'Kò tíi ju wákàtí mẹ́fà tí Anthony Joshua wọ Nàìjíríà fún àbẹ̀wò ọdún tó fi ko ìjàmbá', àwọn ẹbí Anthony Joshua sọ̀rọ̀ lórí ipó ìlera rẹ̀

Oríṣun àwòrán, BBC/Getty Images/BBC
Lati mọ ohun to n ṣẹlẹ lẹyin ijamba ti Anthony Joshua, abẹṣẹkubiojo ọmọ Naijiria pẹlu awọn ọrẹ rẹ ni lanaa ode yii ni marosẹ Eko s'Ibadan, BBC Yoruba ṣabẹwo si ile mọlẹbi rẹ to wa Ijokun, niluu Sagamu, ipinlẹ Ogun.
Oni ọjọ Iṣẹgun, ọgbọnjọ oṣu Kejila ọdun 2025 ni BBC de ile naa, nibi ti a ti ṣalabapade Alagba Adedamola Joshua, to jẹ ọkan lara awọn ẹgbọn fun Anthony Joshua.
Baba naa ṣalaye pe ko ti i ju wakati mẹfa lọ ti Anthony de si Naijiria ti ijamba ọkọ naa fi ṣẹlẹ, o ni o ṣẹṣẹ wọ Naijiria lati papakọ ofurufu nigba naa ni.
Alagba Adedamola sọ pe ibanujẹ ni ijamba ọkọ naa ko ba mọlẹbi Joshua, paapaa nitori iku awọn ọrẹ rẹ ti wọn jọ wa si Naijiria lati ṣọdun.
Ipò ìlera Anthony Joshua bayii
Gẹgẹ bi baba naa ṣe tẹsiwaju, awọn ẹbi ko ni anfaani lati ri Anthony Joshua nileewosan to wa.
Idi eyi bo ṣe wi ni pe eeyan nla ni abẹṣẹkubiojo naa, ogo agbaye ti Aarẹ Bola Tinubu ati Gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun ti ki i lori iṣẹlẹ naa ni.
Awọn alaṣẹ bayii naa ni wọn n ṣugbaa rẹ bi Alagba Adedamola ṣe wi, ati pe awọn n ri i ka lori ayejujara pe alaafia lo wa, ijamba ọkọ naa ko nipa to bẹẹ.
O ni bo tilẹ jẹ pe iku awọn ọrẹ rẹ dun mọlẹbi awọn gan-an.
Lati ana ni a ti fẹ mọ ileewosan to wa, a wa a kaakiri ṣugbọn a ko mọbẹ- Ẹgbọn Baba AJ
Ẹlomiran to tun jẹ ẹgbọn fun Baba to bi Anthony Joshua, Alagba Steven Oye Joshua, ṣalaye fun BBC News Yoruba pe:
"Ohun to foju han ni pe Eko lo ti n bọ nigba ti ijamba yẹn waye, a mọ pe wọn paaki tirela si ẹgbẹ kan, wọn fẹ ya a silẹ ni wọn fori sọ ọ.
"Lati ana yen bayii, inu wa baje, a ṣetan lati wa gbogbo ileewosan lati mọ ibi to wa, boya Ijebu-Ode ni ka wa a lọ, won o je ka mo.
"Mi o ro pe baba e wa ni Naijiria, mama e wa Naijiria ni tiẹ, mama ẹ lọ, o n bọ. Ọsibitu gan-an ni a wa lọ ti a fi de ti a ri i pe ẹyin naa wa nibi, a o tiẹ ti i wọle."
Baba naa sọ pe o n ka awon lara pe awon ko ti i ri Anthony Joshua, nitori omo to n gbe ogo idile, ogo agbaye ga ni, nnkan kan ko gbọdọ ṣẹlẹ si i.
Bakan naa lo ni iku awon ọrẹ rẹ naa dun awọn pupọ, bi wọn ko tilẹ ki n ṣẹ ẹni to n ja ẹṣẹ, eeyan ni wọn.
O fi kun un pe awon fẹ ri oju Anthony Joshua bayii, kawọn ri I pe alaafia lo wa, bawon ṣe n gbọ ọ naa ni awọn tun fẹ ri i.
