Mi ò ní fi PDP sílẹ̀ láti darapọ̀ mọ́ APC láí – Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
Gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo ti ni oun ko ni fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.
Makinde sọ pe oun ko ni kuro ni PDP bo tilẹ jẹ pe oniruru iṣọro lo n ba ẹgbẹ naa finra lasiko yii.
Gomina ọhun lo sọ ọrọ naa niluu Abuja nibi ti wọn ti n ko iwe kan, 'Headlines and Soundbites: Media Moments that Defined an Administration', jade, eyii ti minisita fun eto iroyin tẹlẹ, Lai Muhammed kọ.
Lasiko to n ba awọ eeyan to wa nibé, ti pupọ wọn jẹ oloṣelu sọrọ, Makinde sọ pe ọun ko ṣetan lati tẹle eyikeyi ninu awọn gomina PDP to n darapọ mọ APC.
O ni "Iwe ti a wa ko jade nibi ni mo wa fun. Mi o kii ṣe ọmọ ẹgbẹ APC mi o si ṣetan lati darapọ mọ APC."
Ninu alaye rẹ, Makinde ni idagbasoke ko le waye ni Naijiria ti awọn adari ko ba fọwọsowọpọ pẹlu ara wọn lai wo ti ẹgbẹ oṣelu ti wọn wa.
Makinde sọ pe idi ti Naijiria ko fi toro ni ai si irẹpọ laarin awọn adari ti wọn jẹ oloṣelu eyii ti ko ṣe awọn araalu lanfani kankan.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, pupọ ninu awọn ọmọ Naijirai ni wọn n fẹ ibaṣepọ to dan mọran laarin ara wọn amọ afojusun awọn oloṣelu lati jẹ adari ni gbogbo ọna ati bi wọn ṣe n lo ẹya ati ẹsin lo n fa ipinyan laarin araalu.
Ọrọ Makinde yii lo n jade lẹyin rogbodiyan inu ẹgbẹ oṣelu PDP.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ibi ipade gbogbogbo ẹgbẹ naa to waye niluu Ibadan ni igun ẹgbẹ ọhun to wa lẹyin Makinde ti yọ Nyesom Wike bii jiga kuro ninu ẹgbẹ
Ọsẹ kan lẹyin naa ni igun ẹgbẹ naa to wa lẹyin Wike naa tun yọ Seyi Makinde bii jiga nibi ipade rẹ to waye niluu Abuja.
Wayi o, ṣe lo da bii pe ẹgbẹ oṣelu APC lo n janfani rogobodiyan inu ẹgbẹ PDP naa.















