Ọwọ́ tẹ ọmọ ilẹ̀ òkèèrè 26 tí wọ́n ń jí epo Nàìjíríà wà, ìgbẹ́jọ́ yóò bẹ̀rẹ̀ láìpẹ́!

Ọmọ ilẹ Òkèèrè mẹrindinlọgbọn yóò fojú bá ilé ẹjọ Nàìjíríà laipẹ, fún ẹ̀sùn jíjí epo rọbi
Ẹbi ati ara awọn awakọ ọkọ oju omi merindinlogun ọmọ orilẹede India ti awọn jagunjagun ori omi orilẹede Naijiria fi panpẹ ọba mu ni wọn ti n daaro awọn eniyan wọn to wa ni atimọle ijọba apapọ orilẹede yii.
Akọroyin ile iṣe BBC ninu ifọrọwerọ pẹlu awọn ẹbi wọn ni akoko ayẹyẹ ọdun yii le fun awọn idile awọn atukọ ọkọ oju omi naa nitori igba akọkọ niyi ti wọn ko ba awọn idile wọn ṣe ajọyọ ọdun.
Awọn awakọ ọkọ oju omi naa ni wọn ti wa ni atimọle orilẹede Naijiria lati Oṣu kọkanla lori ẹsun pe wọn n gbe epo kuro lorilẹede yii lọna aito.
Kí ni ẹsẹ ̀ awọn awakọ oju-omi náà
Awọn mẹrindinlogbọn lo wa ninu ọkọ oju-omi ti ijọba orilẹ-ede yii mu ti awọn mẹrindinlogun jẹ ọmọ orilẹede India,
ti awọn yooku wa lati Poland, Sri Lanka ati Philippines.
Okọ oju-omi wọn MT Heroic Idun ni ijọba orilẹ-ede yii ti gbẹsẹ le titi iwadii yoo fi pari.
Ọkọ oju-omi naa- eyi ti o jẹ ti ile iṣe OSM Maritime Group ti Norway ni o ti kọkọ wa ni atimọle ni Equatorial Guinea ni Oṣu Kẹjọ lẹyin ti orilẹ-ede Naijiria fi ẹsun kan pe o ji epo robi lona aito ni orilẹede yii.
Ọjọ Kẹwa si ọjọ kọkanla, Oṣu Kinni ọdun yii ni o ṣese kí ile ẹjọ orilẹede Naijiria gbo ẹjọ wọn.
Ìrètí wá tí ń pín ìdílé
Lẹyin Oṣu mẹrin ni atimọle awọn idile awakọ oju-omi ilu India ni ireti pe awọn yoo ri awọn ẹbi awọn laipẹ n kere si ni.
Sheethal Milton aya ọkan ninu awọn awakọ ọkọ oju-omi naa so fun BBC pe Ọkọ re ti maa n rin irin ajo
ṣugbọn ko pe tọ eleyii ri papa julọ laiṣe ajọyọ ọdun Keresimesi pẹlu idile rẹ, Ọkọ rẹ Milton Deoth ti jẹ atukọ-oko oju-omi fun bii ogun ọdun .
Sneha Harshvardhan, iyawo Harshvardhan Shouche, ọkan lara awọn awakọ ọkọ oju omi, sọ fun BBC pe bi ọjọ ṣe n gori ọjọ ti osu gori Oṣu ni ireti awọn pin latari ai rí awọn olufe awọn.
Sneha nii awọn ọkọ awọn n je iya aito eleyii ti o n se ipalara fun awọn molebi awọn awakọ ọkọ oju-omi to wa ni atimọle orilẹede Naijiria.













