How to stop snoring: Orin kíkọ́ àti àwọn ìgbésẹ̀ mìí tó le ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dẹ́kun bí o ṣe n han'run

Tọkọtaya lori ibusun

Oríṣun àwòrán, Snoring Solution NG

Ẹni to ba n han'run ṣaba ma n koju ikorira tabi idẹyẹsi, paapa ti wọn ba sun ti ẹni ti kii han'run.

Koda, nkan yii ma n fa ija laarin awọn ololufẹ miran, nitori pe ariwo ti imu ẹni to n han'run le di oorun ẹnikeji lọwọ.

Abi, bawo lẹ ṣe ro pe ọrọ yoo ri, ki eniyan meji sun papọ sinu yara tabi ibusun kan naa, ki ariwo to n jade ni iho imu ẹnikan lara wọn o rinlẹ ju boṣe lọ?

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kilo n fa ki eeyan o ma a han'run?

Ayelujara eto ilera webmd.com ati atẹjade kan lori itakun agbaye BBC sọ pe eeyan ma n han'run nitori pe awọn iṣan to wa ni ọfun ati ọrùn iru ẹni bẹẹ ma n gbọn bi atẹgun ba ṣe n sare gba inu ara wọn kọja.

Idi ti o fi n han'run:

  • Ti imu rẹ ba di
  • Ohunkohun ti ko ba jẹ ki o le mi daadaa lati imu rẹ le mu ki o han'run.
  • Ti o ba fi ẹyin rẹ le lẹ lasiko ti o sun, eyi le mu ki bi o ṣe n han'run tun l'agbara si.
  • O san ki o fi ẹgbẹ ọtun tabi ti osi sun. Bakan naa ni o le fi irọri meji si mẹta ha ẹgbẹ rẹ, ki o ma ba a yi si ẹyin ti oorun ba wọra tan.

Bi imu rẹ ba ṣe ri

Ti ogiri awọn iho imu rẹ ko ba ri bo ṣe yẹ, abala kan le kere si ikeji - awọn onimọ iṣegun oyinbo n pe e ni deviated septum.

Eyi le mu ki o nira fun ọ lati mi daadaa, yoo si mu ki o ma han'run.

Iru nkan bayii naa tun le ṣẹlẹ ti o ba fi imu pa lasiko ijamba. Nitori naa, ba dokita rẹ sọrọ ti o ba n ni iriri yii, iṣẹ abẹ le yanju rẹ.

Àkọlé fídíò, Yemen Water Child: Ọmọdé 44 ni Sọ́jà pa, tí 100 míì sì kú látọwọ́ ohun ìjà olóró

Bi ẹnu rẹ ba ṣe ri

Ti oke ẹnu rẹ (soft palate) ba kere, to si nipọn, o le mu ki aaye ti eemi n gba o kere, ti yoo si mu ki o ma a han'run.

Bakan naa ni ọrọ yoo ri, ti isan kekere to wa ni oke ẹnu ba gun ju bo ṣe yẹ lọ.

O ṣe e ṣe ki wọn o bi ọ mọ awọn nkan yii, ṣugbọn o le buru si ti o ba sanra ju sugbọn iṣẹ abẹ le ṣe atunṣe.

Irọri yii 'Sona pillow' ni wọn ṣe lati fi opin si ki eeyan o ma a han'run

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Irọri yii 'Sona pillow' ni wọn ṣe lati fi opin si ki eeyan o ma a han'run

Aisan Sleep Apnea

Ti o ba n han'ran, o le jẹ apẹẹrẹ aisan alagbara kan ti wọn n pe ni obstructive sleep apnea.

Eyi ma n waye ti eemi ba deede dawọ duro lasiko ti eeyan n sun.

O ti ẹ le mu ki o ma mi gule-gule, tabi ji ọ silẹ loju oorun.

Àkọlé fídíò, Òṣèrè tíátà Muideen Oladapo gbàràdá lórí ètò 'Ṣé o láyà?'

Awọn ami ti aisan yii ma n fihan ni ki ẹnu rẹ o ma a gbẹ, ori fifọ, tabi ki ọfun o ma a dun ọ.

Iwadii ti ẹ tun sọ pe, o ni nkan ṣe pẹlu aisan rọpa-rọsẹ, ifunpa giga, ati aarun ọkan.

Ba dokita rẹ sọrọ, wọn le ṣe iṣẹ abẹ si eyi tabi ki wọn fun ọ ni ẹrọ ti yoo jẹ ki o ma a mi daadaa.

