Brazil ṣẹ̀yẹ ìkẹyìn fún akọni agbábọ́ọ̀lù, Pele bó ṣe wọ káà ilẹ̀ sùn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Níṣe ló dàbí pé orílẹ̀ èdè Brazil ń ṣe àjọ̀dún bí ayẹyẹ ìkẹyìn ṣe wáyé fún akọni agbábọ́ọ̀lù Pele ṣe wọ káà ilẹ̀ sùn.
Ní ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá ọdún 2022 ni Pele, ẹni tí ọ̀pọ̀ gbà pé ó jẹ́ ògbóǹtarigì nínú eré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá dágbére fáyé lẹ́ni ọdún méjìlélọ́gọ́rin.
Ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kejì, oṣù Kìíní ọdún 2023 ní òkú rẹ̀ balẹ̀ sí Santos tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ sì pé síbẹ̀ láti wá ṣẹ̀yẹ ìkẹyìn fún-un kòdá àwọn mìíràn tilẹ̀ sun ibẹ̀ mọ́júmọ́.

Àwọn ènìyàn péjọ síwájú pápá ìṣeré Urbano Caldeira nígbà tí wọ́n ń gbé òkú rẹ̀ kúrò, tí ọ̀pọ̀ wọn sì wọ aṣọ tí wọ́n kọ nọ́mbà mẹ́wàá èyí tí Pele máa ń wọ̀ nígbà ayé rẹ̀.
Inú ọkọ̀ oníná tó máa gbé òkú àwọn èèkàn ìlú ni wọ́n fi gbé òkú Pele láti fi rin ìrìn kìlómítà méje káàkiri Santos gẹ́gẹ́ bí ìṣe.
Gbogbo èèyàn ní Brazil ló fẹ́ máa gbá bọ́ọ̀lù láti kọ́ṣe Pele - àwọn ará ìlú fi èrò wọn hàn lórí ikú Pele

Marcia Simoes tó wà lára àwọn tó lọ wo òkú Pele ní òkú kìí òk;u Brazil nìkan pé ó ṣe pàtàkì fún gbogbo àgbáyé àti àwọn ọ̀dọ́ bákan náà.
Simeos tí òun àti ọmọkùnrin rẹ̀ wà ní òpópónà tí wọ́n ń gbé òkú gbà ní ó jẹ̀ ohu ìwúrí fún òun pé òun jẹ́ ọmọ bíbí Santos.
“Gbogbo èèyàn ní Brazil ló fẹ́ máa gbá bọ́ọ̀lù láti kọ́ṣe Pele” ni ohun tí Thiago Silva sọ fún bbc.
Sandra Gracia ní ti ẹ̀ ní ká ní pé bàbá òun ṣì wà láyé ni bàbá òun náà máa báwọn kópa níbi ayẹyẹ ìkẹyìn náà nítorí bàbá òun jẹ́ ẹni tó fẹ́ràn Pele dójú àmì.
Gracia ní láti ìgbà tí òun ti wà ní ọmọ ọdún mọ́kànlá ni bàbá òun ti máa ń sọ̀tàn fún òun nípa Pele tí òun sì ka ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan nípa rẹ̀.
Yàtọ̀ sí eré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá Pele jẹ́ okùnfà ìsopọ̀ ní Brazil lẹ́ka ètò ọrọ̀ ajé àti òṣèlú àti pé nǹkan tó dára ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ kàn ń sọ nípa rẹ̀.
A ó sọ fún gbogbo orílẹ̀-èdè láti fi orúkọ Pele sọ pápá ìṣeré kọ̀ọ̀kan- Aarẹ FIFA

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹẹgbẹrun eeyan lo ṣe iṣọ-oru mọju, lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun akọni Brazil, Pele, ti wọn tẹ oku rẹ si papa iṣere ẹgbẹ agbabọọlu rẹ tẹlẹ ni Santos.
Aarin gbungbun papa iṣere naa, Urbano Caldeira ni Sao Paulo, ni wọn gbe posi rẹ si, ti awọn olulufẹ bọọlu si to si awọn oju popo lati wọle sibẹ.
Ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2022, lẹni ọdun mejilelọgọrin.
Aago mejila ọsan, ọjọ Iṣẹgun ni wọn o sin oku rẹ.
Aarẹ ajọ FIFA, Gianni Infantino sọ pe awọn yoo sọ fun gbogbo awọn orilẹ-ede l’agbaye lati fi orukọ Pele sọ papa iṣere wọn kan.
Oun naa n kopa nibi eto isin ikẹyin naa.
Ijọba Brazil si ti kede ọjọ mẹta lati fi ṣe ọ̀fọ̀ iku Pele.
Aarẹ tuntun fun Brazil, Luiz Inacio Lula da Silva, yoo rinrinajo lọ si Santos, ilu kan ni Sao Paulo, lati kopa nibi ẹyẹ ikẹyin.
Pele ni agbabọọlu ti ọpọ gbagbọ pe o dara julọ ninu itan bọọlu.
Yatọ si awọn eeyan to pejọ, awọn baalu ẹlikọpita naa n fo yika papa iṣere naa.
Bakan naa ni wọn n tan orin ti Pele kọ lọdun 2006, “Meu Legado”, to tumọ si Ipa Mi, fun awọn eeyan lati ma a gbọ́ lai dawọ duro.


















