Kò ní sí ojúṣàájú tàbí ọ́wọ́ òṣèlú nínú yíyan Awujalẹ tuntun - Gómìnà Abiodun

Gomina Dapo Abiodun ati Awujale to waja, Ọba Sikiru Kayode Adetona

Oríṣun àwòrán, Gov. Dapo Abiodun/ Facebook/ Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba ipinlẹ Ogun labẹ iṣakoso Gomina Dapọ Abiọdun, ti ṣeleri pe ko ni i si ojusaaju tabi ọrọ oṣelu ninu yiyan Ọba tuntun fun ipo Awujalẹ tilẹ Ijẹbu.

Gomina Dapo Abiodun ti Kọmiṣanna feto oye jijẹ ati ijọba ibilẹ nipinlẹ naa, Ọnarebu Ganiyu Hamzat, ṣoju fun lo sọrọ idaniloju naa laipẹ yii niluu Abeokuta.

Abiodun jẹ ko di mimọ nibi ipade to ṣe pẹlu awọn alẹnulọrọ, ni ọfiisi rẹ to wa ni Oke-Mọsan, pe gbogbo ilana to ba tọ labẹ ofin yiyan Awujalẹ Ijẹbu ni ijọba yoo tẹle lati ri i pe ko si awuyewuye.

Ipade ọhun lo waye pẹlu awọn aṣoju ijọba ipinlẹ Ogun, awọn alakoso ijọba ibilẹ Ijebu-Ode, to fi mọ awọn olori ẹbi Fusengbuwa ati awọn igbimọ iṣakoso Awujalẹ.

Kí ni wọ́n fi ẹnu kò lé lórí?

Nibi ipade naa ni wọn ti fẹnuko lori ọna ti wọn le gba lati fi yan Awujalẹ tuntun.

Nigba to n ba awọn akopa sọrọ, Gomina Dapo Abiodun sọ idi ti ipo Awujalẹ fi ṣe pataki ninu aṣa, itan ati iyi nini.

Gomina sọ pe ohun to gbẹgẹ to si gba ikiyesara ni yiyan ọmọ oye fun ipo to ṣi silẹ naa.

O ni gbogbo eto lati yan ọmọ oye ni ko gbọdọ ni kọlọfin ninu, bẹẹ si ni gbogbo awọn ti ọrọ naa kan, to fi mọ araalu ni ohun gbogbo gbọdọ han si kedere.

"Bo tilẹ jẹ pe ipo Awujalẹ ṣofo, sibẹ ijọba ipinlẹ Ogun ko ni i kanju lati yan ọmọ oye lai tẹle ilana ati eto to yẹ."

Bẹẹ ni Dapo Abiodun wi.

O wa rọ gbogbo awọn ti ọrọ kan ati araalu lati ṣe suuru, ki wọn si dẹkun lati maa gbe igbesẹ ti ko si labẹ ilana ati eto awọn alakoso.

Gomina ṣeleri pe gbogbo eto to rọ mọ yiyan ọmọ oye naa ni wọn yoo ṣe labẹ ofin to wa nilẹ, to fi mọ ofin oye jijẹ ti ọdun 2021.

O ni eyi n sọ nipa ojuṣe, agbara ati igbesẹ awọn alẹnulọrọ lori ọrọ oye jijẹ kaakiri ipinlẹ Ogun.

Dapo Abiodun ni awọn ni lati bọwọ fun ilana, eto ati ofin to ti wa loju iwe, lati dena gbogbo ọrọ ile ẹjọ to le dide lọjọ iwaju nitori oye jijẹ.