Ghana, Morocco,fi òfin de ìrìnàjò láti China lẹ́yìn tí Covid-19 tún búyọ níbẹ̀

Oríṣun àwòrán, gacl
Ijọba orilẹ-ede Ghana ti kede ofin Covid-19 tuntun fun awọn arinrinajo lati China, to ba n wọ orilẹ-ede naa.
Ikede naa waye lẹyin ti ajakalẹ aarun naa tun gbilẹ ni China, eyi to mu ki awọn orilẹ-ede bi UK, US, australia, Canada, ati awọn mii kede ilana tuntun fun awọn ọmọ China.
Awọn alaṣẹ papakọ ọkọ ofurufu ni Ghana, GACL, sọ pe ọjọ kẹfa, oṣu Kinni, ọdun 2023, ni ofin naa yoo bẹrẹ iṣẹ.
Ninu atẹjade ti wọn fi sita, awọn alaṣẹ ni Ghana sọ pe awọn arinrinajo lati China gbọdọ fi esi ayẹwo Covid-19 to fihan pe wọn ko ni aarun naa han. Ko si gbọdọ tii ju wakati mejidinlaadọta lọ lẹyin ti wọn kuro ni China.
Amọ, awọn arinrinajo to ba wọ Ghana, yala ọmọ ilu, alejo tabi awọn to n gbe nibẹ, to si ti gba abẹrẹ ajẹsara wọn pe, ko ni ṣe ayẹwo kankan ki wọn to kuro ni orilẹ-ede ti wọn ti n bọ, tabi wọle si Ghana, ayafi awọn to ba n bọ lati China nikan.
Lara nkan to tun wa ninu atẹjade naa ni pe ileeṣẹ ọkọ ofurufu to ba tapa si ofin tuntun naa, nipa gbigbe eero ti ko gba abẹrẹ pe tabi wọ China lai si esi ayẹwo pe ko ni Covid-19, yoo san ẹgbẹrun mẹta aabọ Dọla, gẹgẹ bi owo itanran.
Bakan naa ni wọn tun sọ pe dandan ni bayii fun awọn arinrinajo lati ma a wọ ibomu .
Ni awọn orilẹ-ede mii bi US, ọjọ karun-un, oṣu Kinni, ni wọn o bẹrẹ ayẹwo ni dandan fun awọn arinrinajo lati China. Ajọ to n mojuto ajakalẹ aarun tun sọ pe awọn ọmọ orilẹ-ede US yoo ni lati tun ero wọn pa nipa irinajo si China, Hong Kong ati Macau.
Ni orilẹ-ede France, ọjọ kinni, oṣu Kinni, ni wọn ti n beere esi ayẹwo Covid-19, wọn si tun n ṣe ayẹwo PCR fun awọn to ba wọ orilẹ-ede naa lati China.
Iru igbesẹ yii naa ni Canada naa n gbe.
Ṣugbọn ni Morocco, to jẹ orilẹ-ede Africa to tun ti gbe ofin Covid-19 mii jade, wọn ni awọn yoo fi ofin de awọn eeyan lati ma wọ Morocco lati China, bẹrẹ lati ọjọ kẹta, oṣu Kinni.
Wọn ni eyi yoo denaa itankalẹ aarun naa lọtun.












