Kí ló fà á tí ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun fi dá ètò yíyan Awujale Ijebu tuntun dúró? Àlàyé rèé

Oríṣun àwòrán, AWujale Palace
Ijọba ipinlẹ Ogun ti da gbogbo eto ati ilana yiyan ojulowo ọmọ oye fun ipo Awujalẹ tilẹ Ijẹbu, eyi ti mọlẹbi Fsengbuwa n ṣakoso rẹ duro fun igba diẹ.
Ọjọ Aje, ọsẹ yii lo yẹ ki ipade eto yiyan ọmọ oye yẹ ko waye ni gbọngan Bisrod to wa niluu Ijẹbu-Ode, ṣugbọn ti awọn mọlẹbi Fusengbuwa ti ipo naa kan wọgile e pẹlu idi lati ọdọ ijọba ipinlẹ naa.
BBC gbọ pe Ọjọbọ, ọsẹ to kọja ni mọlẹbi Fusengbuwa kede sita pe ipade lati yan awọn to kaju oṣuwọn fun ipo Awujalẹ ti Akilẹ Ijẹbu yoo waye.
Aṣẹ ti ijọba ipinlẹ Ogun pa, la gbọ pe o waye lati le ṣabojuto ilana to yẹ, eyi ti ko nii si ojusaaju ninu eto lati yan ọmọ oye, ati nipa titẹle ofin ti ko nii pada gbe wọn de ile-ẹjọ.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe awọn ti ko din ni ọgọta ni wọn ti fi erongba wọn lati de ori itẹ Awujalẹ, to fi mọ agba olorin Fuji nni, Wasiu Ayinde tọpọ mọ si Kwam1.
Lẹta naa ti agbẹnusọ mọlẹbi Fusengbuwa, Abiodun Ogidan fi sita lọjọ kọkanla, oṣu Kejila, ọdun 2025, o jẹ ko di mimọ pe awọn mọlẹbi tiwọn buwọ lu nikan ni ipade naa wa fun
Bakan naa lo tun sọ pe ọmọ oye kọọkan gbọdọ ni aṣoju meji-meji lati inu mọlẹbi gbọdọ wa nibi ipade ọhun, nigba ti ẹnikan yoo daba, ti ẹnikeji yoo si keji aba.
"Igbesẹ yii waye lati rii pe gbogbo nnkan lọ leto-leto bo ti yẹ''
Nigba ti ipalẹmọ n lọ lọwọ, la gbọ pe igbimọ to n ri si yiyan ọmọ oye tun gbe lẹta miran jade, iyẹn lọjọ Ẹti, wi pe awọn ti sun ipade siwaju.
"Si gbogbo ọmọ mọlẹbi Ọba Fusengbuwa ti Ijẹbu-Ode, nitori awọn ohun to waye, eyi to kọja agbara mọlẹbi wa, ipade mọlẹbi Fusengbuwa lati yan ọmọ oye, eyi a fi si ọjọ Aje, ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kejila, ọdun 2025 la ti sun siwaju," lẹta naa ka bẹẹ.
"A maa kede ọjọ tuntun miran laipẹ. A n rawọ ẹbẹ si ipalara ti eyi le mu wa."
Gbara ti lẹta naa ti jade sita ni awuyewuye ti n kaakiri wi pe agba olorin Fuji naa, Ayinde lo pe awọn mọlẹbi naa lẹjọ lori bi wọn ko ṣe fẹ ka a mọ ọkan lara wọn ninu mọlẹbi.
Alaga igbimọ olori ẹbi naa, Ọtunba Abdulateef Owoyemi nigba to n fidi lẹta naa mulẹ, o ni bi wọn ṣe sun ọjọ ipade siwaju ko ni ohunkohun lati ṣe pẹlu Wasiu Ayinde, bi ko ṣe pe wọn n gbiyanju lati tẹle ilana ti ko nii di ọrọ ile-ẹjọ.
Ọtunba Owoyemi sọ pe gbogbo ọna lawọn n wa lati ma ṣe jẹ ki aṣiṣe, kudiẹ-kudiẹ tabi awuyewuye ti yoo fa ki igbesẹ wọn de ile-ẹjọ nipa ifẹsunkan.
"Bi a ṣe sun ipade siwaju ko ni ohunkohun lati ṣe pẹlu ẹnikankan, ọrọ to jinna si otitọ ni. Ohun to ṣẹlẹ ni pe a gba iwe kan lati ọdọ ijọba fun ipade ti yoo waye lọjọ Iṣẹgun. Ipade naa lo si wa lati le ṣe ohun to tọ, ki gbogbo ilana ati akitiyan wa ma ba a ja si asan, tabi ko pada di ọrọ ile-ẹjọ," Ọtunba Owoyẹmi ṣalaye.
Alaga naa sọ pe igbesẹ naa tẹ gbogbo mọlẹbi lọrun, fun ijọba lati da si ohun ti wọn n ṣe, ki kudiẹkudiẹ ma ba a waye.
O tun fidi rẹ mulẹ pe Waisu Ayinde kii ṣe ọmọ agboole wọn, ati pe ko fi ibi kankan tan mọ idile wọn, fun idi eyi, o sọ pe ko ni ẹtọ lati jade fun ipo Awujalẹ labẹ aburada mọlẹbi fusengbuwa.
Bakan naa, igbakeji alaga mọlẹbi Fusengbuwa naa, Ọjọgbọn Fassy Yusuf fidi ayipada naa mulẹ, to si ni gbogbo awọn afọbajẹ patapata ni ijọba ti pe si ipade, to fi mọ igbimọ iṣakoso Awujalẹ.
"Ọpọ awọn nnkan ni a ko tii ṣe, fun idi eyi, ijọba lohun fẹẹ ṣe ipade pẹlu wa lọjọ Iṣẹgun. Awa idile ti ipo ọba kan, awọn afọbajẹ, to fi mọ igbimọ iṣakoso Ọba Awujalẹ ni yoo wa nibi ipade naa," Ọjọgbọn Yusuf ṣalaye.
Siwaju sii lo tun sọ pe "igbesẹ yii ni lati rii pe gbogbo nnkan lọ leto-leto bo ti yẹ, ati pe ohun ti a ba ba bọ nibi ipade naa ni yoo sọ ọjọ ti a maa fi ipade naa si."
O ni gbogbo awuyewuye wi pe nitori ẹnikan ni wọn fi sun ipade naa siwaju kii ṣe otitọ, bi ko ṣe pe iroyin ẹlẹjẹ lasan ni.















