New Zealand cigarettes ban: Orílẹ́èdè New Zealand ṣetán láti fòfin de sìgá pátápátá

Oríṣun àwòrán, otehrs
Orilẹ ede New Zealand ti ṣetan lati fi ofin de siga mimu patapata fun iran ọmọ wọn to n bọ ni orilẹ ede naa.
Pẹlu ofin ti ijọba fẹ ṣe agbekalẹ rẹ yii, gbogbo ọmọ ti wọn ba bi lẹyin ọdun 2008 ko ni lanfaani lati ra siga ni gbogbo ọjọ aye wọn ti ofin naa ba ti bẹrẹ lati ọdun to n bọ.
Minisita eto ilera, Dokita Ayesha Verall ni ijọba n gbero lati ri pe awọn ọdọ orilẹ ede New Zealand ko mo mu siga rara.
- Àwọn akọrin ìjọ tó fẹ́ lọ ṣe ìgbéyàwó kàgbákò òjò àrọ̀rọ̀dá, ẹ̀mí 23 sọnù...
- Ẹ̀ wo bàbá àgbàlagbà tó lo ayédèrú apá nitorí kò fẹ́ gba abẹrẹ́ àjẹsára Covid-19
- Wó ìgbésẹ̀ táwọn ọlọ́pàá gbé níwájú iléẹ̀kọ́ Dowen College tí Sylvester Oromoni tó kú lọ
- "Àwọn agbésùmọ́mí ló ń ṣe ìjọba lé wa lórí, kìí ṣe ìjọba Nàìjíríà tí Buhari ń darí"
- Ilé ẹjọ́ ti pàṣẹ tuntun fún ọ̀ga ọlọ́pàá Nàìjíríà lórí Rahmon Adedoyin tí Timothy Adegoke kú sí ilé ìtura rẹ̀
Igbesẹ yii wa lara awọn ọna ti ẹka eto ilera fẹ gba lati kasẹ siga mimu nilẹ ni New Zealand.
Ọpọ awọn dokita at'awọn eleto ilera lo ti lu ijọba lọgọ ẹnu lori igbesẹ naa.
Ni bayii, ida mẹtala ninu ọgọrun awọn agba lorilẹ ede New Zealand lo n mu siga.
Ida mejidinlogun ni o n mu siga níbẹ ni bi ọdun mẹwàá sẹyin.
Ṣugbọn awọn to n mu siga níbẹ bayii ti di idà mokanlelọgbọn papaa julọ laarin awọn ẹyà Maori.
Ẹka eto ilera ni siga mimu lo n fa ọkan lara eeyan mẹrin to n ni arun jẹjẹrẹ ni New Zealand.
Ni bayii, ijọba ti kede adinku awọn ṣọọbu ti wọn ti n ta siga lati ẹgbẹrun mẹjọ si ẹẹdẹgbẹta.















