Èèyàn mẹ́fà kú lọ́jọ́ ọdún tuntun nínú ìjàmbá ọkọ̀ ní márosẹ̀ Eko s'Ibadan

Aworan tirela to ni ijamba ati awọn eeyan to duro ti i

Oríṣun àwòrán, FRSC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lonii ti i ṣe ọjọ akọkọ ninu oṣu Kin-in-ni ọdun tuntun 2026 yii, ko din ni eeyan mẹfa to padanu ẹmi sinu ijamba ọkọ kan to waye ni marosẹ ilu Eko s'Ibadan.

Ajọ FRSC to n ri si aabo loju popo, fidi ẹ mulẹ pe yatọ si awon to di oloogbe, eeyan meji mi-in tun farapa nibi ijamba to waye ni ikorita NASFAT naa.

Gẹgẹ bi FRSC ṣe wi, nnkan bii aago mẹta ọsan ku diẹ ni ijamba naa ṣẹlẹ.

Agbẹnusọ ajọ naa fun ipinlẹ Ogun, SRC Odunsi Afolabi, ṣalaye pe eeyan mẹjọ ni ijamba ọkọ naa kan.

O ni eeyan mẹfa ku lẹsẹkẹsẹ, nigba ti awọn meji farapa.

Ki lo fa ijamba ọkọ naa?

Ibi ijamba naa pẹlu awọn oṣiṣẹ FRSC to n pa ilẹ ibẹ mọ

Oríṣun àwòrán, FRSC

Àkọlé àwòrán, Ibi ijamba naa pẹlu awọn oṣiṣẹ FRSC to n pa ilẹ ibẹ mọ

Gẹgẹ bi o ṣoju mi koro kan ṣe wi, ọkọ akero to n bọ lati ilu Eko lo ko si abẹ tirela to n bọ lati ilu Ibadan.

Tirela naa fẹẹ lọri pada nikorita NASFAT ni bi a ṣe gbọ, asiko naa si si ọkọ akero to n ba ere bọ, ko si I labẹ.

Eyi lo mu awọn eeyan inu rẹ ha sabẹ tirela, ti pupọ ninu wọn si di oku.

Bakan naa, Agbẹnusọ FRSC Ogun, SRC Odunsi Afolabi, sọ pe ọkọ akero Mazda ati tirela ni ijamba naa kan.

"Ohun to fa ijamba yii ni ere asaju"

" A gbọ pe awọn ẹlẹyinju aanu kan ti gbe awọn to farapa lọ sile iwosan ti a ko mọ orukọ rẹ ki ikọ alaabo too de.

"Awọn to di oloogbe ti wa nile igbokuu-pamọ si."

Bẹẹ ni agbẹnusọ FRSC Ogun naa wi.

O fi kun un pe ọga agba FRSC nipinlẹ Ogun, Akinwumi .O.Fasakin, ti ni ki wọn ṣe iwadii ohun to fa iṣẹlẹ yii.

Bakan naa ni wọn kilọ fun awọn awakọ, pe ki wọn yee sare asapajude to n sọ ọpọ ẹmi nu yii, nitori bi okun ẹmi ba ja pẹnrẹn, ko ṣee so.