Wo ewu tó wà nínú fífi tábà sójú ara obìnrin àti aburú tó ti ṣe fáwọn obìnrin tó ń lò ó

Taba ni wọn mọ ni Gambia bii gbajumọ oogun to le ṣẹgun irẹwẹsi, amarayagaga to daa fun ilera, pẹlu bawọn dokita ṣe n kilọ fun wọn to pe ki wọn yee lo o.
Àkọlé àwòrán, Aworan taba ti wọn di sinu ọra, ti ọwọ kan mu dani, ti wọn fi beba tẹ ẹ.
    • Author, Azeezat Olaoluwa
    • Role, Senior Journalist Reporter, West Africa
    • Reporting from, Gambia
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 10

Ikilọ: Awọn ohun to wa ninu iroyin yii le ma ba ọkan rẹ rẹ́.

*Aishatou, obinrin kan ti a fun ni orukọ yii lati le da aabo bo o, jẹ opo to n gbe lorilẹede Gambia.

O ṣalaye fun BBC pe fun ọdun mẹẹẹdogun loun fi n lo taba si oju ara lai ṣiwọ, lẹyin eyi lo si di ko ṣee lo fun oun.

Taba jẹ orukọ miran fun ewe tobacco, eyi ti wọn maa n lọ ti yoo si di iyẹfun, ti tọkunrin-tobinrin maa n mu lati ọdun pipẹ ni Iwọ-Oorun Africa.

Ọpọ eeyan lo n fin taba simu, awọn mi-in a si maa mu un bii siga, bẹẹ ni awọn kan maa n jẹ ẹ lẹnu.

Ṣugbọn ṣaa, ọpọ eeyan bii Aishatou ni wọn maa n ra taba yii lai jẹ kawọn eeyan mọ, wọn yoo si waa fi taba naa si oju ara ni tiwọn, eyi ti yoo ṣiṣẹ fun nnkan mi-in to yatọ gedegbe.

Ẹnu ọna ibi iṣẹ nọọsi kan ni a ti ba a to jokoo, nile iwosan alabọọde to wa lagbegbe naa, nibi to ti n ba wọn ṣepade nipa ipolongo tako taba.

Nibẹ ni Aishatou ti ṣalaye fun wa nipa bo ṣe kabaamọ pe oun tiẹ bẹrẹ si i lo taba rara.

*Orukọ gbogbo awọn to sọ iriri wọn nipa taba yii ni a ti yi pada.

Afigba ti taba fa jẹjẹrẹ oju ara fun Aishatou, yatọ si iku ọmọ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Taba ti wọn n ta yii, wọn n ta a loku oru laarin ara wọn nipasẹ awọn to n gbe e fun wọn ni, ọpọ igba lo jẹ pe ọja abẹle ti ko tobi ni wọn ti n ta a kaakiri orilẹede naa.

Ilana ti wọn n gba ṣe taba ọhun si ti yipada lati bii ọdun diẹ sẹyin; iyẹfun tobacco ti wọn n lo bayii ni wọn n po oriṣiirsii nnkan mọ ti yoo fi di ohun ti eeyan le tẹ pọrọ (paste).

Nigba to loyun ni 2021, Aishatou sọ pe oun naa mọ pe oun gbọdọ dẹkun lilo taba– gẹgẹ bo ṣe kọ ọ silẹ nigba to ni awọn oyun kan ṣaaju - ṣugbọn lero yii, Aishatou ri i pe oun ko le fi taba naa silẹ.

Nigba to si bimọ naa tan ti ọmọ ku, Aishatou di ẹbi iku ọmọ to ku ru taba ti ko le ma mu.

O lọ sọdọ dokita rẹ nigba to ri i pe ọmọ ko yi ninu oun mọ.

"Dokita sọ fun mi pe ọmọ naa ti ku, wọn ni lati ṣe iṣẹ abẹ fun mi.

Ngba ti wọn gbe ọmọ mi jade, awọ rẹ jọ bii pe o ti jona.

Mo mo pe taba ti mo lo lo pa ọmọ mi." Aishatou lo ṣalaye bẹẹ.

