'Ẹ dákun ẹ foríjìn mí' , Peller bẹ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, Ó ní òun ò jẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́

Oríṣun àwòrán, Peller/x
Gbajumọ sọrọsọrọ lori Tiktok, Habeeb Hamzat, ti ọpọ mọ si Peller, ti tọrọ aforijin lọwọ awọn ololufẹ rẹ lẹyin iṣẹlẹ to ṣẹ eyi to fi fẹ wa ara rẹ pa.
Laipẹ yii ni fidio jade lori ayelujara nibi ti Peller ti n sunkun ninu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ to si ni oun fẹ pa ara oun nitori ipinya to waye laarin oun ati ololufẹ rẹ, Amadou Elizabeth Aminata ti ọpọ mọ si Jarvis.
Lẹyin iṣẹlẹ naa ni ileeṣẹ ọlọpaa fi panpẹ odin mu u lori ẹsun wiwa ọkọ ni iwakuwa, ati igbimọ lati gb'ẹmi ara ẹni.
Ninu fidio kan to fi sita lori ayelujara, Peller tọrọ aforijin lọwọ awọn ọmọ Naijiria, to si ni oun kabamọ ihuwasi oun.
Peller fi kun un pe iru iṣẹlẹ bẹẹ ko ni waye mọ lọwọ oun.
O tun ṣàlàyé siwaju sii pe oun ṣi n gba itọju lọwọ ati wipe nigba ti oun ba ṣetan oun yoo pada si ori ayelujara.
"Ẹyin ọmọ Naijiria, ẹ maṣe binu si mi o. Mi o ni jawe bẹẹ ṣoro mọ. Ni bayii mo n gba itọju lọwọ, ni kete ti mo ba si ti gba itọju tan maa pada si ori ayelujara."










