Sex drugs: Àjọ aṣọ́bodè gbẹ́sẹ̀ lé òògùn ìbálòpọ̀ tórí ayédèrú nọ́mbà NAFDAC

Oríṣun àwòrán, @Others
Ajọ aṣọ́bodè ti gbẹsẹ le ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu oogun Ibalopọ nipinlẹ Katsina tori ai ni nọmba ajọ NAFDAC gidi.
Alakoso eka Zone B ileeṣẹ aṣọbode Katsina, Useni Aliyu Olorukooba ṣalaye pe awọn ẹṣọ aṣọbode lo rẹ buru awọn to n gbe oogun Ibalopọ lọ sí Katsina.
Olorukooba ni oogun ti ko ni nọmba NAFDAC gidi yii le ni mílíọ̀nù mẹfa.
- Ọ̀fẹ́ ni ọkọ̀ ojú irin akérò yóò máa kó àwọn arìnrìnàjò lásìkò pọ̀pọ̀ṣìnṣin ọdún yìí - Ìjọba àpapọ̀
- Ènìyàn Mẹ́ta kú, Mẹrin Farapa bí ọkọ̀ ńlá ṣe rọ́lu àwọn ènìyàn ni Mokola ní Ibadan
- Ẹ fura àwọn agbésùmọ̀mi láti Mali fẹ́ wọ ìlú Abuja
- Ooni ṣẹ̀ṣẹ̀ fi ẹ̀bùn tuntun ta Olorì Naomi lọ́rẹ tán ní, ìfẹ́ wọn dúró, kò sí ìpínyà- Aàfin Oòdúà
- Mọ̀ síi nípa Olorì Abibat Nihinlola Adeyemi tó ti lo ọdún 60 gẹ́gẹ́ bíi olorì láàfin Alaafin Oyo
- Ta ni Ashley Folasade Adegoke ti ayé ń pariwo pé òun ni Olorì tó máa rọ́pò Naomi Silekunola?
O ni awọn oogun naa ni EJAC, Hympashy, Amipara, Bobarak ata ati ginseng coffee.
Olorukooba ni bi ọwọ ṣe tẹ awọn eeyan yii fihan pe ko sí iru idokowo t'awọn okọ nifayawọ le ṣe ti ko ni ja si pabo.
Olorukooba ni awọn ẹṣọ aṣọbode ko ni kaarẹ ninu akitiyan awọn lati dẹkun iṣẹ awọn onifayawọ..









