Àlàyé rèé lórí bí obìnrin tí àwọn agbésùnmọ̀mí jí gbé ní Zamfara ṣe bímọ sákàtà wọn

Oríṣun àwòrán, gettu images
Inu ibẹrubojo lawọn eeyan ilu Nahuce, ni ipinlẹ Zamfara wa bayii lẹyin ti awọn agbesunmọmi ji obinrin to le ni ogun, awọn ọmọ wọn ati ọkunrin mẹrin gbe lọ nibẹ.
Ohun to ya awọn ara ilu naa lẹnu julọ ni bi ọkan ninu awọn obinrin ti wọn ji gbe ọhun ṣe bi ọmọ lasiko ti wọn n ko wọn lọ sinu igbo.
Iṣẹlẹ yii lo n waye lasiko ti awọn kan n sọ pe nnkan ti n pada ṣenu ire lori eto aabo ni Ariwa Naijiria.
Ipinlẹ Zamfara wa lara awọn ipinlẹ ti iṣẹlẹ ijinigbe ti milẹ titi julọ ni Naiijiria lati ọpọ ọdun sẹyin.
Amọ lẹnu lọlọ yii ni awọn alaṣẹ sọ pe nnkan ti n pada bọ sipo lagbegbe naa lẹyin ti wọn mẹnuba awọn aṣeyọsri wọn lati koju eto abo to mẹhe.
Bi obinrin naa ṣe bimọ
Gẹgẹ bii ohun ti awọn eeyan ilu naa sọ fun awọn akọroyin, asiko ti wọn n mura lati kirun alẹ ni awọn ajinigbe naa ya wọ aarin ilu.
Olugbe ilu naa kan sọ fun BBC pe "ọkan wa ko balẹ mọ bayii o, alẹ ana ni wọn ṣadede ya wọ aarin ilu wa ti wọn si ji awọn eeyan gbe lọ, awọn ọmọ wa wa lara awọn ti wọn ti je gbe pẹlu.
"Nigba ti obinrin ọhun bẹrẹ si n rọbi, wọn gbe lọ sinu igbo kan ko lọ bimọ sibẹ kaka ki wọn da pada sile.
"Nigba to ya, obinrin naa pada wale latari pe ko ni okun daadaa."
Olugbe ilu ọhun ṣalaye pe awọn agbesunmọmi se ti ṣe ayipada si bi wọn ṣe n ṣọsẹ.
Ẹni naa ti ko fẹ fi orukọ ara rẹ lede ṣalaye pe wọn ko wọ ilu wọn lori alupupu bii iṣe wọn, amọ niṣe ni awọn ajinigbe naa fi ẹsẹ rin wọlẹ, ti wọn a si gbe ẹni ti wọn ba fẹ ji gbe lọ ki wọn to gbe ẹni naa sori alupupu.