Bo tilẹ jẹ pe iṣegun oyinbo ko ti i fidi ohun to sọ yii mulẹ, Aishatou sọ pe abẹ oun maa n gbona nigbakugba toun ba lo taba.

Aishatou tẹsiwaju pe ọdun pipẹ sẹyin loun bẹrẹ si i mu taba, pẹlu ero pe yoo jẹ ki oun din ara asanju ku, yoo si jẹ koun ri oyun ni.

O ni ṣugbọn ko si eyi ti taba ṣe foun ninu awọn nnkan mejeeji yii.

"Nigba ti taba ba wọnu ẹjẹ eeyan lọ, o maa n gba akoso gbogbo ara eeyan ni, yoo si maa dari eeyan .

Eeyan yoo ni lati maa lo o lọ ko too le gbele aye lọna to yẹ.

Taba maa n fun mi ni adun, ṣugbọn o din ifẹ mi fun ibalopọ ku." Aishatou lo sọ bẹẹ

"O di ohun ti mi o le ma lo, mi o si le maa lo o lẹẹmẹta si mẹrin lojumọ."

"Lẹyin ti mo padanu ọmọ mi ni mo fopin si taba lilo, lai tiẹ mọ pe mọ pe mo tilẹ ti ni jẹjẹrẹ oju ara."

Aishatou ni wọn pada sọ foun nile iwosan pe oun ti lugbadi aisan jẹjẹrẹ oju ara, iyẹn lọdun meji sẹyin.

Nibomiran ti a tun lọ, a ṣe alabapade Rashida, (ki i ṣe orukọ rẹ gan-an leyi). A ba a to jokoo labẹ iboji igi mangoro kan.

Rashida toun naa maa n lo taba sabẹ, sọ fun BBC pe ọdun keje ree toun ti n lo taba, bẹẹ ni ọkọ oun ko mọ si i.

Bo ṣe n ba wa sọrọ lo n gbiyanju lati da omije to fẹ jade loju rẹ pada, o pada fomije ṣalaye bi taba ṣe ti gba gbogbo igbesi aye rẹ poo.

Rashida loun ranti aburo ọkọ oun to jẹ obinrin, to ku si ileewosan, o ni oun ni lati duro ti i nigba to n gba itọju lọwọ, ṣugbon oun ko ranti lati mu taba oun dani.

"Mo ni lati duro ti i fun ọjọ mẹta, ṣugbọn mo gbagbe lati mu taba mi dani.

Niṣe lo n ṣe mi bii ki n ri i, mi o le pa ọkan pọ rara, ara mi ko si balẹ lai ri taba."

Nigba to tun fẹ lọ ra taba miran, o ṣalaye bi taba yii ṣe ti di ko ṣee ma lo lọjọ kan foun.

Awọn obinrin ti BBC ba sọrọ yii ṣalaye pe lilo taba si oju ara jẹ ohun kan to lagbara pupọ, paapaa fun awọn obinrin to ba kọkọ dan an wo fun igba akọkọ.

"Igba akọkọ ti mo lo taba si oju ara mi, mo daku lọ, o ju wakati kan lọ ti mo fi daku, mo si jẹẹjẹ pe mi o ni i lo o mọ laye mi.

"Nigba ti mi lo o lẹẹkeji, mo bì rẹpẹtẹ. Ẹni to ṣi oju mi si taba sọ fun mi pe ki n maa lo o lọ, pe o n fọ ara mi ni."

Aishatou lo tẹsiwaju ninu alaye tirẹ bẹẹ.

Rashida paapaa gba pe bẹẹ lo ri, o ni ;

"Ooyi kọ mi mo si bẹrẹ si i gbọ̀n. Niṣe lo da bii pe iba n ṣe mi. Mo pada daku."

O ni bẹẹ lo tun ri lọjọ keji toun lo o, ṣugbọn nigba ti yoo fi di ọjọ kẹta, o mọ oun lara.

