Dúkìá ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ mílíọ̀nù jóná, ẹ̀mí sùn níbi ìjàmbá iná méjì tó ṣẹlẹ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ kan l'Eko

Oríṣun àwòrán, Lagos State Fire and Rescue Service/X
Dukia ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu ati ẹmi eeyan ṣofo nibi ijamba ina meji to ṣẹlẹ laaarin ọsẹ kan niluu Eko lasiko ọdun to n lọ lọwọ yii.
Lanaa ọjọ Iṣẹgun ti i ṣe ọgbọnjọ oṣu Kejila ọdun 2025 ni iroyin jade pe apa kan ọja Arena ni Oshodi n jona.
Ina ọhun ni a gbọ pe ko din ni ṣọọbu mẹwaa ti o jona raurau.
Ajọ LSFRS to n ri si idoola ẹmi ninu iṣẹlẹ pajawiri ina sọ ninu atẹjade kan to fi sita pe ni nnkan ago mẹfa ku iṣẹju mẹwaa lawọn gba ipe wi pe ọja Arena ni Bolade, l'Oshodi n jona.
''Bayii ni a ti tete ran awọn oṣiṣẹ panapana lọ sibẹ, ti wọn si debi ti ina ti n jo ọhun laarin iṣẹju marun un.
Ijamba ina ọhun ṣakoba fun apa kan ọja naa nibi ti ina ti jo ṣoobu kọntena mẹwaa ti ọja wa ninu rẹ.
Ọja asọ onibeeli lo wa ninu awọn kọntena mẹwaa naa, amọ, a ri pe a pa ina ọhun ti ko si ran lọ si ibomiran ninu ọja ọhun.
Ọga agba ajọ LSFRS, Margaret Adeseye, sọ pe ijọba yoo ṣe iwadii lori nnkan to ṣe okunfa ijamba ina ọhun, ati pe gbogbo eeyan ni yoo gbọ esi iwadii naa to ba pari.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ẹmi sun, dukia olowo iyebiye jona nibi ijamba ina Ọja Balogun
Oniṣowo aṣọ lati China ti wọn n pe ni Obum wa lara awọn to ba iṣẹlẹ ina to jo nile itaja GNI to wa lọja Balogun niluu Eko lọ.
Ina ọhun ni a gbọ pe o bẹrẹ ni aja kẹrin ile itaja naa ti o si ran de aja kẹfa ile alaja mẹẹdọgbọn naa.
Nigba to ya ni ina ọhun ran de gbogbo aja ile ọhun to fi mawọn ile to wa lẹgbẹẹ rẹ.
A gbọ pe apa kan ile naa ya lulẹ lasiko ti ina ọhun n jo lọwọ, o si ya lu awọn oniṣowo kan to wa ninu ọja lasiko naa.
Agbẹnusọ ajọ LASEMA to n ri si iṣẹlẹ pajawiri, Nosa Okunbor, lo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.
Okunbor ṣalaye pe ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri yọ oku obinrin kan ti ile wo lu mọlẹ, wọn si ti gbe oku naa fun ọkọ rẹ.
Agbẹnusọ ajọ LASEMA fikun ọrọ rẹ pe ajọ naa tun yọ oku agbalagba kan ti ẹsẹ rẹ ti ge ati oku ẹlomiran ti gbogbo ẹya ara rẹ si pe sibẹ nibi ile to wo naa.
Ọkunrin meje ti won farapa yanayana lajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri yọ jade ti wọn si gbe wọn lọ si ile iwosan fun itọju.
Ẹwẹ, Gomina Babajide Sanwo-Olu ipinlẹ Eko ti sọ pe ijọba yoo wo ile alaja mẹẹdọgbọn GNI nibi ti ina to jo lulẹ.
Sanwo-Olu sọrọ yii lasiko to ṣabẹwo si ọja Balogun nibi ti ijamba ina ọhun ti ṣẹlẹ.
Gomina ni kọmiṣọna fun akanṣẹ iṣẹ ati ibaṣepọ laarin awọn ileeṣẹ ijọba, Gbenga Oyerinde, yoo sọ ọna ti ijọba yoo gba lati wo ile naa.
Sanwo-Olu ni ile GNI yii to yẹ ki wọn maa lo fun ọfiisi lasan an ti di ibi ti wọn n ko oniruuru ọja papaa julọ awọn nnkan to le tete jona si.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2