Nipa pe ṣe AJ ti ṣeleri igbadun kan fun wọn ṣaaju ko too wale, eyi to le ma ṣee ṣe mọ bayii, Oye Joshua sọ pe rara o.
O ni ọpọ eeyan ninu ẹbi awon ni wọn jẹ araalu oyinbo, ti kaluku si n ṣe daadaa ni aye ara rẹ.
Baba sọ pe bi Anthony Joshua ba wale, ayọ lo jẹ fun awọn ju owo tabi ohunkohun miran lọ.
O ni AJ ko ṣeleri kankan fun ẹnikẹni, o kan n bọ nile lati ṣọdun pẹlu ẹbi rẹ ni.
Tinubu bá Anthony Joshua sọ̀rọ̀, Sanwo-Olu, Abiodun ní ara rẹ̀ ti balẹ̀ lẹ́yìn tórí kó o yọ nínú ìjàmbá ọkọ̀ tó gbẹ́mí èèyàn méjì

Oríṣun àwòrán, Bayo Onanuga/X
Aarẹ Bola Tinubu loun ti pe abẹṣẹkubiojo, Anthony Joshua, lori ago lẹyin tori ko o yọ ninu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ lanaa ọjọ Aje ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kejila eyi to gbẹmi eeyan meji.
Ohun ti a gbọ ni pe Joshua atawọn ọrẹ rẹ n lọ si ilu Shagamu ni ipinlẹ Ogun ti i ṣe ilu abinibi rẹ nigba ti ijamba ọkọ naa sẹlẹ lọna marọsẹ ilu Eko si Ibadan.
Ninu atẹjade ti Bayo Onanuga ti i ṣe oludamọran aarẹ lori eto iroyin fi sita, Tinubu ṣalaye pe oun pe AJ lori ago lati kẹdun pẹlu rẹ lori iku awọn alabaṣiṣẹpọ meji rẹ to ku ninu ijamba ọkọ naa.
''Mo gbadura fun Joshua nigba ti mo pe e, o si fi dami loju pe oun n gba itọju to peye nile iwosan toun wa .
Bakan naa ni mo tun ba mama Joshua sọrọ, mo si gbadura foun naa.
Emi ati Gomina Dapo Abiodun ipinlẹ Ogun to wa pẹlu Joshua nile iwosan ti wọn gbe e lọ naa sọrọ.
Gomina ipinlẹ Ogun fi dami loju pe oun yoo sa gbogbo ipa oun lati ri pe Joshua gba itọju to peye,'' Tinubu lo sọ bẹẹ.
Ṣaaju ni aarẹ, to wa ni Yuroopu bayii fun isinmi opin ọdun, ti kọkọ ranṣẹ ibanikẹdun si ẹbi Joshua lori ijamba ọkọ to ṣẹlẹ naa.
Tinubu ni ''mo kẹdun pẹlu Anthony Joshua ati ẹbi rẹ wi pe ki Ọlọrun fun wọn ni okun ati agbara lati le la asiko yii ja.
Gẹgẹ bi elere idaraya, o maa n ṣọkan akin, o si maa n fi ifẹ ti o ni si orilẹede rẹ han.
Awọn amuyẹ yii lo jẹ ki o jẹ iwuri fun ọpọ eeyan ni Naijiria.
A ni lati gba ara wa ni iyanju ni iru asiko yii gẹgẹ bii ọmọ iya kan naa.
Mo gbadura pe ki Eledua fun ọ ni agbara, ọgbọn ati ore ọfẹ lati la asiko yii ja.
Mo tun gbadura ilera pipe fun ọ ati pe ki Eledua tẹ awọn to ku si afẹfẹ rere.''
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
''Ara Anthony Joshua ti balẹ bayii nile iwosan''
Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Ogun ati Eko ti fidi rẹ mulẹ pe ara Anthony Joshua ti balẹ bayii nile iwosan to ti n gba itọju lẹyin tori ko o yọ ninu ijamba ọkọ.
Gomina Babajide Sanwo-Olu ati Dapo Abiodun ti ipinlẹ Ogun sọ ninu atẹjade kan ti wọn jọ fi sita pe awọn kẹdun pẹlu ẹbi eeyan meji to ku ninu iṣẹlẹ naa.
Ile iwosan kan niluu Eko ni wọn gbe Joshua ati ẹlominran toun naa moribọ ninu ijamba ọkọ naa lọ fun itọju.
