Àwọn oníṣẹ́ ibi tó pa tọkọtaya náà de àwa tí a kọ́kọ́ dé síbẹ̀ mọ́lẹ̀- Ó ṣojú mi
Awọn tọkọ t’iyawo naa pe awọn eeyan fun iranlọwọ
Kii ṣe iroyin tuntun mọ wi pe awọn amookunṣeka ya wọ ile Ọgbẹni Kẹhinde Fatinoye, ẹni ọdun mẹrindinlọgọta (56), ati iyawo rẹ, Olubukọla Fatinoye, ẹni aadọta ọdun (50) l’ọjọ kinni, oṣu kinni, ọdun 2023 ti a wa yii.
Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni iṣẹlẹ ọhun ṣi n jẹ kayeefi nla fun ọpọ awọn to ti gbọ, paapaa awọn mọlẹbi rẹ.

BBC YORUBA mu iroyin naa wa fun un yin wi pe oṣiṣẹ banki apapọ orileede Naijiria, Central Bank of Nigeria (CBN) ni Ọgbẹni Kẹhinde,
koda, wọn ni oun ni alakoso agba fun ẹka ipolowo (Maketing Manager) ni banki ọhun, nigba ti iyawo rẹ,
Arabinrin Olubọla jẹ oṣiṣẹ fasiti ọgbin, Federal University of Agriculture, Abẹokuta (FUNAAB).
Inu ile wọn ti wọn n gbe to wa lagbegbe Ibara GRA, Abẹokuta ni wọn ti lọ ka wọn mọ, ti wọn si ṣeku pa wọn,
ko to di pe wọn dana sun ile naa mọ oku wọn, ni nnkan bi aago kan ku iṣẹju diẹ oru ọjọ naa, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Oríṣun àwòrán, Others
E gbọ ohun ti awọn isẹlẹ naa ṣoju wọn sọ fun BBC:
Lara awọn ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn, ti wọn ba awọn akọroyin sọrọ lori iṣẹlẹ naa jẹ ko ye wa pe ọpọ igba ni Arabinrin Olubukọla pe awọn eeyan fun iranlọwọ lori foonu lakoko ti awọn amookunṣeka naa wọle tọ wọn lọ.
Ẹnikan to lọ fi iṣẹlẹ naa to ọlọpaa leti sọ pe inu ṣọọṣi loun wa, lakoko ti iṣọ-oru n lọ lọwọ, toun si ṣakiyesi pe obinrin oloogbe naa n pe oun lemọlemọ, eyi ti ko ṣẹlẹ ri.
O ni bi ipe naa ṣe n wọle, lo jẹ koun sare kuro ninu ṣọọṣi pẹlu ọkan lara awọn ọmọ wọn, t’awọn si sare lọ sile wọn pẹlu mọto ayọkẹlẹ Hyundai lati lọ mọ ohun to fa ipe pajawiri ọhun.
Ẹni naa ti wọn fi orukọ bo laṣiri ṣalaye pe b’awọn ṣe de inu ọgba ile naa, l’awọn mẹta kan to ko ohun ija oloro dani ra wọn mu, ti wọn si de wọn ni ṣẹkẹṣẹkẹ mọlẹ.
O lawọn ko mọ ohun to n ṣẹlẹ l’oke, nitori ti wọn ko raaye debẹ, ṣugbọn t’awọn pada kofiri pe awọn agbẹbọn amookunṣeka naa n sare nu ẹjẹ awọn tọkọ t’iyawo to wa nilẹ inu yara ti wọn n sun.
Wọn ti sin òku awọn tọkọtaya mejeeji ti awọn oniṣẹ ibi dana sun ni Abeokuta
Bi ẹlẹkun ṣe n sunkun, bẹẹ l’awọn miran n gbera ṣanlẹ nibi ti wọn ti sinku awọn oloogbe mejeeji yii ni itẹku to wa lagbegbe Lantoro niluu Abẹokuta.
Ẹsẹ ko gbero ni ṣọọṣi Christ Anglican Church to wa ni Iporo Ake niluu Abẹokuta, nibi ti wọn ti gbe oku wọn wọ lati ṣe ẹyẹ ikẹhin fun wọn.
