Lẹ́yìn oṣù mọ́kànlá, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ padà sẹ́nu iṣẹ́ nípìnlẹ̀ Osun

Awọn oṣiṣẹ Ijọba ibilẹ ni ipinlẹ Osun ti bẹrẹ iṣẹ pada lẹyìn ti wọn ti wa ni ile fun osu mọkanla.
Ni ọjọ Aje, ọjọ Karun-un, oṣu Kiini ọdun 2026 ni awọn oṣiṣẹ naa pada sẹnu iṣẹ léyin ti ifanfa ti n waye laaarin ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party to n ṣejọba lọwọ ni ipinlẹ Osun ati ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC.
Ti ẹ ko ba gbagbe pe, ọjọ Keje, osu Keji ọdun 2025 ni awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ ni ipinlẹ Osun ti lọ si ọfiisi gbẹyin latari ifanfa to n waye lori awọn alaga ijọba ibilẹ.
Eyi ko sẹyin idajọ ile ẹjọ Kotẹmilọrun ti ilu Akure nipinlẹ Ondo to ni ki awọn alaga ijọba ibilẹ ti Gomina Ademola Adeleke fi ọwọ osi juwe ile fun pada si ọfiisi wọn ni ọjọ Kẹwaa, oṣu Keji ọdun 2025.
Ẹ o ranti pe ni kete ti Gomina Ademola Adeleke gba akoso ijọba ipinlẹ Osun ni o fi ọwọ osi juwe ile fun awọn alaga ijọba ibilẹ ti gomina ana ni ipinlẹ naa Gboyega Oyetola yan ko to kuro lori ipo.
Lẹyin naa ni Gomina Adeleke ṣe eto idibo ijọba ibilẹ miiran lati fi yan awọn kahunsilọ atawọn alaga mii ṣugbọn ti eyi ko tẹ awọn alaga ẹgbẹ oṣelu APC lọrun ti wọn si gba ile ẹjọ lọ lati pe igbesẹ naa nija.
Ile ẹjọ Kotẹmilọrun wa gbe idajọ kalẹ pe kawọn alaga APC naa pada si ọfiisi ṣugbọn idajọ naa ko tẹ awọn alaga PDP lọrun to si mu awuyewuye nla dani.
Awuyewuye naa da wahala nla silẹ nibi ti eeyan mẹfa ti padanu ẹmi wọn.
Eyi lo mu ki Gomina Adeleke paṣẹ pe ki awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ jokoo sile, ki wọn ma lọ sibi iṣẹ mọ nitori ati dena pipadanu ẹmi ati dukia awọn eeyan.
Amọ lẹyin osu mọkanla ti awọn oṣiṣẹ Ijọba ibilẹ naa ti wa nile bayii ni wọn pada si ẹnu iṣẹ wọn lọjọ Karun-un osu Kiini ọdun 2026.
Alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ sọrọ
Ṣaaju ni aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ ijọba ibilẹ ni Osun fi atẹjade kan sita pe ki gbogbo awọn oṣiṣẹ pada si ọfiisi koowa wọn.
Eyi lo mu BBC News Yoruba sabẹwo si ijọba ibilẹ Olorunda ati Osogbo lati lọ wo boya awọn oṣiṣẹ naa ti pada sẹnu iṣẹ.
A ṣawari rẹ pe awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ naa ti pada si sẹnu iṣẹ wọn.
Alaga ìjọba ibilẹ Olorunda, Kunle Kudaisi wa rọ gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ rẹ lati fi ọwọ sowọ pọ ba oun ṣiṣẹ lasiko yii.
Alaga Kudaisi, tun tẹsiwaju pe, ki awọn oṣiṣẹ Ijọba ibilẹ to kan eti ikun si ipada wọn si ọfiisi ki wọn tete pada si ọfiisi koowa wọn ki ọrọ wọn mọ ba gba ibomiran yọ fun wọn.
Ninu ọrọ rẹ, Arakunrin Nathaniel Ogungbangbe, ni inu oun dun bi awọn oṣiṣẹ Ijọba ibilẹ ni Osun ṣe ti pada si ọfiisi koowa wọn.
Aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ Ijọba ibilẹ naa ni iṣẹlẹ to waye lọdun to kọja ya oun lẹnu pe awọn alaga ẹgbẹ oṣelu APC ko ribi pada sẹnu iṣẹ wọn lẹyin ti ile ẹjọ Kotẹmilọrun ti dajọ wọn.
Nathaniel wa rọ gbogbo awọn oṣiṣẹ Ijọba ibilẹ Osun pe ki wọn ko fi ọkan balẹ bẹrẹ iṣẹ wọn.














