Queen Naomi Adeyeye Ogunwusi Kí ẹnikẹ̀ni máṣe pè mí ní 'Ìyàwó Ooni Ilé Ife' mọ́ -Olorì Silekunola Naomi Ogunwusi

Ooni ati Yeyeluwa

Oríṣun àwòrán, HM. Queen Evang. Silekunola Moronke Naomi Ogunwusi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Nnkan n ṣẹ laafin Ọọni ile ifẹ pẹlu bii Olori Yeyeluwa ti ilẹ ifẹ, Naomi Ogunwusi ṣe bọ sita lori ayelujara lati fọn rere rẹ faye gbọ pe lwọ yii, ki ẹnikẹni maṣe pe oun ni 'Iyawo Ọọni ile Ifẹ tabi gẹgẹ bi Olori ile Ifẹ.'

Ninu atẹjade kan to fi sita loju opo Facebook rẹ, Olori Silẹkunọla Naomi Ogunwusi ṣalaye pe Oun fẹ bẹrẹ ipele tuntun ninu irinajo aye oun ti oun yoo si ti omiran pa.

Olori Silẹkunọla

Oríṣun àwòrán, @Ooni

Kí ló tún ń ṣẹlẹ̀ láàfin Ooni Ife báyìí o?

"Emi, lọwọ yii kede pe mi o ni fẹ ki ẹnikẹni o pe mi ni iyawo Ọọni ile Ifẹ tabi Olori Ile- Ifẹ bikoṣe Olori gbogbo eeyanati iya ọmọmi."

Atẹjade naa ti Olori fi sita ti n fa ọplọpọ awuyewuye. amọṣa, ki lawọn ọrọ to jẹyọ ninu atẹjade Olori Silẹkunọla?

Se tori iroyin obinrin miran ni Olori fi n sun siwaju ni?

Ọpọ iroyin lo ti n kaakiri pe bi awọn obinrin miran ṣe n yọju ninu aye Kabiyesi Ọọni Ifẹ lo mu ki Olori o fariga bayii.

Aworan atẹjade Olori Naomi Ogunwusi

Oríṣun àwòrán, Olubayode Alebiosu

Amọṣa Olori Naomi Ogunwusi ni lootọ oniruuru gbọyisọyi ati nnkan lo n waye, ṣugbọn "oun ko gbe igbesẹ ati sun siwaju nitori pe Ọọni ni iyawo miran nitoripe ni gbogbo asiko ti a gbe pọ gẹgẹ bi lọkọlaya, emi nikan ni iyawo to fẹ niṣu lọka."

Ifẹ ni mo fi fẹ Ọọni kii ṣe iran

Ooni ati Yeyeluwa

Oríṣun àwòrán, HM. Queen Evang. Silekunola Moronke Naomi Ogunwusi

Ninu atẹjade ti Yeyeluwa fi sita, o ni lara awọn nnkan ti oun yoo gbiyanju lati fọ mọ. O ni oun ko lọ ba kabiyesi nitori iran kankan gẹgẹbi awọn eeyan kan ṣe n sọ kiri.

Ati pe Kabiyesi gan lo kọkọ dẹnu ifẹ kọ oun.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Olori Ogunwusi ṣalaye siwaju sii pe oun ko mọwolii obinrin kankan ninu irinajo ifẹ oun pẹlu Ọọni.

"Mi o mọ wolii obinrin ti wọn sọ pe o mu emi ati Kabiyesi mọra. Kabiyesi gan lo mu mi mọ wolii obinrin naa lẹyin ti mo ti gba lati fẹ ẹ. Mo kan bọwọ fun kabiyesi ni."

Olori Silẹkunọla

Oríṣun àwòrán, HM. Queen Evang. Silekunola Moronke Naomi Ogunwusi

Se lootọ ni Olori ti loyun ri?

Bakan naa ni Olori Silẹkunọla pẹlu tun ṣalaye pe ohun ti awọn kan n sọ pe oun ti bi ọmọ obinrin kan ri tẹlẹ ki oun to fẹ Ọọni kii ṣe otitọ.

Àkọlé fídíò, Parental Guidance: Ọdún méjì ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọmọ nípa ìbálòpọ̀

O ni ọmọbinrin ti wọn n pe ni mọ oun kii ṣe bẹẹ bi ko ṣe ọmọ ibatan oun.

"Mi o ni oyun ri laye mi ṣaaju oyun Tadenikawo; ọmọ mi kunrin ni oyun akọkọ ti mo ni ri laye mi ti iwe ayẹwo awọn dokita si wa lati fi idi rẹ mulẹ."