Rẹfurẹndi S.K Oyewale to lewaju isin ẹyẹ ikẹhin naa ṣapejuwe awọn oloogbe naa gẹgẹ bi oniwa tutu ti wọn n ran iṣẹ iranṣẹ ijọ naa lọwọ ni gbogbo igba, koda to ni wọn kii fi isin ṣere.
Kini Alufaa ile ijosin sọ nipa awọn mejeeji?
Alufaa yii sọ pe inu ṣọọṣi naa ni wọn ti kuro ko to di pe iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ loru mọjumọ, to si rawọ ẹbẹ s’awọn agbofinro lati tọpinpin iṣẹlẹ ọhun, ki ọwọ le tẹ gbogbo awọn to lọwọ ninu iku naa.
Ara, ọrẹ, ojulumọ atawọn abanikẹdun la gbọ pe wọn wa nibi eto isinku naa lọjọ Aje, Mọnde ana.
Pupọ awọn to wa nibi itẹkuu naa ni wọn n ṣepe rabandẹ rabandẹ f’awọn to ṣiṣẹ buruku naa, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe awọn ti wọn pa yii jẹ gboogi to n ṣe iranlọwọ f’awọn eeyan, paapaa ninu mọlẹbi.
Abimbọla Oyeyẹmi to jẹ agbẹnusọ f’awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun nigba to n sọrọ sọ pe iṣẹlẹ naa ko yatọ si ti agbanipa, to si ni ọga awọn ti paṣẹ pe ki ẹka ileeṣẹ wọn to n ṣe iwadii ọran, iyẹn State Criminal Investigation Department (SCID) tẹsiwaju iwadii, ki ọwọ le tẹ awọn amookunṣeka ọhun.
Ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lórí àwọn tó dáná sun tọkọtaya mọ́lé lọ́jọ́ ọdún tuntun
Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni iṣẹlẹ naa ṣi n jẹ kayeefi fun gbogbo awọn araalu Abẹokuta ati agbegbe ẹ nipinlẹ Ogun, paapaa awọn to gbọ sii, sibẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti f’idi rẹ mulẹ pe gbogbo awọn to lọwọ ninu iwa ika naa ni yoo f’oju wina ofin.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi n’igba to n sọrọ kọminu lori iṣẹlẹ aburu ọhun.
To si l’awọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii, ati pe ọwọ ti tẹ ẹnikan lori bi wọn ṣe dana sun t’ọkọ t’iyawo naa mọle, ti wọn tun ji awọn ọmọ wọn gbe salọ.
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ BBC YORUBA lọwọ, a gbọ pe ni kete ti ọkọ ati iyawo naa, Ọgbẹni Kẹhinde Fatinoye ati Arabinrin Bukọla Fatinoye de lati ibi isin wọnu ọdun tuntun l’awọn amookunṣeka naa lọ ka wọn mọle ni nnkan bi aago mẹta ọru, ko to di pe wọn dana sun wọn mọle.
Kini o ṣẹlẹ si awọn ọmọ to wa nile pẹlu tọkọtaya naa?
Bi wọn ṣe ṣe eyi tan lo sọ pe wọn ko awọn mejeeji si ẹyin mọto Hyundai naa, ti wọn si lọ ju awọn sinu odo Ogun to wa lagbegbe Adigbe mọ Ọbada Oko.
O ni lẹyin wakati meloo kan, loun too ni anfaani lati rapala jade ninu odo naa, toun ko si ri ọmọ wọn ọkunrin ti wọn jọ ju s’odo.
Lara awọn to wa lagbegbe naa la gbọ pe wọn ta ileeṣẹ ọlọpaa ẹkun Ibara l’Abẹokuta lolobo nipa iṣẹlẹ ọhun, to si jẹ k’awọn ọlọpaa too debẹ, awọn amookunṣeka yii ti dana sun ile, wọn si ti na papa bora.
Kini Oga ọlọpaa ipinlẹ Ogun sọ nipa iṣẹlẹ naa bayii?
Bi iroyin naa ṣe tẹ ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankọle lọwọ la gbọ pe o ti sare gbera lati lọ sibẹ, to si kọminu pupọ lori iṣẹlẹ ọhun.
Igba to kuro nile ti wọn ti ṣọṣẹ yii ni wọn lo gba odo naa lọ lati wo ibi ibẹ ṣe rii.
Loju ẹsẹ ti ọga ọlọpaa yii ti debẹ, lo ti rọ awọn omuwẹ to wa nitosi lati wa ẹnikan yooku ti wọn ju sibẹ, ṣugbọn ti wọn ko pada ri ohun to jọ eeyan niibẹ, ko too kuro.
