Ṣé lóòtọ́ọ́ ni pé Bayo Adelabu juwọ́ sílẹ̀ fún Teslim Folarin láti díje gómìnà l‘Oyo?

Aworan Adelabu ati Folarin

Oríṣun àwòrán, Others

Laipẹ yii ni iroyin kan jade sita pe oludije fun ipo gomina fẹgbẹ oselu Accord Party, Oloye Adebayo Adelabu ti juwọ silẹ, ti ko si dije mọ.

Iroyin naa lo gbalẹ kan pe Adelabu lo ti yẹba kuro gẹgẹ bi oludije, to si fara mọ idije dupo oludije fẹgbẹ oselu APC, Oloye Teslim Kolawole Folarin.

Amọ iroyin miran to n tẹ BBC Yoruba lọwọ ti wa sẹ lori iroyin naa, to si ni ẹbu ati eke iroyin ni.

Iroyin Ofege ni APC n gbe kiri, mo si n dije fun ipo gomina l‘Oyo - Adelabu

Nibayi Oludije sipo gomina fẹgbẹ oṣelu Accord nipinlẹ Oyo, Adebayo Adelabu ti wa pariwo sita pe oun ko juwọ silẹ fun oludije ẹgbẹ oṣelu miran nipinlẹ Oyo.

Adelabu, to jẹ igbakeji gomina tẹlẹ fun banki apapọ ilẹ wa, CBN, sọ eleyi ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Adegboyega Adegoke fi lede lọjọ Satide.

O ni irọ nla ni pe oun ti lẹdi apo pọ pẹlu oludije fẹgbẹ oṣelu APC, Teslim Folarin.

Adelabu ni iroyin ofege ni ẹgbẹ APC n gbe kiri lati ṣe akoba fun erongba oun lati di Gomina ipinlẹ Oyo.

Amọ o ni oun mọ pe iroyin ofege yii ko jẹ tuntun fun awọn eeyan ipinlẹ Oyo.

Àkọlé fídíò, Florence Ajimobi: Ọkọ mi fẹ́ ká rántí òun bíi Bàbá ìpínlẹ̀ Oyo tuntun

N ko ṣe ipade kankan pẹlu Folarin, ọgbọn ijapa ni APC n da - Adelabu

Oludije fun ipo gomina naa ni ko si igba kankan ri, ti oun pẹlu oludije fẹgbẹ oṣelu APC ṣe ipade pọ lati juwọ lẹ fun Teslim Folarin.

O salaye pe o da oun loju pe gbogbo ọgbọn ijapa ẹgbẹ APC ko ni wa si imusẹ, ti ko si ni gbe wọn de ibi kankan ninu eto idibo ọdun yii.

“Iroyin ofege kan ti to wa leti pe Oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Teslim Folarin ti bẹrẹ ọgbọn ijapa pe Adebayo Adelabu, oludije sipo gomina ẹgbẹ oṣelu Accord Party, yoo fọwọsowọpọ pẹlu rẹ ninu eto idibo gomina nipinlẹ Oyo.

“A fẹ ki gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Oyo mọ pe ko si nkankan to jọ mọ bẹẹ rara, ti ko si sigba kankan ti Adelabu ṣe ipade pọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu APC.

“Adebayo Adelabu n du ipo yii lati bori ni, ti yoo si di gomina ipinlẹ Oyo.”