Wo bí òfin tí Trump ṣẹ̀ṣẹ̀ fi de Naijiria àtàwọn orílẹ́èdè mii ṣe kàn ọ́

Oríṣun àwòrán, Donald Trump/Facebook/Bola Ahmed Tinubu/X
Aarẹ Donald Trump orilẹede Amẹrika ti fofin de isọri awọn eeyan kan lati Naijiria atawọn orilẹede mẹrin mii pe wọn o gbọdọ wa si orilẹede Amẹrika mọ.
Ileeṣẹ ijọba Amẹrika, White House, sọ pe Trump gbe igbesẹ yii lati le daabo bo awọn ọmọ orilẹede Amẹrika.
Ọjọ kinni oṣu Kinni ọdun 2026 ni Trump sọ pe ofin naa yoo bẹrẹ l'Amẹrika.
Trump tun kede awọn orilẹede bii Burkina Faso, Mali, Niger, South Sudan ati Syria atawọn to ba ni iwe irina Palestine pe Amẹrika ti fofin de wọn lati ma wọ orilẹede naa mọ.
Ijọba Trump tun ti fi Laos ati Sierra Leone sara awọn orilẹede to ti fofin de pata pata pe wọn o le wa si Amẹrika mọ.
Ileeṣẹ ijọba White House tun kede pe oun tun ti fofin de isọri awọn eeyan kan lawọn orilẹede mẹẹdogun mii ti Naijiria wa ninu wọn.
Ijọba Amẹrika ni awọn agbesunmọmi bii Boko Haram ati ISS si n ṣọṣẹ lẹkun aaringbungbun orilẹede Naijiria.
Ṣaaju ni Trump ti kilọ fun Naijiria lori bi eto aabo ṣe mẹhẹ nibẹ, nigba naa ni o sọ pe awọn alakatakiti ẹsin n ṣekupa awọn kristẹni ni Naijiria.
Trump ni ofin ti Amẹrika ṣẹṣẹ fi de awọn orilẹede kan ṣe pataki, lẹyin kudiẹ kudiẹ to n wa ninu bawọn olu ileeṣẹ Amẹrika ṣe n ṣayẹwo fawọn eeyan to fẹ wa si Amẹrika lawọn orilẹede agbaye.
Awọn oṣiṣẹ Amẹrika sọ pe orilẹede naa gbe igbesẹ yii tori bi ọpọ eeyan ṣe n pẹ l'Amẹrika ju bo ti yẹ lọ, awọn eeyan to lakọsilẹ to labawọn, iwa ajẹbanu ati bawọn agbesunmọmi ṣe n ṣọṣẹ.
Ikede yii waye lẹyin ti awọn agbofinro mu afurasi ọmọ Afghanistan kan lori ẹsun pe o yinbọn fun awọn ẹṣọ eleto aabo Amẹrika meji lasiko ti orilẹede naa n ṣe eto idupẹ.
Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ijọba White House fi sita eyi ti Aarẹ Trump buwọlu ni ijọba Amẹrika ti sọ pe awọn ti fofin de awọn orilẹede ti kudiẹ kudiẹ maa n saba ninu ayẹwo fisa wọn lati le daabo bo orilẹede Amẹrika.
Igba kẹta ree ti Trump yoo kede pe Amẹrika ti fofin de awọn orilẹede kan
Lasiko to jẹ aarẹ fun saa akọkọ lọdun 2017 ni Trump kọkọ kede iru ofin yii, eyi si di nnkan tawọn eeyan ṣewọde le lori tawọn mii si tun pe e lẹjọ.
Amọ, ile ẹjọ to ga julọ l'Amẹrika pada fọntẹ lu ofin naa nigba to ya.
Ileeṣẹ ijọba White House sọ pe ofin ti Trump kede yii yoo si wa sibẹ titi tawọn orilẹede tọrọ kan yoo fi ṣatunṣe.
Loṣu Kẹfa to kọja ni Trump kede pe Amẹrika ti fofin de awọn eeyan lati orilẹede mejila ati meje mii pe wọn o le wa si Amerika mọ.
Amọ, ofin yii ko kan awọn to ba ti ni iwe igbeluu lọwọ l'Amẹrika, atawọn to ba ti ni fisa lọwọ to fi mawọn elere idaraya to nilo lati rinrin ajo lọ si Amẹrika.
Awọn orilẹede ti Amẹrika ti fofin de pe wọn o le wọ orilẹede naa mọ
Afghanistan
Burkina Faso
Burma
Chad
Equatorial Guinea
Eritrea
Haiti
Iran
Laos
Libya
Mali
Niger
Republic of the Congo
Sierra Leone
Somalia
South Sudan
Sudan
Syria
Yemen
Awọn eeyan to n fi iwe irinna Palestine rinrin ajo
Awọn orilẹede ti Amẹrika fofin de isọri awọn eeyan kan nibẹ
Angola
Antigua and Barbuda
Benin
Burundi
Côte d'Ivoire
Cuba
Dominica
Gabon
The Gambia
Malawi
Mauritania
Nigeria
Senegal
Tanzania
Togo
Tonga
Venezuela
Zambia
Zimbabwe
Awọn ti ọrọ wọn yatọ
Turkmenistan















