Ìdí rèé tí Abubakar Malami agbẹjọ́rò àgbà Naijiria tẹ́lẹ̀ yóò fi ṣọdún tuntun lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Kuje

Oríṣun àwòrán, EFCC/Facebook
Ọgba ẹwọn Kuje l'Abuja ni agbẹjọro agba ati minisita eto idajọ Naijiria tẹlẹ, Abubakar Malami, yoo ti ṣe ọdun tuntun 2026, lẹyin ti ile ẹjọ paṣẹ pe ko wa lahamọ lori ẹsun iwa ajẹbanu ti wọn fi kan an.
Ajọ EFCC gbe Malami ati ọmọkunrin rẹ, Abubakar Malami Jnr ati arabinrin kan, Bashir Asabe, lọ ile ẹjọ lori ẹsun onikoko mẹrindinlogun to da lori jiji owo ilu ko lọ soke okun ati aṣilo ọfiisi.
EFCC fẹsun kan Malami pe o lo ọfiisi rẹ nigba to wa nipo agbẹjọro agba lati ji owo ilu ko eyi ti wọn lo fi ra oriṣiiriṣii dukia bii ilẹ, ile ati ile itura kaakiri orilẹede Naijiria to fi mọ Abuja, ipinlẹ Kebbi ati Kano.
Amọ, awọn eeyan mẹtẹẹta sọ fun ile ẹjọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti EFCC fi kan awọn.
Lẹyin naa ni Adajọ Emeka Nwite paṣẹ wi pe ki wọn ko wọn lọ si ahamọ lọgba ẹwọn Kuje, titi di asiko ti ile ẹjọ yoo fi ṣe agbeyẹwo beeli ti wọn n beere fun.
Lasiko ijọba Muhammadu Buhari ni Malami jẹ agbẹjọro agba ati minisita eto idajọ ni Naijiria.
Adajọ Nwite paṣẹ wi pe ọjọ keji oṣu Kinni ọdun 2026 ni ile ẹjọ yoo gbọ awijare Malami atawọn meji yooku fun beeli.
Adajọ ni olujẹjọ kini ati ekeji yoo wa ni ahamọ lọgba ẹwọn Kuje, nigba ti olujẹjọ kẹta yoo wa lahamọ lọgba ẹwọn Suleja.
Awọn ẹsun ti wọn fi kan Malami
Ẹsun akọkọ ti ajọ EFCC fi kan Malami ati ọmọkunrin rẹ ni pe wọn ra ileeṣẹ kan torukọ rẹ n jẹ "Metropoltan Auto Tech Limited'' laarin oṣu Keje ọdun 2022 si oṣu Kẹfa ọdun 2025.
EFCC ni awọn mejeeji lo ileeṣẹ yii lati ko owo bii biliọnu kan naira pamọ lọna aitọ.
Ẹsun yii tako abala 21(c) jiji owo ko lọ si oke okun ti ọdun 2022, eyi si ni ijiya labẹ abala 18(3) ofin naa.
Ẹsun keji ni pe Malami ati ọmọkunrin rẹ ra ileeṣẹ Metropoltan Auto Tech Limited lati ko owo mii to to N600m pamọ.
Ẹsun kẹta ni pe, EFCC ni Malami lo ileeṣẹ Rahamaniyya Properties Limited lati ko N500m pamọ, eyi ti o fi ra ile nla Duplex kan lopopona Amazon street, niluu Abuja lọdun 2022.
EFCC tun fẹsun kawọn olujẹjọ mẹtẹẹta wi pe wọn tun ji owo kan to le ni biliọnu kan naira pamọ loṣu Kẹsan an ọdun 2024 ni ile ifowopamọ Union Bank to wa ni ile itura Meethaq Hotels Ltd Jabi, Abuja.
Ẹsun mii tun ni pe Malami, ọmọkunrin rẹ ati Bashir Asabe tun jọ ko N700m pamọ sinu ile kan lopopona 3, Onitsha Crescent, Garki, Abuja, EFCC ni wọn tun ko owo mii to to N850m pamọ sinu ile mii to wa ni Plot 683, Jabi District, Abuja.
Loṣu Keji ọdun 2018, wọn fẹsun kan Malami pe o ra dukia kan lopopona 3, Rhine Street, Maitama, Abuja pẹlu N430m.
Ni oṣu Keji yii kan naa ni wọn tun sọ pe Malami ra dukia mii lopopona 3130, Cadastral Zone A04, Asokoro, Abuja pẹlu N210m.
Awọn dukia mii ti EFCC fẹsun kan Malami, ọmọkunrin rẹ ati Asabe pe wọn ra pẹlu owo ti wọn ni Malami ji ni dukia to wa ni opopona 1241B, Asokoro District pẹlu N325m lọdun 2021.
EFCC ni Malami tun ra dukia mii si opopona 27 Efab Estate, Gwarimpa, Abuja pẹlu N120 million laarin ọdun 2015 si 2016.















