Ganusi, Kundus, Atasa àtàwọn ọ̀rọ̀ ìgboro míì tó milẹ̀ tìtì ní Naijiria lọ́dún 2025

MC Oluomo ati Kwam1

Oríṣun àwòrán, Oluomo/Kwam1

    • Author, Olumide Owaduge
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Oniruru nnkan lo ṣẹlẹ lọdun 2025 yii bi iṣẹlẹ ijinigbe, igbesunmọmi, iku awọn eeyan nlanla, ati bẹẹ lọ.

Bo tilẹ jẹ pe nnkan le ti ọpọ ọmọ Naijiria si n rahun bi igboro ṣe le to, pupọ ninu awọn eeyan ọhun lo wa ọna lati mu inu ara wọn dun.

Lara awọn ọna lati mu inu ara wọn naa dun ni awọn ọrọ olokiki ti awọn eeyan n sọ, eyii to si gbajumọ kaakiri Naijiria ati kaakiri agbaye nibi ti awọn ọmọ Naijiria n gbe.

Lara awọn ọrọ olokiki to gbode lawọn ọdun kan sẹyin ni 'shey u dey whine ni; dey play, e choke, we move, ati bẹẹ lọ.

Lọdun yii, iwọyin ni akojọpọ awọn ọrọ olokikio to gbode lọdun 2025 ni Naijiria.

Ganusi

Kwam1 lasiko eto isinu iya rẹ

Oríṣun àwòrán, refinedng

Ganusi tumọ si ki eeyan lọ si ode ariya ti wọn ko pe e si lati ṣe atẹnujẹ eyii ti ko mu iyi lọwọ.

Ọrọ naa gbajumọ lẹyin ti gbajugba olorin Fuji, Waius 'Kwam1' Ayinde sọ pe awọn alfaa kan wa 'Ganu' sile oun lẹyin oku iya oun ki wọn le ri owo gba lọwọ oun.

Ọrọ na bi ọpọ awọn ọlori ẹsin Islam ninu ni Naijiria, wọn si paṣẹ ki Wasiu tọrọ aforijin fun ọrọ abuku naa amọ o kọ jalẹ.

Kudunsi

Kundunsi jẹyọ lasiko ti olori ẹgbẹ awọn awakọ, NURTW, Musiliu 'Mc Oluomo' Akinsayan n kan saara si awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ fun iṣẹ ribiribi ti wọn ṣe.

A gbọ pe 'Kudos' ni Mc Oluomo fẹ sọ to fi sọ pe 'Kundusi."

Gadus

Ọrọ Gadus yii lo milẹ titi lẹyin ti awọn ọrẹ ọkunrin kan Abdulgafar Saad, n ki ti wọn si n sọ pe "No be Gadus be this?"

Awọn ọmọ Gen Z maa n lo ọrọ yii ti wọn ba n sọrọ lori ohun to ya wọn lẹnu tabi ti wọn ba fẹ kan saara si eeyan kan lọna awada.

Atasa

A ko le sọ ibi ti 'Atasa' ti wa amọ awọn kan sọ pe kii ṣe orilẹede Naijria lo ti ṣẹ wa.

Igbagbọ wa pe asiko idije bọọlu kan ni ọkunrin kan n kigbe "Atasa! Atasa!" lati ṣe moriwu fun ẹnikan to n gba bọolu naa.

Raise Am, Raise Am

Joel Ogebe ninu ṣọọṣi

Oríṣun àwòrán, Prophet Joel Ogebe

Ọkunrin kan to n gbọ iṣẹ ọkọ ayọkẹlẹ kan wo lo kọkọ sọ ede raise am raise am lati mọ bi ẹrọ inu ọkọ naa ṣe daa tọ.

Amọ nigba ti yoo di saa kan, wolii Joel Ogebe ti ijọ House of Salem bẹrẹ si n lo ọrọ naa ninu awọn orin rẹ bii "Promise Keeper," eyii to mu ki ọrọ ọhun gbajumọ daadaa ni Najiria.

Everywhere Go First Blurr

nkan ti ko han daadaa

Oríṣun àwòrán, refinedng

Asiko ti opin ọdun n de ni Everywhere Go First Blurr gbajumọ. Awọn ọmọ aye si maa lo ọrọ naa ti nnkan ti ko dara ba ṣẹlẹ.

Yala wọn ji foonu eeyan ni o tabi awọn onijibi wọ owo inu apo iṣuna eeyan lọ tabi ki eeyan gba ipe pajawiri ti ko dara.

Oju irufẹ ẹni ti nnkan bẹẹ ba sẹlẹ si yoo kọkọ ṣu lootọ, eyii ti oloyinbo n pe ni 'blur.'

Nepo Baby vs Lapo Baby

Ọrọ yii n tumọ si awọn ọmọ ọlọrọ atawọn ọmọ ẹni ti ko rọwọ họri.

Nepo Baby n tumọ si ọmọ olowo tabi oloṣelu ti baba rẹ ri owo ilu ko jẹ.

Nigba ti Lapo Baby jẹ ọmọ otoṣi ti wọn fi owo gbese banki Lapo tọ.

Opueh

Opueh jade lati inu ede Ijaw, ni Naijiria, o si tumọ si nnkan to tobi.

Amọ ṣa, awọn mii n lo Opueh fun ibalopọ.

Lode oni, ọpọ alawada bii Brain Jotter atawọn mii lo n lo Opueh ninu orin wọn, paapaa ti wọn ba n ṣẹfẹ.

Labubu

Awọn bebi labubu lori atẹ inu ọja kan niluu London

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Labubu jẹ bebi kekere kan ti awọn obinrin n so mọ eti kọkọrọ tabi apo wọn ni China atawọn orilẹede kan nilẹ Asia.

Labubu milẹ titi ni Naijiria lẹyin ti awọn ọmọ Najiriari ri pe iye owo ti wọn n ta a pọ jọjọ bo tilẹ jẹ pe bebi naa kere pupọ.

Achalugo

Achalugo n tumọ si obirin arẹwa to yẹ ki ọkunrin le na owo gọbọi le lori.

Inu ede igbo ni ọrọ naa ti ṣẹ wa ṣugbọn o gbajumọ lẹyin ti wọn lo o ninu fiimu kan, Love in Every Word.

Sinima Love in Every Word

Oríṣun àwòrán, Sinima Love in Every Word

Odogwu tabi Odogwu Paranra

Odogwu ni Naijiria n tumọ ọkunrin to lowo lọwọ tabi ẹni to lara to tun lowo.

Inu fiimu Love in Every Word ni ọrọ naa ti kọkọ jẹyọ ko to gbajumọ.

Sọ pe o ti lọ

Ti nnkan ba sọnu, ti nnkan ba bajẹ tabi ti ololufẹ ẹni ba kọ ẹni silẹ lawọn eeyan maa n sọ pe o ti lọ.

Lọpọ igba ti wọn ba fẹ ṣe awada tabi tu ẹni to padanu nnkan bẹẹ ninu, wọn a sọ pe 'O ti lọ.'

If E Reach Your Turn

Yoruba ni ti wọn ba ti n ke gbegbegbe, ti o ko ba tete ba wọn gbe wọn le gbe si ẹyinkunle rẹ.

Ọrọ yii gaa lo ba 'If E Reach Your Turn' mu.

Ọrọ naa n tunmọ si pe 'ki eeyan ma gọ ara rẹ' nibi to yẹ ko ti ja fafa.

O n ble, on cho

Asiko ti opin ọdun n sunmọ etile ni awọ ọrọ meji gbajumọ.

O n ble ati O n cho n tumọ si ayẹyẹ tabi ariya.