Ebi yóò dẹ́kun, ọrọ̀ ajé yóò búrẹ́kẹ́, ìjà láàárín Tinubu àti Dangote - Ẹ gbọ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ti jáde fún ọdún 2026 láti ẹnu àwọn Òjíṣẹ Ọlọrun

Pasitọ Enoch Adeboye wọ kootu alawọ ewe, Wolii Samuel King Malkiel wọ kootu alawọ paali, nigba ti Primate Elijah Ayodele wọ aṣọ wolii alawọ funfun ati buluu

Oríṣun àwòrán, Pastor E.A. Adeboye/Seer Samuel King Malkiel/Primate Babatunde Ayodele/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Asọtẹlẹ ti n jade lati ẹnu awọn iranṣẹ Ọlọrun fun ọdun tuntun 2026 to gberasọ lonii.

Bi ọdun 2026 ti bẹrẹ ni awọn gbajugbaja ojiṣẹ Ọlọrun bii oludari ijọ Redeemed Christian Church of God (RCCG), Pasitọ Enoch Adejare Adeboye ati Primate Babatunde Elijah Ayodele to jẹ oludasilẹ ijọ INRI Evangelical Spiritual Church ti sọ awọn ọrọ asọtẹlẹ nipa nnkan ti yoo ṣẹlẹ lọdun naa.

Awọn asọtẹlẹ naa da lori ijọba orilẹede Naijiria, awọn ọmọ Naijiria, eto ọrọ aje, awọn oloṣelu, eto aabo ni Naijiria ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ọdun 2026 yii ni ọpọ ọmọ Naijiria to ti japa lọ soke okun yoo pada wale - Adeboye

Ninu ọrọ asọtẹlẹ tiẹ, Pasitọ Adeboye sọ pe ọdun 2026 yoo jẹ ọdun ti adinku yoo ba ebi ọpagba to n pa ọpọ araalu ni Naijiria.

Baba Adeboye tun sọ pe ọdun 2026 yii ni ọpọ ọmọ Naijiria ti wọn ti japa lọ soke okun yoo pada wale.

Nibi eto isin aisun ọdun to waye ni Redemption Camp to wa ni kilomita 47 opopona marosẹ ilu Eko si Ibadan nipinlẹ Ọgun ni pasitọ Adeboye ti sọrọ yii.

Baba Adeboye ṣalaye pe ni ọdun 2026 yii, ọrọ aje Naijiria yoo gberu sii ti ounjẹ yoo si pọ si bakan naa.

Adeboye ni Ọlọrun sọ foun pe ebi yoo dinku ni Naijiria, ati pe awọn olokowo alabọde yoo ṣowo jere.

Aawọ yoo ṣẹlẹ laarin Dangote ati Tinubu, agbabọọlu ọmọ Naijiria kan yoo ku lọdun 2026 – Primate Ayodele

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu ọrọ asọtẹlẹ tiẹ, Pasitọ ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, Primate Ayodele sọ pe awọn agba oselu kan lẹkun ariwa orilẹde Naijiria yoo tako Aarẹ Bola Tinubu lọdun 2026 yii lori erongba rẹ lati dupo aarẹ fun saa keji.

Ayodele wa rọ Tinubu lati ṣiṣẹ lori ibaṣepọ rẹ pẹlu awọn alatilẹyin rẹ to wa lẹkun ila oorun guusu, aarin gbungbun ariwa ati lẹkun ila oorun ariwa orilẹede Naijiria daadaa.

Ojiṣẹ Ọlọrun naa tun sọ tẹlẹ pe awọn ẹgbẹ oṣelu meji to gbọrẹgẹjigẹ ni Naijiria yoo ṣe kara-kata ibo lọdun yii.

Pasitọ ijọ INRI Evangelical Spiritual Church tun sọ pe pe awọn eeyan kan yoo dide lati ba orukọ igbakeji aarẹ Naijiria tẹlẹ ri, Atiku Abubakar, jẹ lọdun 2026.

Bakan naa ni o tun kilọ fun Tinubu wi pe awọn oludamọran rẹ tẹlẹ kan yoo gbẹyin bẹbọ jẹ fun un.

Ayodele tun ni o kere tan minisita kan atawọn eeyan mii ninu ijọba Tinubu yoo wọ gau, aarẹ yoo si yọ wọn nipo lọdun 2026.

Alufaa Ayodele sọ pe ijọba Tinubu yoo fẹsẹ mulẹ sii lẹka ọrọ aje ati lagbo oṣelu, bo tilẹ jẹ pe aarẹ yo koju ipenija to pọ.

Oludasilẹ ijọ INRI tun sọ pe igba mẹjọ ọtọọtọ lawọn eeyan yoo ṣe ifẹhonuhan tako ijọba Tinubu lọdun 2026.

Primate Ayodele ni faakaja yoo waye laarin gbajugbaja oniṣowo, Aliko Dangote ati Tinubu lọdun 2026 yii.

Ojiṣẹ Ọlọrun naa ko ṣai kilọ wi pe abẹṣẹkubiojo ati agbabọọlu ọmọ Naijiria kan yoo ku lọdun 2026 ninu asọtẹlẹ rẹ.

Ayodele tun kilọ fun Aarẹ ile aṣofin agba l'Abuja, Sẹnẹtọ Godswill Akpabio, wi pe ko kiyesi ọrọ ẹnu rẹ ati ilera rẹ lọdun 2026.

Ninu ọrọ asọtẹlẹ tiẹ, Pasitọ ijọ the Dynamite Glory Ministry International niluu Eko, Wolii Malkiel Samuel King sọ pe ọdun ilọrọ ati itaniji ni ọdun 2026 yoo jẹ fawọn ọmọ Naijiria.