Christmas Eve message: Ìjọba àpapọ̀ ní ọ̀fẹ́ ni ọkọ̀ ojú irin akérò yóò máa kó àwọn arìnrìnàjò lásìkò pọ̀pọ̀ṣìnṣin ọdún

Nigeria railway

Oríṣun àwòrán, @OvieAli

Ijọba apapọ ti kede pe ọfẹ ni ọkọ oju irin akero yoo ba de fun gbogbo araalu lasiko pọpọṣinṣin ọdun Keresimesi.

Ikede yii lo jade lati ọọfisi ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri si ọrọ ọkọ oju irin akero ni Naijiria, NRC.

Wọn ni awọn gbe igbesẹ naa ki awọn araalu le ri aye lati rinriajo lọ ba awọn ẹbi wọn ṣe ọdun.

Agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Yakub Mahmood ni awọn ọkọ oju irin akero ti ọrọ naa kan ni eyii to n ko ero lati Abuja si Kaduna, Eko si Ibadan, Warri si Itakpe, Kano si Eko, Minna si Kaduna ati Abba si Port Harcourt.

Awọn eeyan le bẹrẹ si n wọ ọkọ oju irin naa lọfẹ lati ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kejila, ọdun 2021, titi di ọjọ kẹrin, oṣu Kinni, ọdun 2022.

Àkọlé fídíò, Èmi nìkàn kọ́ ni mó n ṣe àkójọ orin- Fasoyin

Amọ NRC sọ pe gbogbo awọn arinrinajo ti ọrọ naa kan gbọdọ gba tikẹẹti, bo tilẹ jẹ pe wọn ko ni san owo tikẹẹti naa.

NRC tun sọ pe gbogbo awọn arinrinajo gbọdọ tẹlẹ awọn ilana to rọ mọ Covid-19.

Àkọlé fídíò, Christmas:Ṣé ẹ ti ra fìlà ọdún?

Lẹyin naa ni wọn rọ awọn araalu lati fi akoko ti wọn n wọn ọkọ oju irni ọfẹ naa gbadura fun alaafia ati ilọsiwaju Naijiria.