Kí ló kàn fún Farouk Ahmed ọ̀gá àjọ NMDPRA tó ń ṣàmójútó epo rọ̀bì tó kọ̀wé fipò sílẹ̀ lórí ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu?

Oríṣun àwòrán, NMDPRA
Ibeere kan ti ọpọ eeyan n beere naa ni pe ki lo kan fun ọga aga ajọ NMDPRA to n ṣamojuto kata-kara epo rọbi ni Naijiria, Farouk Ahmed, to kọwe fipo silẹ lẹyin ti oludari ileeṣẹ Dangote, Aliko Dangote, fẹsun iwa ajẹbanu kan an.
Ṣaaju ni Dangote beere wi pe nibo ni Ahmed ti ri owo bii $5m to fi ran ọmọ rẹ mẹrin lọ kawe loke okun bi kii ba ṣowo ijọba.
Dangote ni iwa ajẹbanu n ṣakoba nla fun okowo epo rọbi ni Naijiria pẹlu nnkan tawọn to wa nipo adari lẹka naa n ṣe.
Ẹwẹ, Dangote ti kọwe si ajọ ICPC to n gbogun ti iwa ibajẹ lẹnu iṣẹ wi pe ki ajọ naa ṣewadii Ahmed lori ẹsun iwa ibajẹ, ṣiṣe owo ilu kumọ kumọ ati lilo ọfiisi rẹ nigba to wa nipo ọga ajọ NMDPRA lọna aitọ.
Agbẹjọro agba Ogwu James Onoja (SAN) ni Dangote lo lati kọ iwe naa si ICPC, eyi ti alaga ajọ naa, Ọmọwe Musa Adamu Aliyu, tẹwọ gba.
Dangote ni ki wọn mu Ahmed ni kia kia, ki o si foju ba ile ẹjọ lẹyin iwadii ajọ naa.
Gbajugbaja oniṣowo naa sọ pe igbe aye ti Ahmed n gbe ju owo oṣu to n gba lọ.
Dangote tun fẹsun kan Ahmed pe o ti san asanlẹ owo to le ni $7m gẹgẹ bii owo ile ẹkọ awọn ọmọ rẹ mẹrin nile ẹkọ wọn lorilẹede Switzerland.
Koda, o tun darukọ awọn ọmọ ati orukọ ile ẹkọ wọn lorilẹede Switzerland gẹgẹ bi ẹri fun ajọ ICPC.
Ta ni Oritsemeyiwa Amanorisewo Eyesan ọga ajọ NMDPRA tuntun?
Oritsemeyiwa Amanorisewo Eyesan kekọọ gboye ninu imọ ọrọ aje ni fasiti ilu Benin, UNIBEN.
Eyesan ti ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ epo rọbi Naijiria, NNPC, fun bii ọdun mẹtalelọgbọn.
O tun ti dipo igbakeji aarẹ mu ni ẹka to n ṣamojuto epo rọbi ni Naijiria laarin ọdun 2023 si 2024.
Bakan naa lo tun dipo ọga agba ẹka ọgbọn inu ati eto ṣiṣe mu ni ileeṣẹ NNPC lati ọdun 2019 si 2023.
A bi Onimọ ẹrọ Saidu Aliyu Mohammed lọdun 1957 ni ipinlẹ Gombe.
Mohammed kẹkọọ gboye ni fasiti Ahmadu Bello, Zaria ni ipinlẹ Kaduna.
Ẹkọ nipa imọ ẹrọ lori kẹmika lo kọ ni fasiti ABU, ọdun 1981 lo si ṣetan nile ẹkọ ọhun.
Mohammed ti dipo ọga agba ileeṣẹ ifọpo rọbi to wa niluu Kaduna mu.
Bakan naa ni o tun ti jẹ alaga ajọ to ri si agba ti epo n gba inu rẹ kọja lẹkun iwọ oorun Afirika ri.
Onimọ ẹrọ Mohammed tun ti kopa ribi ribi ninu awọn akanṣe iṣẹ kan bii Escravos–Lagos Pipeline Expansion, Ajaokuta–Kaduna–Kano (AKK) Gas Pipeline, ati Nigeria LNG Train.
Ọpọ eeyan lo gbagbọ wi pe kia kia ni ile igbimọ aṣofin agba yoo buwọlu iyansipo awọn mejeeji yii gẹgẹ bi wọn ti ṣe fun minisita eto aabo, Christopher Musa.
Ọ̀gá àjọ alámójútó epo rọ̀bì tí Dangote ní kó wá sọ bó ṣe rí $5m rán ọmọ rẹ̀ lọ kàwé lókè òkun ti kọ̀wé fipò sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọga agba ajọ NMDPRA to n ṣamojuto kata-kara epo rọbi ni Naijiria, Farouk Ahmed, ti Aliko Dangote ti i ṣe oludari ileeṣẹ Dangote to ni ileeṣẹ ifọpo rọbi to wa nipinlẹ Eko fẹsun ajẹbanu ati kiko owo ẹka epo rọbi Naijiria si apo ara rẹ kan ti kọwe fipo silẹ.
Oludamọran aarẹ lori eto iroyin, Bayo Onanuga, lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi lede loju opo X rẹ nirọlẹ ọni Ọjọru ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kejila.
Ṣaaju ni Dangote ti fẹsun ajẹbanu ati gbigbabọde fun ẹka epo rọbi Naijiria kan Ọgbẹni Ahmed.
O ni ọrọ aje Naijiria n bajẹ, araalu n daamu lori epo rọbi, ijọba n fowo nla ra epo ti a ni wọ Naijiria, ẹni kan si n gba ibi epo naa gbabọde fun araalu, o n fi owo ilu gbọ bukaata ara rẹ nikan .
Olori ileeṣẹ Dangote sọ pe owo to to miliọnu marun-un dọla ($5m) ni Ahmed n san fun ileewe girama ti awọn ọmọ rẹ mẹrin n lọ ni Switzerland.
O ni eyi to ki awọn ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ṣewadii ọga ileeṣẹ to n ri si ọrọ epo naa wo.
O fi kun un pe afi ki Ahmed foju kan kootu to n ri si ihuwasi ni Naijria, ko si ṣalaye fun gbogbo ọmọ Naijiria, ibi to ti n ri $5m owo ile ẹkọ naa san, bi ko ba jẹ pe owo ilu lo n na.
Ẹ o ranti pe ṣaaju ni NMDPRA ti ni ahesọ ati ibajẹ lasan ni awọn to n fẹsun kan Ahmed n ba ka.
Ẹwẹ, Aarẹ Bola Tinubu ti forukọ onimọ ẹrọ Saidu Aliyu Mohammed ranṣẹ si ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja lati buwọlu u gẹgẹ bii ọga agba tuntun ajọ NMDPRA.
Bakan naa ni aarẹ tun forukọ Oritsemeyiwa Amanorisewo Eyesan ranṣẹ gẹgẹ bi ọga agba tuntun ajọ NUPRC lati rọpo Gbenga Kolawole toun naa kọwe fipo silẹ bii Ahmed.
Aarẹ Muhammadu Buhari lo yan Ahmed ati Kolawole sipo wọn lọdun 2021 lati maa ṣamojuto ẹka epo rọbi ni Naijiria.
Akọṣẹmọṣẹ to ti pẹ lẹka epo rọbi lawọn mejeeji ti Aarẹ Tinubu ṣẹṣẹ yan sipo yii ti o n reti ki ile aṣofin agba buwọlu iyansipo wọn.