Ẹni to lọ fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti sọ pe oun da ọkan lara awọn amookunṣeka naa mọ daadaa,
idi pataki to fi ni wọn fẹẹ pa oun danu, ṣugbọn ti ori ko oun yọ, bo tilẹ jẹ oun farapa yannayanna.
Awọn pannapanna la gbọ pe wọn ko oku awọn t’ọkọ t’iyawo naa lọ si mọṣuari ọsibitu ijọba to wa ni Ijaye niluu Abẹokuta, pẹlu iranlọwọ awọn ọlọpaa.
Won ni kete ti ọkọ ati iyawo naa, Ọgbẹni Kẹhinde Fatinoye ati Arabinrin Bukọla Fatinoye de lati ibi isin wọnu ọdun tuntun l’awọn amookunṣeka naa lọ ka wọn mọle ni nnkan bi aago mẹta ọru, ko to di pe wọn dana sun wọn mọle.
Agbegbe kan ti wọn n pe ni Ibara GRA niluu Abẹokuta ni iṣẹlẹ ọhun ti waye lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kinni, oṣu kinni, ọdun 2023 ti a wa yii.
Lara awọn to fi ṣẹlẹ naa to wa leti sọ pe ko pẹ rara ti t’ọkọ t’iyawo naa wọle, ni wọn l’awọn kan kan ilẹkun ile wọn, ti wọn si ni ọmọ-ọdọ wọn lọ ṣilẹkun, lai mọ pe awọn oniṣẹ-ibi ni wọn.
Bi wọn ṣe wọle tọ wọn, la gbọ pe wọn ti dana sun ile, ti wọn si tilẹkun lẹyin mọ wọn, mọ inu ile.
Wọn ni niṣe láwọn amookunṣẹka naa mu ọmọ wọn kan ṣoṣo to wa nile lasiko naa, ati ọmọ-ọmọ ọdọ to ṣilẹkun salọ, ti wọn si lọ ju wọn danu sinu odo Ogun to wa loju ọna Adigbẹ si Ọbada-Oko.
Tani tokotiyawo naa?
BBC YORUBA gbọ pe oṣiṣẹ banki apapọ orileede Naijiria, iyẹn Central Bank of Nigeria ni Ọgbẹni JKẹhinde Fatinloye, nigba ti iyawo rẹ, Arabinrin Bukọla jẹ oṣiṣẹ fasiti ọgbin to wa niluu Abẹokuta, iyẹn Federal University of Agriculture, Abẹokuta, FUNAAB.
Lara awọn ti wọn n gbe lagbegbe naa la gbọ pe wọn ranṣẹ si awọn oṣiṣẹ uileeṣẹ panapana nigba ti wọn ri ile ọhun to n jona lọwọ, ti wọn si ni k’awọn panapana too debẹ, aṣọ ko ba ọmọyẹ mọ.
Igba ti wọn lawọn panapana wọnu ile naa, ni wọn too mọ pe niṣe ni wọn wa dana sun t’ọkọ ti’iyawo naa mọle.
Kini ọlọpaa Ogun so bayii?
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi ninu ọrọ rẹ sọ pe “Lotitọ ni iṣẹlẹ naa, a ti gbọ sii. Wọn lawọn kan lo lọ dana sun wọn ile, ni ko pẹ ti wọn de lati iṣọ-oru alẹ aisun.
“Ọwọ ti tẹ ẹnikan ti a fura si. A si maa ṣe iwadii iku naa nipa ofintoto, iṣẹ iwadii ti bẹrẹ lẹkunrẹrẹ.”
Bo tilẹ jẹ pe ko tii sẹni to le f’idi ohun to fa sababi iku awọn eeyan naa mulẹ, sibẹ ohun ti ọpọ awọn eeyan n sọ ni pe o ṣee ṣe ki awọn to kagbako iku yii ti b’awọn kan dowopọ, to si yiwọ.
Koda, won ni pe ko pẹ ti baba agbalagba ẹni ọdun mejilelọgọrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Majẹkodunmi naa jona mọ inu ile ẹ lagbegbe Olomore ni ti awọn t’ọkọ t’iyawo yii naa tun ṣẹlẹ.












