Kò sí ìsinmi, ọjoojúmọ́ là ń ṣiṣẹ́ láti àárọ̀ títí di alẹ́– Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ọmọ-ọ̀dọ̀ ní Qatar ké gbajarè!

Gbogbo ohun to n dan ko ni wura ni ọrọ jẹ fun awọn miran ti wọn n lọ si oke okun lati lọ ṣiṣẹ.
Pupọ ninu wọn to n ṣiṣẹ ọmọ ọdọ sọ iriri wọn ati bi awọn ṣe n ṣiṣẹ lati owuro titi di aṣalẹ lai si iṣinmi.
Awọn oṣiṣẹ ile ọba ni ilẹ Qatar ṣapejuwe bi awọn ṣe n ṣiṣẹ lai si ọjọ kan fun isinmi.
Ajẹku ounjẹ awọn ọga wa ni a ma n jẹ lẹyin ti a ba ṣiṣẹ lati aago 8am si 11pm - Gladys
Akọroyin ileeṣẹ BBC to fi ọrọ wa awọn oṣiṣẹ lẹnu wo ni arabinrin Gladys ti wọn fi orukọ oun bo ni aṣiri sọ iriri rẹ.
Bio tilẹ jẹpe ko le sọrọ ni gbangba lẹyin ti awọn ọga rẹ lọ sun tan, ni o bọ si ori ẹrọ ilewọ rẹ lati ba akọroyin ọhun sọrọ.
O ni aago mẹjọ aarọ si aago mọkanla alẹ ni awọn n fi n tun ile ṣe ni ojoojumọ, ti awọn yoo si ṣe ounjẹ ati lati tọju ọmọ.
Ounjẹ ti awọn ọga rẹ ati mọlẹbi rẹ ba jẹ ku ni awọn ma n jẹ.
Bakan naa lo fi kun pe awọn ko ni ọjọ isinmi kankan lati igba ti oun ti bẹrẹ iṣẹ lati ọṣu mejidinlogun ṣẹyin.

‘’Nise ni ọga mi obinrin maa n pariwo mọ mi ni ojoojumọ’’
Arabinrin Gladys to jẹ ẹni ogoji ọdun ni niṣe ni ọga oun to jẹ obinrin ma n pariwo mọ ounlojoojumọ
Bakan naa ni wọn gba iwe irinna oun dani nitori naa oun ko le sa lọ si ibi kankan.
Amọ pẹlu bi o ṣe buru to naa, Gladys ni inu oun dun wi pe wọn ko ggba foonu ni ọwọ oun.
Bakan naa lo ni wọn ko na oun tabi fi iya jẹ oun bi wọn ṣe n fi iya jẹ awọn ọmọ ọdọ miran ni orilẹede Qatar.
Arabinrin naa ni owo osu oun to jẹ 1,500 rials ni osu to fẹrẹ to ẹgbẹrun lọna igba, eleyii ti oun ma n fi ranṣẹ si ile.
Amọ o fikun un pe oun ko lee fi iṣẹ ọhun silẹ nitori ko si iṣẹ miran fun awọn arinrinajo lati orilẹede miran pẹlu ọjọ ori oun.
Ti oun si fẹ maa fi owo ranṣẹ si ile fun awọn ẹbi oun lati le fi maa tọju ara wọn.
Ife ẹyẹ agbaye ti Qatar gba lalejo lo tu awọn aṣiri nipa igbe aye awọn eniyan nibẹ paapaa awọn arinrinajo to fi mọ awọn to kọ papa iṣere fun wọn.

Kini ẹtọ awọn ọmọ ọdọ?
- Ni orilẹede Qatar, Iwadii ileeṣẹ ijọba Planning and Statistics Authority fihan pe o kere tan awọn ọmọ -ọdọ 160,000 ni wọn n ṣiṣẹ ni Qatar
- Ni ọdun 2017 ni Qatar gbe ofin jade lati ri i pe awọn oṣiṣẹ ko ṣiṣẹ ju wakati mẹwaa.
- Bakan naa ni wọn paṣẹ pe ki wọn fun wọn ni gbedeke owo oṣu wọn,
- Ki won si fun wọn ni aaye lati kuro ni ibi ti wọn ti n ṣiṣẹ ni igba to ba wu wọn.
- Bakan naa ni wọn ti paṣẹ ki wọn ma lo wọn ni ilokulo, ki wọn si maa gba wọn ni aaye lati ṣinmi ni oore koore.












