Wo àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́wàá tí kìí ṣe ayẹyẹ ọdún tuntun ní January 1

Oríṣun àwòrán, Bianca De Marchi/AAP Image via REUTERS
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè káàkiri àgbáyé ló kí ọdún tuntun, 2026, káàbọ̀ ní Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kìíní, oṣù Kìíní, gẹ́gẹ́ bí ìṣe ní ọdọọdún.
Ní ọdún 1582 ni Pope Gregory ṣe àtúnṣe sí òǹkà ọjọ́ àti oṣù tí àwọn orílẹ̀-èdè ń lò tó sì gbé kàlẹ́ńdà tuntun mìíràn jáde èyí tó bí ṣíṣe ayẹyẹ ọdún tuntun ní ọjọ́ Kìíní oṣù January.
Àmọ́ bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè ṣe ń ṣayẹyẹ yìí, àwọn orílẹ̀ èdè kàn wá tó jẹ́ wí pé wọn kìí ṣe ayẹyẹ ọdún tuntun ti wọn ní ọjọ́ yìí.
Àwọn orílẹ̀ èdè tí à ń sọ yìí ló jẹ́ wí pé dípò kajọ́ kaṣù Gregorian, oòrùn, òṣùpá àti àwọn nǹkan mìíràn ni wọ́n fi ń ka ọjọ́ ti wọn.
Èyí ló fà á tó fi jẹ́ pé wọ́n ní àwọn ọjọ́ tí wọ́n yà fúnra wọn gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí wọ́n ń bẹ̀rẹ̀ ọdún tuntun lọ́tọ̀ tí kò si jọ ara wọn.
Nínú àwọn orílẹ̀ èdè tí wọn kìí ṣe ayẹyẹ ọdún tuntun ní January 1, ẹ wo àwọn mẹ́wàá tí BBC News Yorùbá ṣe àkójọ wọn.
Ethiopia

Oríṣun àwòrán, Instagram
Orílẹ̀ Ethiopia nìkan ni orílẹ̀ èdè ẹkùn Adúláwọ̀ tí kìí ṣe ayẹyẹ ọdún tuntun ní ọjọ́ Kìíní, oṣù Kìíní ọdún.
Ní ọjọ́ Kọkànlá, oṣù Kẹsàn-án ọdọọdún ni orílẹ̀ èdè Ethiopia, tó wà ní ẹkùn ìlà-oòrun ilẹ̀ Adúláwọ̀ máa ń bẹ̀rẹ̀ ọdún tuntun tirẹ̀.
Ìdí tí èyí fi ríbẹ̀ ni pé dípò kajọ́ kaṣù Gregorian, kajọ́ kaṣù Coptic èyí tó ń ka oṣù mẹ́tàlá fún ọdún kan ni Ethiopia ń lò nítorí wọn ò ní ìgbàgbọ́ nínú ìjọ Àgùdà.
Ọdún méje àti oṣù mẹ́jọ ni Ethiopia fi wà lẹ́yìn àwọn orílẹ̀ èdè àgbáyé tó ń lo kajọ́ kaṣù Gregorian.
Ní oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2025 tó kọjá ni Ethiopia ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ ọdún 2018.
China

Oríṣun àwòrán, Others
Ní ọdún 2025, ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kìíní ni orílẹ̀-èdè China tó bọ́ sí ọdún tuntun.
Fún ọdún 2026 yìí, ọjọ́ Kẹtàdínlógún, oṣù Kejì ni China yóò ṣẹ̀ṣẹ̀ bọ́ sí ọdún tuntun.
Ayẹyẹ ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún ni China àti àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jọ máa ń ṣayẹyẹ ọdún tuntun fi máa ń kí ọdún tuntun káàbọ̀.
Láti àárín ọdún 1990 ni orílẹ̀-èdè China ti máa ń fún àwọn ènìyàn ní ọlidé ọjọ́ mẹ́sàn-án láti ṣayẹyẹ ọdún tuntun.
Saudi Arabia

Oríṣun àwòrán, Instagram
Hijri ní kajọ́-kaṣù tí Saudi Arabia àti àwọn orílẹ̀-èdè GCC ń lò, ọjọ́ Kìíní, oṣù Muharram sì ni wọ́n máa ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ Kìíní ọdún tuntun.
Òṣùpá ni àwọn orílẹ̀ èdè yìí fi máa ń ka ọjọ́.
Ìbẹ̀rẹ̀ ọdún tuntun ní Muharram ń wáyé láti fi ṣe ìrántí bí Ànọ́bì Muhammad ṣe rin ìrìnàjò láti Mecca lọ sí Medina èyí tí wọ́n ń pè ní Hijrah.
Iye ọjọ́ tó wà nínú kajọ́-kaṣù Hijri ní ọdún kan máa ń fi ọjọ́ mọ̀kánlà sí méjìlá dín sí kajọ́-kaṣù Gregorian.
Ọdún 1447AH ni Saudi Arabia wà báyìí ní èyí tó túmọ̀ sí ẹ̀yìn ikú Ànọ́bì Muhammad.
India

