Lẹ́yìn tí ìjọba Burkina Faso mú àwọn ọmọ ogun Naijiria mọ́kànlá, níbo ni wọ́n wà báyìí?

Awọn aṣoju Naijiria nibi ipade pẹlu Aarẹ Ibrahim Traoré ni Burkina Faso

Oríṣun àwòrán, YusufTuggar

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba ologun Burkina Faso ti tu awọn ologun Naijiria to fi si atimọle silẹ.

Igbeṣẹ yii lo n waye lẹyin ti Aarẹ Naijiiria, Bola Tinubu ran awọn aṣọju lọ si orilẹede Burkina Faso fun ijiroro lẹyin ti ijọba ilẹ naa.

Awọn aṣoju naa ni minisita fun ọrọ ilẹ okeere, Yusuf Maitama Tuggar dari wọn lati ba Aarẹ Burkina Faso, ọgagun Ibrahim Traoré ṣe ipade niluu Ouagadougou.

Nibi ipade naa ni Tuggar ti jiroro pẹlu Aarẹ ologun, Ibrahim Traoré, to si sọ nipa pataki ibaṣepọ to dan mọran laarin orilẹede adulawọ mejeji naa.

Aarẹ Burkina Faso naa ki awọn aṣoju Naijiria kaabọ, bẹẹ lo tun dupẹ lọwọ wọn fun ọrọ Aarẹ Bola Tinubu ti wọn fi ranṣẹ.

Nibi ipade naa ni ijọba orilẹede mejeji ti fẹnuko pe awọn yoo yanju ọrọ awọn ologun ọhun ni itubi inubi.

Awọn aṣoju ijọba naa tun yọju si awọn ologun ti wọn mu sọhun lati wo alaafia wọn.

Lẹyin ti wọn yọju si wọn tan ni wọn fidi rẹ mulẹ pe alaafia ni gbogbo wọn wa.

Tuggar ninu ọrọ rẹ sọ pe ijọba Naijiria ko ni yẹsẹ ninu afojusun rẹ lati ri daju pe ibaṣẹpọ to dan mọran wa laarin orilẹede mejeji.

O ṣalaye pe ijọba Naijiria ko ni yẹsẹ ninu ijiroro pẹlu ibaṣepọ pẹlu orilẹede naa fun alaafia, ilọsiwaju ati idagbasoke orilẹede mejeji.

Awọn aṣoju Naijiria ni Burkina Faso

Oríṣun àwòrán, YusufTuggar

Nibo ni awọn ologun naa wa bayii?

Gẹgẹ bii ohun ti a mọ, wọn ti tu awọn ologun naa silẹ ni ahamọ amọ wọn ṣi wa lọhun, alaafi ni wọn wa, wọn ṣi n pada bọ nile laipẹ ọjọ.

Alkasim Abdulkadir to n gbẹnusọ fun minisita ọrọ ilẹ okere, Yusuf Maitama Tuggar, lo fidi ọrọ naa mulẹ.

O ni "wọn maa pada si Naijiria, amọ wọn ko tii pada.

Bi awọn ologun Naijiria ṣe ha si Burkina Faso

Ede aiyede yii bẹrẹ lẹyin ti baalu ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria, Nigerian Air Force C-130 balẹ si orilẹeede naa lasiko to n fo lọ si Portugal.

A gbọ pe awọn ologun ọhun ko kọkọ gba aṣẹ ki wọn to balẹ sibẹ ati pe ọmọ ogun Naijiria mọkanla lo wa ninu baalu ọhun.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu Naijiria, Ehimen Ejodame sọ lẹyin iṣẹlẹ naa to waye ni nnkan bii ọsẹ meji ṣeyin pe, niṣe ni baalu naa yọnu ki wọn to gbe igbesẹ pajawiri lati balẹ sibẹ.

Amọ nigba to n fesi, Assimi Goita, to gbẹnusọ lorukọ ijọba Burkina Faso ni o lodi si ofin irinajo ofurufu bi baalu ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ṣe balẹ sibẹ, ati pe wọn laṣẹ lati kọju ija si baalu ọhun.