Àwọn ìkọlù agbébọn àti agbéṣùmọ̀mí tó milẹ̀ tìtì lọ́dún 2025

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọ̀pọ̀ òjò ló rọ̀ tí ilẹ̀ ti fà mu ní ọ̀rọ̀ ìkọlù àwọn agbébọn àti agbéṣùmọ̀mí lọ́dún 2025 ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Gẹ́gẹ́ bí àjọ Nigeria's National Human Rights Commission ṣe sọ kò dín ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba èèyàn (2,000) tó pàdánù ẹ̀mí wọn sọ́wọ́ àwọn agbébọn àti agbéṣùmọ̀mí nínú ọdún 2025.
Níṣe ni ìkọlù àwọn agbébọn àti agbéṣùmọ̀mí peléke si ní èkùn ìwọ̀ oòrùn àti ààrin gbùngbùn àríwá Nàìjíríà.
Díẹ̀ lára àwọn ìkọlù agbébọn àti agbéṣùmọ̀mí tó milẹ̀ tìtì ní Nàìjíríà lọ́dún 2025 nìyí.
- Ìkọlù Yelewata
Ní alẹ́ ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹtàlá mọ́ òwúrọ̀ kùtù ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹrìnlá oṣù Kẹfà ni ìkọlù tuntun míì wáyé ní ìlú Yelwata, ìjọba ìbílẹ̀ Guma ní ìpínlẹ̀ Benue níbi tí àwọn aláṣẹ ti sọ pé èèyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún ló pàdánù ẹ̀mí wọn.
Óṣojúmikòró kan ní àwọn darandaran tó gbé ìbọn dání ló kọlu agbègbè náà, tí wọ́n sì tún kojú àwọn ọlọ́pàá.
Ọ̀pọ̀ àwọn ilé ni àwọn tó ṣèkọlù sí ìlú náà tún dáná sun.
Èyí mú kí àwọn ọ̀dọ́ ìlú náà tú síta lọ́jọ́ Àìkú láti fi ṣe ìfẹ̀hónúhàn lórí ìṣekúpani tó ń wáyé lemọ́lemọ́ ní agbègbè náà.
Ọ̀pọ̀àwọn èèyàn tó fi mọ́ àwọn lọ́ọ́kọ lóòkì ní Nàìjíríà tó fi mọ́ Atiku Abubakar ló bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù náà.
Èyí ló mú ààrẹ Nàìjíríà, Bola Tinubu, lẹ́yìn tó fi àtẹ̀jáde léde láti bá àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Benue kẹ́dùn, ṣàbẹ̀wò síbẹ̀ lọ́jọ́rú.
Tinubu ní òpin gbọdọ̀ dé bá ìkọlù tó ń wáyé ní Benue ní gbogbo ìgbà náà.
- Ìkọlù Boko Haram ní Borno
Ní ọjọ́ Kẹta, oṣù Kẹsàn-án ni ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí Boko Haram ṣe ìkọlù sí ìlú Darul Jamal tó jẹ́ ibùdó àwọn ọmọ ogun tó wà ní ẹnubodè Nàìjíríà sí Cameroon ní ìpínlẹ̀ Borno.
Èèyàn tó lé ní ọgọ́ta làwọn agbéṣùmọ̀mí ṣekúpa ní òru mọ́jú níbi ìkọlù náà tó fi mọ́ àwọn ọmọ ogun márùn-ún.
Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí ṣe sọ, àwọn ọmọ ogun ojú òfurufú náà ṣekúpa àwọn agbéṣùmọ̀mí tó tó ọgbọ̀n nígbà tí wọ́n ṣe ìkọlù sí ìlú náà padà.
Kò dín ní ilé ogún àti ọkọ̀ mẹ́wàá táwọn agbéṣùmọ̀mí náà dáná sun lásìkò tí wọ́n ṣèkọlù sí ìlú Darul Jamal náà.
- Ìkọlù àwọn agbébọn ní Plateau
Kò dín ní àádọ́jọ àwọn èèyàn tí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn níbi onírúurú ìkọlù tó wáyé káàkiri ìpínlẹ̀ Plateau ní ọdún yìí.
Ní oṣù Kìíní ọdún 2025 làwọn agbéṣùmọ̀mí kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ọṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ náà pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ṣèkọlù sí ìlú Mangu, tí wọ́n sì pa èèyàn tọ lé ní ogún.
Ní oṣù Kẹrin, kò dín ní èèyàn mẹ́rìnléláàádọ́ta táwọn agbébọn ṣekúpa ní ìjọba ìbílẹ̀ Bassa àti Bokko ní ìpínlẹ̀ Plateau.
Lasiko ti awọn eeyan ti pupọ ninu wọn jẹ ara abule Chirang n daribọ lati ọja Bokkos, ti wọn n pada si Abule Mangor ni awọn agbebọn to ti dena de wọn ṣina ibọn bolẹ fun wọn.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló di aláìnílélórí mọ́ nítorí àwọn ìkọlù yìí.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Ìkọlù sílé ẹ̀kọ́ ní Kebbi
Lásìkò tí ìdúnkokò Ààrẹ Donald Trump ń gbilẹ̀ làwọn agbébọn lọ ṣe ìkọlù sí ilé ẹ̀kọ́ kan ní ìpínlẹ̀ Kebbi, tí wọ́n sì jí àwọn èèyàn mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n gbé lọ.