Awọn to n ta taba naa ki i patẹ rẹ, mẹnumọ ni wọn fi n ṣe

Bii ọpọ obinrin ti taba fifi si oju ara ti di ko ṣee ma ṣe fun ni Gambia, bẹẹ naa lo ri fu Aishatou toun naa jagun iṣoro taba mimu.
Àkọlé àwòrán, Aishatou, obinrin kan ti ko le ma ki taba bọ oju ara nitori pe o ti mọ ọn lara, sọ pe oun gbagbọ pe taba naa lo fa a toun fi padanu ọmọ toun bi. Idi niyẹn to fi n ṣalaye ara rẹ, to si n fi ohun to ṣẹlẹ si i kọ awọn obinrin yoku lọgbọn.

Awọn to n ta taba yii ki i le patẹ rẹ sita gbangba, niṣe ni wọn yoo patẹ awọn ọja mi-in ti wọn yoo si tọju taba sisalẹ.

Awọn onibaara wọn ti wọn ti jọ mọ ara wọn, ti wọn ko si ni i fi gbogbo ẹnu pe e ni wọn maa n ta a fun. Awon arugbo obinrin ni wọn tun maa n ta a nigberiko kiri.

Ramat, ẹni ọdun mẹrindinlọgọta (56) ṣalaye fun wa nipa bo ṣe n dọgbọn ta taba lati ọdun meji sẹyin, ni ilu kekere kan lapa North Bank.

O ṣalaye pe inu ọra lawọn maa n di i si, awọn si maa n fi beba kun un nigba mi-in nitori oorun rẹ to lagbara, ko ma baa run jade.

Nnkan bii Dalasi mẹẹẹdogun (15 Dalasi) ti i ṣe 20 cents lo ni awon n ta ìdì kan.

Ramat - to loun ko mọ ohun ti awọn to n ṣe taba naa fi n ṣe e, sọ pe oun n ta daadaa ni toun. Ere ilọpo meji (200% profit) lo ni oun maa n jẹ lori koroba onilita marun-un toun ba ra lati tun ta.

Nigba to kọkọ bẹrẹ okoowo naa, o loun ko mọ pe ohun ti awọn kan ko le ma lo ni.

"Ti mo ba ri okoowo mi-in to lere lori, mo maa dẹkun tita taba, nitori mi o fẹ ipalara fun eeyan bii temi."

"Emi naa ti lo taba ri lẹẹkan ṣoṣo lati fi tọju kokoro aifojuri, ṣugbọn mo fẹrẹ ku. Lati ọjọ yẹn, mi o lo o mọ. Awọn onibaara mi kan naa sọ fun mi pe bo ṣe ṣe awọn naa niyẹn."

Bina o ba lawọ, ko le gunke odo, taba yii kọja abẹle nikan

Ọdun 2020 ni Gambia kede taba bii ohun to lewu, ṣugbọn ai mulele lori ofin naa ti jẹ ki ọpọ awọn to n lo o ṣi maa lo o lọ. Kajali Sonko, ọmọ ile igbimọ aṣofin kan, sọ pe awọn yoo mura si ọrọ taba naa.
Àkọlé àwòrán, Ọdun 2020 ni Gambia kede taba bii ohun to lewu, ṣugbọn ai mulele lori ofin naa ti jẹ ki ọpọ awọn to n lo o ṣi maa lo o lọ. Kajali Sonko, ọmọ ile igbimọ aṣofin kan, sọ pe awọn yoo mura si ọrọ taba naa.

Igbagbọ awọn alaṣẹ wọn ni pe ọrọ taba tita ati lilo yii kọja ohun ti wọn n ṣe labẹle ni Gambia, wọn ni o lọwọ awọn oniṣowo ilẹ ibomi-in ninu, pẹlu bawọn to n ta a ṣe n wa a de Guinea-Bissau; Sierra Leone ati Casamance ni Senegal ti gbogbo ẹ jinna.

Ijọba Gambia kede taba lilo bii ohun to lewu fun awọn ọmọbinrin ni 2020.

Ṣugbọn eyi ko tu irun gidi kan lara awọn to n lo o- ko si ofin kan to mu awọn to n ta a pe ki wọn ma ta a mọ, bẹẹ ni wọn ko si fọwọ ofin mu awọn to n lo o naa.

Bo tilẹ jẹ pe lilo taba ko lodi sofin, ọdun mejidinlogun (18) ni wọn fi ọjọ ori ti eeyan ti le bẹrẹ si i lo o si, eyi jẹ ohun to n kọ awọn ẹgbẹ bii Mothers' Health Foundation ati ileesẹ to n ri si ọrọ awọn obinrin lominu, wọn ni awọn ọmọde naa ti n lo o.