Oríṣun àwòrán, Others
Ọjọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n máa ń ṣayẹyẹ ọdún tuntun káàkiri orílẹ̀-èdè India.
Ní gúúsù India, oṣù Kẹta sí oṣù Kẹrin ọdún ni wọ́n máa ń ṣe ayẹyẹ ọdún tuntun tó sì jẹ́ wí pé ní àríwá àti ààrin gbùngùn India, inú oṣù Kẹrin ọdún ló máa ń wáyé.
Bẹ́ẹ̀ inú oṣù Kọkànlá ni Gujarat - ìwọ̀ oòrùn India máa ń ṣayẹyẹ ọdún tuntun.
Bangladesh

Oríṣun àwòrán, Instagram
Ní ọjọ́ Kìíní, oṣù Baishakh ni orílẹ̀ èdè Bangladesh máa ń ṣayẹyẹ ọdún tuntun tí wọ́n ń pè ní Naba Barsha.
Ọjọ́ Kẹrìnlá oṣù Kẹrin ọdún ni ọjọ́ bọ́ sí nínú kajọ́-kaṣù Gregorian tó sì jẹ́ pé kajọ́-kaṣù Hindu Bengali ni wọ́n ń lò ní Bangladesh.
Iran

Oríṣun àwòrán, Instagram
Kajọ́-kaṣù Persian ni orílẹ̀ èdè Iran ń lò láti fi máa ka ọjọ́ wọn.
Nowruz ni wọ́n máa ń pe ayẹyẹ tí wọ́n máa ń ṣe nínú oṣù Kẹta láti fi ṣàmì ayẹyẹ ọdún tuntun bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kajọ́-kaṣù Hijri ni wọ́n ń lò ní Iran.
Lára àwọn nǹkan tí wọ́n fi máa fi ń ṣayẹyẹ ni ṣíṣe ìmọ́tótó àyíká àti ìrúbọ láti fi bèèrè fún ohun rere nínú ọdún tuntun.
Afghanistan

Oríṣun àwòrán, Instagram
Gẹ́gẹ́ bí Iran Kajọ́-kaṣù Persian náà ni orílẹ̀ èdè Afghanistan ń lò láti fi máa ka ọjọ́ wọn tí ayẹyẹ ọdún, èyí tí wọn sì ń pè ní Nowruz.
Ọ̀sẹ̀ méjì ni Afghanistan fi máa ń ṣayẹyẹ ọdún tuntun wọn.
Korea

Oríṣun àwòrán, Insatgram
Ọdún tuntun ló ń jẹ́ Seollal ní Korea, tí ayẹyẹ rẹ̀ sì máa ń wáyé fún odidi ọjọ́ mẹ́ta gbáko.
Òṣùpá ni àwọn Korea máa ń lò láti fi ka ọjọ́ wọn.
Tí ọdún tuntun bá ku ọ̀la ni ayẹyẹ náà ń bẹ̀rẹ̀ tí yóò sì parí ní ọjọ́ kejì ọdún.
Ọjọ́ tuntun túmọ̀ sí ọjọ́ láti bọ̀wọ̀ fún àwọn babańlá ènìyàn ní Korea pẹ̀lú wíwọ aṣọ ìbílẹ̀.
Isreal

Oríṣun àwòrán, Instagram
Ní oṣù Kẹsàn-án ni orílẹ̀èdè Isreal máa ń ṣayẹyẹ ọdún tuntun ní ìlànà kajọ́-kaṣù Jew.
Rosh Hashanah tó túmọ̀ sí “orí ọdún” ni wọ́n ń pe ọdún tuntun èyí tí wọ́n máa ń ṣe ní ọjọ́ Kìíní, oṣù Tishri.
Aṣọ funfun ni wọ́n sábà máa ń wọ̀ ní ọjọ́ yìí pẹ̀lú gbígba àdúrà ní Synagogue.
Ìgbàgbọ́ wọn ni pé ọjọ́ náà ni Ọlọ́run dá Adam àti Efa àti pé ọ jẹ́ ọjọ́ láti ṣayẹyẹ ìdásílẹ̀ ayé.
Vietnam

Oríṣun àwòrán, Instagram
Tet Nguyen Dan tàbí Tet ni wọ́n máa ń pe ọdún tuntun ní Vietnam.
Lẹ́yìn tí Vietnam ya kúrò lára orílẹ̀ èdè China ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní lo oòrùn láti fi máa ka ọjọ́ wọn lọ́tọ̀.
Ọjọ́ Kejìlélógún, oṣù Kìíní ni Vietnam máa ṣe ayẹyẹ ọdún tuntun ti wọn.
Tó bà sì ti ku ọ̀sẹ̀ kan tí ọdún tuntun máa bẹ̀rẹ̀ ni ayẹyẹ ti máa ń wáyé pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé àsìkò yìí ni ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa ń lọ jábọ̀ ohun tó ń lọ láyé fún Ọlọ́run kó tó tún padà wá sáyé fún ọdún tuntun.















