Kókó àbá ètò ìṣúná N58.47trn ọdún 2026 tí Tinubu gbé lọ síwájú ilé aṣòfin fún ìbuwọ́lù

Oríṣun àwòrán, Presidency
Aarẹ Bola Tinubu ti gbe aba eto iṣuna N58.47 trn ọdun 2026 lọ siwaju ile aṣofin agba l'Abuja fun ibuwọlu lọjọ Ẹti ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kejila yii.
Aarẹ Tinubu ni eto iṣuna ifarada, aṣeyọri iṣẹ ati ilọrọ ni eto isuna ọhun.
O ni ijọba fẹ pese iṣẹ, ṣe atunṣe ọrọ aje ko le fẹsẹ mulẹ daadaa ati pe ijọba oun tun fẹ mu aye rọrun fawọn ọmo Naijiria lọdun 2026 lẹyin ti wọn ti ni ifarada fun ọdun meji bayii.
Owo to to ₦34.33 tiriliọnu ni ijọba n reti lati pa wọle, nigba ti wọn fẹ na owo ti ko din ni ₦26.08 tiriliọnu lọdun to n bọ.
Tinubu ni ₦15.52 tiriliọnu ni ijọba yoo fi san ele ori gbese ti Naijiria n jẹ.
Koko to wa ninu aba eto iṣuna 2026 ti Tinubu gbe lọ siwaju ile aṣofin agba
Eto aabo yoo gba ₦5.41 tiriliọnu
Ẹka eto aabo ni yoo ijọba yoo nawo le lori julo lódun 2026, ₦5.41 tiriliọnu ni owo ti ijóba apapọ ya sọtọ lati na lori eto aabo.
Tinubu ni ọna mii ni ijọba yoo gba lati wa ojutuu si eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria lọdun 2026.
Aarẹ ni gbogbo awọn janduku agbebọn, awọn agbesunmọmi, ati gbogbo awọn to n ṣagbatẹru wọn ni ijọba yoo doju ija kọ lọdun 2026.
Aarẹ Naijiria sọ pe ijọba ṣetan lati dẹkun iṣẹlẹ ijinigbe ati iṣekupani awọn alaiṣẹ lódun 2026.
Lori ọrọ aje, Tinubu ni ijọba oun ti ṣe awọn aṣeyọri kan lori orọ aje lẹnu asiko toun gori aleefa.
O ni odiwọn bi nnkan ṣe n wọn ti ja lulẹ wa si ida 14.45% ni ibẹrẹ ọdun 2025 yii, ati pe owo Naijiria to wa ni ipamọ ti di $47bn eyi to fawọn olokowo ni igboya lati wa dokowo ni Naijiria.
Ohun amayedẹrun yoo gba ₦3.56 tiriliọnu
Ẹka eto ẹkọ yoo gba ₦3.52 tiriliọnu
Eto ilera yoo gba ₦2.48 tiriliọnu
Gbogbo owo ti ijọba n reti lati pa wọle ni ₦34.33 tiriliọnu.
Owo ti ijọba fẹ na fun akanṣe iṣẹ ni ₦26.08 tiriliọnu.
Owo ti ijọba fẹ fi san ele ori gbese ni ₦15.52.















