Ooni Ile Ife fi oyè dá Ààrẹ Ghana lọ́lá, agbẹjọ́rò kan ti pè é lẹ́jọ́

Oríṣun àwòrán, Ooni Ile Ife
Agbẹjọro kan to n gbe niluu Ibadan, Wale Ojo-Lanre ti pe Ooni Ile Ife lẹjọ lẹyin to fi oye nla kan da Aarẹ Ghana lọla.
Igbesẹ yii lo n waye lẹyin ti Ooni fi oye Ifá Ọmọ Odùduwà da Aarẹ John Mahama lọla.
Ninu ẹjọ to pe nile ẹjọ giga kan niluu Ile Ife, agbẹjọro naa ni ki ile ẹjọ ọhun ṣalaye agbara ti Ooni ni lati fi oye da ẹni ti kii ṣe ọmọ Naijiria lọla.
Lara awọn ohun ti agbẹjọro naa n sọ ni pe Ooni Ile Ife ko lagbara lati fi Aarẹ orilẹede Ghana jẹ oye to fi da lọla.
Ninu iwe kan ti Ojo-Lanre ti bura nile ẹjọ ọhun, o fidi rẹ mulẹ pe Ooni ni Olórí Adé Gbogbo, ati Àrólẹ̀ Odùduwà nilẹ Yoruba.
"Ooni ko lagbara lati fi Aarẹ Ghana joye, Usi-Ekiti ni agbara naa wa"

Oríṣun àwòrán, Ooni Ile Ife
O fidi rẹ mulẹ pe agbara Ooni ko pin silẹ Yoruba nikan amọ o tun lọ de awọn agbabe mii lagbaye.
Sibẹsibẹ, agbẹjọro ọhun ni Ooni ko laṣẹ lati fi Aarẹ Ghana jẹ oye to fun.
Gẹgẹ bi ohun to sọ, agbara lati fi Aarẹ Ghana jẹ oye ọmọ Oduduwa ko si lọwọ Ooni, amọ ilu Usi-Ekiti ni agbara naa wa.
Agbẹjọro ọhun tẹsiwaju pe ilu naa ni agaba ọhun wa, kii si ṣe pẹlu ori ade rẹ tabi pẹlu aafin rẹ.
"Eremode lasan ni mo n ṣe o"
Amọ ṣa lẹyin to to pe ọjọ ọhun, agbẹjọro naa sọ pe ere lasan loun n ṣe.
O ni "Ẹ ma dan mi lohun o, ere lasan ni mo n ṣe."
Agbẹjọro naa fi kun pe ti Ooni Ile Ife ko ba le fi eeyan jẹ oye, ko si ori ade mii ti yoo tun le ṣe bẹẹ nilẹ Yoruba.
Ọjọ Aje, ọjọ karundinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2025 ti a wa yii ni Ooni fi ọkunrin naa joye ọhun niluu Ile Ife.
Nigba to n gba oye naa, Ọgbẹni Mahama sọ pe inu oun dun lati joye naa, ati pe o ṣe pataki ki ibaṣepọ to wa laarin Naijiiria ati Ghana ma bajẹ.
Lara awọn eeyan to wa nibi ifinijoye naa ni Aliko Dangote; Owa Obokun ilẹ Ijesa, Ọba Adesuyi Haastrup; Oloffa ilu Offa, Ọba Mufutau Gbadamonsi; Dele Momodu atawọn eeyan nla mii.















