Drunk driving: Mu pàrágá wakọ̀ l'Oyo, kóo kó sí gbaga ìjọba

Igo ọti lọwọ awakọ

Oríṣun àwòrán, Other

Omi tuntun ti ru, ẹja tuntun ti wọ ọ ni ipinlẹ Oyo. Awakọ mẹẹdọgbọn ni ọwọ ofin ti tẹ nipinlẹ naa lori ẹsun pe wọn n muti nigba ti wọn tun n wa ọkọ.

Kọmiṣọnna nipinlẹ naa lasiko ọhun, ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe igbesẹ yii yoo jẹ ẹkọ fawọn awakọ mii ti wọn ba tun fẹ hu iru iwa bẹẹ.

Ajọ to n ri si idari ọkọ ni ipinlẹ Oyo, OYRTMA mu awọn awakọ naa pẹlu iranlọwọ ẹrọ igbalode to le ṣafihan bi eeyan ba mu ọti.

O sọ pe gbogbo awọn awakọ mẹẹdọgbọn naa ni yoo foju ba ile ẹjọ.

Kọmiṣọnna ni ile ẹjọ si ni yoo sọ pato ijiya to tọ si wọn.

Àkọlé fídíò, Wa ko iṣẹ ọwọ nipa lilo ede Yoruba

O tun fi kun ọrọ rẹ pe mimu awọn awakọ to n mu ọti kii ṣe ninu asiko pọpọsinsin nikan.

O ni eto naa yoo tẹsiwaju ninu ọdun 202i nitori ẹmi awọn eeyan ipinlẹ jẹ ijọba Gomina Ṣeyi Makinde logun.

Awọn oṣiṣẹ OYRTMA

Oríṣun àwòrán, Facebook/Inside Oyo

Ẹwẹ, alaga OYRTMA ṣalaye pe igbesẹ ajọ wọn lati mu awọn ọmuti awakọ wa ni ibamu pẹlu iṣẹ ajọ naa lati dẹkun ijamba ọkọ tawọn ọmuti awakọ n ṣe okunfa rẹ nipinlẹ Oyo.

O fi kun ọrọ rẹ pe ni opopona Ring-Road, Iwo-Road, ati Moniya si Ogbomoso ni wọn ti mu awọn awakọ ọhun.