Ijọba ipinlẹ Eko ati ti Ogun sọ pe awọn dokita ti fidi rẹ mulẹ pe ara Joshua ati ẹnikeji ti wọn gbe lọ sile iwosan naa ti balẹ daadaa lẹyin gbogbo ayẹwo ti wọn ti ṣe fun wọn.
Awọn dokita si tẹsiwaju itọju awọn mejeeji nile iwosan naa.
Ohun ti a gbọ ni pe Joshua ti n ba ẹbi rẹ sọrọ nibi ti o ti n gba itọju.
Ijọba ipinlẹ mejeeji ṣeleri pe awọn yoo ri pe Joshua ati ẹnikeji ti wọn jọ wa nile iwosan gbadun daadaa.
Iwadii lori nnkan to ṣokunfa ijamba ọkọ naa ti bẹrẹ bayii.
Ijọba ipinlẹ Eko ati Ogun ni awọn mọ riri ibanikẹdun awọn araalu lori iṣẹlẹ ọjọ Aje, amọ, wọn rọ awọn eeyan lati ma yọ Joshua ati ẹbi rẹ lẹnu lasiko yii rara.
A tun gbọ pe awọn aṣoju olu ileeṣẹ ijọba ilẹ Gẹẹsi ni Naijiria naa ti ṣabẹwo si Joshua nile iwosan.
Anthony Joshua dèrò ilé ìwòsàn, lẹ́yìn ìjàmbá ọkọ̀ tó pa èèyàn méjì ní márosẹ̀ Eko s'Ibadan

Oríṣun àwòrán, Adeniyi Orojo
Abẹṣẹkubiojo ọmọ Naijiria nni, Anthony Joshua, ni wọn ti sare gbe lọ sile iwosan bayii, lẹyin ijamba ọkọ kan to ni lonii, ọjọ Aje, ni marosẹ Eko s'Ibadan, nibi ti eeyan meji ti dagbere faye.
DSP Oluseyi Babaseyi, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, fidi ijamba naa mulẹ fun BBC lori aago lọsan-an oni.
Gẹgẹ bi DSP Babaseyi ṣe wi, ijamba naa waye lagbegbe kan ti a mọ si Sinoma, ka too de ile epo Danco, ni marosẹ Eko s'Ibadan.
"Ijamba ọkọ naa pa eeyan meji loju ẹsẹ ,ṣugbọn Anthony Joshua fi ara pa ni tiẹ, wọn si ti sare gbe e lọ sile iwosan fun itọju.''
Bẹẹ ni DSP Oluseyi Babaseyi wi.
O fi kun un pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo maa fi bo ba ṣe n lọ to wa leti.
Bawo ni ijamba ọkọ naa ṣe ṣẹlẹ?

Oríṣun àwòrán, Adeniyi Orojo
Gẹgẹ bi ẹka iroyin Punch ṣe royin iṣẹlẹ naa, ọkọ jiipu kan to jẹ Lexus ni Anthony Joshua wa ninu rẹ lasiko ijamba naa.
Jiipu ọhun ni wọn lo fori sọ tirela kan to duro, eyi to fa ijamba.
Wọn fi kun un pe ijamba ọhun ṣi ruju, iwadii si n lọ lati mọ ohun to fa a gan-an.
Ọpọ eeyan lo ti n daro latigba ti iroyin ijamba naa ti balẹ sori ayelujara.
Wọn n sọ pe iwadii gbọdọ waye lori ohun to fa ijamba ọkọ fun AJ bawọn ololufẹ rẹ ṣe maa n pe e.
Ẹ o ranti pe laipẹ yii ni Joshua fi ẹṣẹ fọ pari ẹkẹ abẹṣẹkubiojo ẹgbẹ rẹ kan, Jake Paul, tiyẹn si balẹ si ile iwosan.
Awọn eeyan ṣi n gboriyin fun Joshua lọwọ lori ija naa, bo ṣe fi ajulọ han oyinbo, Jake Paul, ni US.
Bi ijamba ọkọ ṣe wa jẹ laaarin ọjọ diẹ ti AJ wa ni Naijiria lo n kọ kaluku lominu.
Wọn n sọ pe nnkan kan ko gbọdọ ṣe ọmọ Yoruba atata lati ilu Sagamu, nipinlẹ Ogun naa.
