Timothy Adegoke: Ramon Adedoyin ní òun láìsàn kan fún ọgbọ̀n ọdún ni ilé ẹjọ́ bá pàṣẹ fún ọ̀ga ọlọ́pàá Nàìjíríà kó fún un láàyè

Oríṣun àwòrán, Rahmon Adedoyin /Timothy Adegoke/ facebook
Ile ẹjọ apapọ nilu Abuja ti paṣẹ fun ọga ọlọpaa patapata lorilẹede Naijiria, lati fun oloye Ramon Adegoke Adedoyin lanfani lati lọ tọju ara rẹ ni ileewosan yoowu to ba fẹ.
Onidajọ Inyang Ekwo pa aṣẹ yii ninu ẹjọ kan ti adedoyin pe niwaju ile ẹjọ naa.
Oloye Ramon Adegoke Adedoyin lo ni ile itura Hilton hotel to wa nilu Ile ifẹ nibi ti wọn pa Timothy Adegoke to n kẹkọọ lati gba imọ kun imọ Masters ni fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ OAU nilu Ile ifẹ si.
Adajọ naa rọ ọga ọlọpaa Naijiria lati fun oloye Adedoyin lanfani lati lọ gba itọju ni ileewosan to baa wu U titi digba ti wọn ba pari iwadii tabi ti igbẹjọ ba bẹrẹ.
Ohun ti agbẹjọro oloye Ramon Adedoyin sọ nipa ilera rẹ
Agbẹjọro fun Adedoyin, amofin agba Kunle Adegoke SAN ṣalaye fun BBC News Yoruba pe o ti to ọgbọn ọdun ti oloye Adedoyin ti n ba aisan itọ ṣuga ati ẹjẹ riru finra to si nilo itọju loore koore ko ma baa di pe airi itọju lee mu ẹmi rẹ lọ ki ile ẹjọ to wa ri aridaju ẹjọ naa.
O ni ohun meji ni Oloye Adedoyin beere niwaju ile ẹjọ naa
"Ninu ki wọn o fi silẹ di igba ti wọn yoo ṣetan lati fi ẹsun kan an tabi ki wọn o fun un laaye lati lọ gba itọju to peye."
O ni ni ọjọ kẹrinlelogun oṣu kọkanla ọdun 2021, Oloye Ramon Adedoyin ṣubu lulẹ ni ahamọ awọn ọlọpaa to jẹ pe ileewosan awọn ọlọpaa to wa ni agbegbe Okefia ni ilu Oṣogbo ni wọn gbe e lọ eyi to ni ko kun oju iwọ to fun afurasi naa.
O fi kun un pe Oloye naa ti joro tan ni ahamọ awọn agbofinro ki ile ẹjọ to gbọ awijare wọn to si "fun un laye lati lọ tju ara rẹ tori pe oku o kii n dahun ẹsun"