Àkọlé fídíò, SS3 ní mo wà báyìí, mo sì ti gba àmì ẹ̀yẹ̀ púpò nílé-lóko gẹ́gẹ́ bí onílù - Ayansike

Ti ọmọ rẹ ba n han'run

Kii ṣe nkan ti ko wọpọ ki ọmọde ma a han'run lẹkọọkan, paapa to ba n ṣe ọfinkin.

Ṣugbọn nigba mii, o le jẹ apẹẹrẹ aisan ninu ọfun, ẹdọ fooro tabi aisan mii. Nitori naa, ti o ba ṣakiyesi pe ọmọ rẹ n han'run to ba sun, ri i pe o sọ fun dokita ọmọ wẹwẹ.

Àkọlé fídíò, Pottery: Àwọn onímọ̀ nípa amọ̀ wúlò púpọ̀ ju ike àbí irin lọ

Bawo ni o ṣe le dẹkun ki o ma a han'run?

Gẹgẹ bi iwadii kan ti BBC ṣe akọsilẹ rẹ lori ayelujara, awọn nkan yii le ran ọ lọwọ lati dẹkun ki o ma a han'run

Àkọlé fídíò, Bolaji Faleke ni Olùkọ́ tó ń kọ́ wa ní àṣà oge ṣiṣe lórí BBC Yorùbá

Din ọti mimu ku

Ọti mimu ma n mu ki awọn iṣan ara, sinmi ju ti tẹlẹ lọ lasiko ti a ba sun - nitori naa, ọna ti eemi n gba jade nimu rẹ yoo kere si.

Nidi eyi, ma ṣe mu ọti amupara to ba ti to asiko ti o fẹ sun.

Àkọlé fídíò, Èmi nìkàn kọ́ ni mó n ṣe àkójọ orin- Fasoyin

Fi ẹgbẹ sun

Ti o ba fi ẹyin sun, ahọn, ẹrẹkẹ ati ọra to wa ni abẹ agbọn rẹ le di eemi lọwọ, ti yoo si mu ki o han'run.

Awọn eroja bi eyi to wa ninu aworan yii 'Mouth silencer', ma n mu adinku ba bi eeyan ṣe n han'run

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn eroja bi eyi to wa ninu aworan yii 'Mouth silencer', ma n mu adinku ba bi eeyan ṣe n han'run

Ẹrọ to n dena ki o ma a han'run

Oriṣiriṣi ẹrọ lo wa to le fi opin si ki eeyan o ma a han'run. Wọn si n ta wọn ni awọn ile itaja oogun oyinbo.

Iṣẹ ti awọn irin'ṣẹ yii n ṣe ni pe, wọn o jẹ ki imu rẹ ṣi silẹ, to ba jẹ pe imu lo fi n han'run. Ṣugbọn ko ti i si ẹri to l'agbara pe, awọn ẹrọ naa n ṣiṣẹ.

Ti o ba n ṣe ọfinkin, ti imu rẹ si di pa, o ṣe e ṣe ki o han'run. Nitori naa, gbiyanju lati fọn ikun imu rẹ jade, ki o to sun.

Àkọlé fídíò, The9jaboy: Ojú burúkú ni wọ́n fi ń wo ìwé ìrìnnà aláwọ́ ewé Nàìjíríà nílẹ̀ òkèèrè- MCDolly

Mu adinku ba bi o ṣe sanra si

Iwadi BBC fihan pe, ti o ba sanra ju, ọra yoo pọ ni agbọn ati ọrùn rẹ, to si le fun ọna ti eemi n gba jade tabi wọle si ara rẹ, pọ.

Ẹni to n han'run

Oríṣun àwòrán, others

Mimu adinku ba ara sisan ju yoo ran ọ lọwọ lati le ma a mi daadaa, ti yoo si dena ki o ma a han'run.

Bakan naa ni ileeṣẹ eto ilera orilẹ-ede United Kingdom, NHS, sọ pe orin kikọ gẹgẹ bi ere idaraya le fi opin si ki eyan o han'run.

Abọ iwadii kan ti ileeṣẹ eto ilera naa fi sita lori ayelujara sọ pe, iwadii fihan pe awọn orin kikọ ni gbogbo igba gẹgẹ bi ere idaraya, le ṣe awọn to n hna'run ni anfaani tabi mu adinku ba.

Àkọlé fídíò, Debo Adedayo: Agbára wà lọ́wọ́ àwa ọ̀dọ́ lórí ètò ìdìbò 2023- Macaroni