A o maa fi to yin leti bo ba ṣe n lọ.
FRSC sọrọ, wọn ni ere asaju lo fa ijamba ọkọ yii
Ninu atẹjade ti ajọ Federal Road Safety Corps, (FRSC) fi sita lori iṣẹlẹ yii ni wọn ti sọ pe ere asaju lo fa ijamba ọkọ fun Anthony Joshua ati awọn to jokoo ti i ninu mọto naa.
Ajọ Federal Road Safety Corps (FRSC) to n ri si aabo loju popo,fidi iṣẹlẹ yii mulẹ lati ileeṣẹ wọn niluu Abuja.
Nnkan bii aago mejila ọsan oni ni wọn ni iṣẹlẹ naa waye.
Gẹgẹ bi atẹjade ti Olusegun Ogungbemide, Igbakeji ọga agba ajọ naa fun ikede ṣe wi, eeyan marun-un lo wa ninu ọkọ Joshua, ọkunrin ni gbogbo wọn.
"Eeyan meji ku bi ijamba naa ṣe ṣẹlẹ, nigba ti jiipu Joshua lọ kọlu tirela ti wọn gbe kalẹ jẹjẹ, ẹnikan fara pa, awọn meji si jade lai farapa rara.
" Anthony Joshua naa wa lara awọn ti wọn ṣugbaa laaye, ṣugbọn o farapa diẹ"
FRSC fi kun un pe ile igbokusi Livewell, to wa ni Ajaka, Sagamu, ni wọn gbe awon to di oloogbe lọ.
Atẹjade naa sọ pe iwadii fi han, pe ọkọ Lexus naa n sare ju bo ṣe yẹ lọ lasiko ijamba naa, paapaa fun ibi to jẹ iloro.
Nigba naa lo padanu akoso ọkọ lasiko to fẹ ya ọkọ miran silẹ, to si lọ fori sọ tirela ti wọn gbe kalẹ jẹjẹ lẹba ọna.
Ajọ FRSC ba ẹbi awọn to di oloogbe ninu iṣẹlẹ naa kẹdun, wọn si gbadura pe ki alaafia de ba Anthony Joshua naa kia.
Wọn kilọ fun awọn awakọ lati yee sare asaju, paapaa lawọn iloro ọna marosẹ Eko s'Ibadan, ki wọn si maa ranti pe ẹmi ko ni aarọ.
Ẹbi Anthony Joshua ba BBC sọrọ lori ijamba naa
Ẹnikan to ba BBC sọrọ ninu ẹbi Anthony Joshua, to ni ka ma darukọ oun, ṣalaye pe abẹṣẹkubiojo naa n lọ si ipinlẹ Ogun lati ilu Eko ni.
O ni ajọyọ ọdun tuntun ni Joshua fẹ lọ ṣe pẹlu awọn ẹbi rẹ l'Ogun, ti ijamba fi waye.
O ni gbogbo ẹbi lo ti n rẹti rẹ ni Sagamu.
Ọkunrin naa sọ pe iyalẹnu gbaa ni iṣẹlẹ to ṣẹlẹ nigba ti ọdun tuntun ku si dẹdẹ yii jẹ fun gbogbo ẹbi.
O fi kun un pe awọn n gbadura pe ki alaafia tete de ba ologo ọmọ awọn naa .
Bakan naa lo ni awọn ṣi n duro de ileeṣẹ ọlọpaa lati ṣewadii iṣẹlẹ naa ni kikun.
Ijọba Ogun kede pe ajoji ni awọn eeyan meji to ba ijamba naa lọ
Bakan naa ni ijọba ipinlẹ Ogun, labẹ akoso Gomina Dapo Abiodun, ṣalaye pe awọn meji to di oloogbe ninu ijamba naa ki I ṣe ọmọ orilẹede Naijiria.
Atẹjade ti Kayode Akinmade, Oludamọran pataki fun gomina Abiodun lori eto iroyin, fi ṣọwọ si awọn akọroyin lọjọ Aje oni ni wọn ti kede bẹẹ.
Ijọba Ogun naa ba ẹbi awọn to di oloogbe kẹdun, wọn si ṣe e ladura pe Anthony Joshua naa wa ni alaafia ara laipẹ rara.