Àwọn agbébọn náà jí olùkọ́ méjì àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ márùndínlọ́gbọ̀n gbé lọ ṣùgbọ́n tí ẹnìkan nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà padà sá ma àwọn agbébọn náà lọ́wọ́.
Ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ àgbà ní ilé ẹ̀kọ́ pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lásìkò tó ń gbìyànjú láti dá ààbò bo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́ àwọn ajínigbé.
Ọjọ́ Kẹtàdínlógún, oṣù Kọkànlá ni ìkọlù náà wáyé àmọ́ tí ìjọba kéde gbígba ìtúsílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ náà.
- Ìkọlù ilé ìjọ́sìn CAC Oke Isegun, Kwara
Ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kọkànlá láwọn agbébọn yawọ ilé ìjọ́sìn CAC ti ìlú Eruku, ìpínlẹ̀ Kwara tí wọ́n sì ṣíná ìbọn bolẹ̀.
Èèyàn mẹ́ta ló pàdánù ẹ̀mí wọn lásìkò ìkọlù náà, tí àwọn agbébọn sì jí èèyàn méjìdínlógójì gbé lọ.
Ní ọjọ́ Kẹtàlélógún, oṣù Kọkànlá ni Ààrẹ Bola Tinubu kéde pé àwọn ti gba ìtúsílẹ̀ gbogbo àwọn èèyàn táwọn ajínigbé náà gbé lọ.
Ìkọlù yìí tún dá ìbẹ̀rùbojo sọ́kàn àwọn èèyàn, tí ọ̀pọ̀ èèyàn kò sì fẹ́ máa lọ síbi tí ìpéjọ ńlá bá ti wà mọ́.
- Ìkọlù sílé ẹ̀kọ́ St Mary Catholic School
Òru ọjọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kọkànlá láwọn agbébọn yawọ ilé ẹ̀kọ́ St Mary's Catholic Schools, Papiri, ìpínlẹ̀ Niger tí wọ́n sì jí ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ gbé lọ.
Alága ẹgbẹ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristẹni, Christian Association of Nigeria, CAN tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Niger, Ẹni ọ̀wọ̀ Bulus Dauwa Yohanna sọ pé èèyàn 315, tó fi mọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn olùkọ́ láwọn ajínigbé náà gbé lọ.
Ṣùgbọ́n èyí fa awuyewuye láàárín CAN àti ìjọba ÌPÍNLẹ̀ Niger báwọn aláṣẹ ṣe sọ pé àwọn èèyàn tí ajínigbé gbé lọ kò tó bẹ́ẹ̀.
Ó sọ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan móríbọ́ lásìkò ìkọlù ọ̀hún, tí àwọn òbí sì ti ń lọ mú àwọn ọmọ wọn nítorí wọ́n máa ti ilé ẹ̀kọ́ náà pa fún ìgbà kan ná.
Ọjọ́ Keje, oṣù Kejìlá ni ìjọba kéde pé àwọn ti gba ìtúsílẹ̀ ọgọ́rùn-ún akẹ́kọ̀ọ́ nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní àhámọ́ náà, tí àwọn yòókù sì wà ní àhámọ́ àwọn ajínigbé títí tí a fi ń kó ìròyìn jọ.
Ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kejìlá ni ìjọba gba ìtúsílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àádóje tó kù tó wà ní àháma ajínigbé náà.
- Ìkọlù ṣọ́ọ̀ṣì Kogi
Ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kejìlá, ọdún 2025 láwọn agbébọn yabo ilé ìjọ́sìn Evangelical Church Winning All tó wà ní Aaaaz-Kiri ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Kabba/Bunu, ìpínlẹ̀ Kogi lásìkò tí ìjọ́sìn ń ló lọ́wọ́ tí wọ́n sì ṣíná ìbọn bolẹ̀.
Èèyàn mẹ́tàlá láwọn agbébọn náà jí gbé lọ, táwọn míì sì farapa nínú ìkọlù náà.
Kọmíṣánnà fétò ìròyìn ìpínlẹ̀ Kogi, Kingsley Fanwo ṣàlàyé pé agbébọm márùn-ún ló jáde láyé lásìkò ìkọlù ṣùgbọ́n àwọn yòókù wọn móríbọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fara gbọta.
Ìgbà kejì rèé tí irúfẹ́ ìkọlù báyìí yóò wáyé láàárín ọ̀sẹ̀ méjì.
Ní ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn láwọn agbébọn ti kọ́kọ́ yabo ṣọ́ọ̀ṣì kan ní ìlú Ejiba, ìpínlẹ̀ Kogi kan náà, tí wọ́n sì jí pásítọ̀ kan, ìyàwó rẹ̀, àtàwọn ọmọ ìjọ míì gbé lọ.
Títí di àsìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, àwọn èèyàn tó wà ní àhámọ́ àwọn ajínigbé náà kò ì tíì gba ìtúsílẹ̀.