"Ijọba mọ pe taba jẹ ohun kan to n ko ba ilera awọn obinrin Gambia gan-an, awa si fẹ ri si awọn eto ti yoo bojuto o."

Kajali Sonko, Igbakeji ọga agba nileeṣẹ to n ri si ọrọ ẹya ni Gambia lo sọ bẹẹ.

Bakan naa, Dokita Bai Cham, onimọ nipa awọ ara ni Medical Research Council, Gambia, ṣe iwe kan ni 2023 lori ipa ti taba maa n ni lara .

Ikọ rẹ ri i pe taba lilo yii le pa ilera lara, gẹgẹ bo ṣe maa n ri lara awọn to ba n mu siga.

Dokita Cham tun n ṣiṣẹ lorii irufẹ awọn ohun ti wọn n po mọ taba bii kẹmika.

Lara iwadii rẹ naa ni bo ṣe fọrọ wa obinrin 42 lẹnu wo, ati ọkunrin 15 ti wọn jẹ ololufẹ, ti wọn jọ n lo taba, atawọn ti wọn ti fẹra wọn kọja.

O ni o ju ida 90% obinrin lọ ninu awon toun ba sọrọ ti wọn ti ni ohun ti a mọ si nicotine poisoning - lara ohun ti yoo maa ṣe wọn ni eebi, igbẹ gbuuru, itọ ti wọn ko le da duro pe ko ma wa, ki abẹ maa gbona ati ko maa yun wọn.

Awọn kan lara awọn obinrin to ba sọrọ tun maa n fi soda kun taba ti wọn n ki bọ abẹ wọn.

Ikọ yii tun ri awọn ti nicotine ati ohun to n fa jẹjẹrẹ (carcinogenic tobacco-specific N-nitrosamines ) ninu ẹjẹ awọn miran ti wọn yẹwo.(TSNAs).

Ayẹwo fi han pe o to ida 3.63 mg/kg to wa ninu irufẹ taba ti wọn yẹwo, to lagbara ni ilọpo mẹwaa ju odiwọn ti WHO kede pe ko lewu, ti i ṣe 0.3 mg/kg to wa ninu awọn ewe to ṣee jẹ.

Ipolongo ati ilaniloye ti bẹrẹ

BBC mu awọn ẹya taba mi-in lati Essau ati Banjul - lọ si yara ayẹwo yunifasiti ilu Eko fun ayẹwo.

Esi fi han pe eroja ti a le ri pyridine ninu rẹ (eyi to ni ohun to farajọ nicotine ninu) to ju odiwọn ti ajọ Ilera agbaye, World Health Organisation, fọwọ si lọ.

Ijọba Gambia ti n lo awọn oṣiṣẹ eleto ilera ati awọn ajijagbara lati kede tako lilo taba ni awọn igberiko orilẹede naa.

Ọgbẹni Sonko, lati Gender Ministry, sọ fun BBC pe awọn ti bẹrẹ eto ipolongo ati ilanilóye kan.

Orilẹede naa si ti bẹrẹ si i kọ ibudo akọkọ fun atunṣe aye awọn eeyan ti aye wọn nilo atunṣe, ati ibudo itọju, ṣugbọn a ko ti i mọ boya yoo kan awọn to n lo taba.

Nigba ti awọn alaṣẹ n wo igbesẹ to kan lọwọ, awọn eeyan to ti lo taba ri bii Aishatou, n kede tako lilo taba lawọn agbegbe ati igberiko.

"Mi o fẹ kawọn obinrin koju ohun ti mo la kọja."

Bakan naa ni Rashida naa loun kabaamọ lilo taba, oun si nireti ati dẹkun lilo rẹ lọjọ kan.

"Bi mo ba le ri iranlọwọ, o daju pe mi o ni i lo o mọ. Mi o le gba ẹnikẹni nimọran lati maa lo taba, ko ma lọọ di ko ṣee ma lo bii temi fun wọn."

Afikun iroyin lati ọwọọ Yusuf Akinpelu