo to mẹhẹ labẹ akoso rẹ.

A ko le sọ ipo ti aarẹ yoo yan El Rufai si ṣugbọn ohun to daju ni pe awọn ọmọ Naijiria yoo ri ọpọ ọrọ s lori rẹ nigba to ba bẹrẹ iṣẹ.