Buhari's warship lagos visit: Ìlú Eko yóò gbàlejò Àarẹ Muhammadu Buhari lónìí

Oríṣun àwòrán, Garba Shehu
Aarẹ Muhammadu Buhari yoo gunlẹ si ipinlẹ Eko lonii, ọjọ kẹsan an, oṣu Kejila, ọdun 2021 yii lati ṣi awọn akanṣẹ iṣẹ kan.
Awọn akanṣẹ iṣẹ naa ni ọkọ oju mi ileeṣẹ awọn ọmọ ogun ori omi.
Bakan naa ni Aarẹ yoo tun yọju sibi ayẹyẹ kan ti yoo waye ni gbọgan ile itura Eko Hotels.
- Gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ nínú ikú Sylvester Oromoni kò ní lọ láì jìyà lábẹ́ òfin - Buhari
- Ẹ̀jọ́ àtí ìwádìí ikú Timothy Adegoke ti kúró lọ́dọ̀ọ wa nípinlẹ̀ Osun- Agbẹnusọ Ọlọ́pàá Oṣun
- Mọ̀ síi nípa abẹ́rẹ́ àjẹsara tó jẹ́ dandan: Wo ìdí mẹ́ta tí àwọn kan ṣe nífẹ̀ síi àti ìdí mẹ́ta tí àwọn ẹlòmíì kò ṣe gbà á
- Ìjọba ti iléẹ̀kọ́ Ojodu pa, Ó ní àlàyé ohun tó ṣókùnkùn nípa ìjàmbà tírélà tó pa akẹ̀kọ̀ọ́ níbẹ̀ ńbọ̀ láipẹ̀
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí tí wọ́n fẹ̀sùn ikú Demilade, ọmọ ọdún méje tí wọ́n bá òkú rẹ̀ nínú 'cooler' lẹ́yìn tó dàwátì ní Ado-Ekiti
- Ẹnikẹ́ni kò ní lè yọjú síbi ayẹyẹ kankan l'Eko láì fi ẹ̀rí hàn pé ó ti gbabẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19- Sanwo-Olu
Tunde Rahman, to jẹ agbẹnusọ aṣaaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu lo kede abẹwo naa ninu atẹjade kan.
Gẹgẹ bii ohun ti Rahman sọ, Buhari yoo yọju sibi ayẹyẹ iwe lori igbeaye alaga fidihẹ ẹgbẹ oṣelu APC, Bisi Akande, eyii ti yoo waye nile itura Eko Hotels lagbegbe Victoria Island.
Lara awọn ti yoo wa nibi ayẹyẹ naa ni gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu pẹlu BolaTinubu funra rẹ.
Ẹwẹ, ileeṣẹ to n ri si eto irinna ni ipinlẹ Eko ti kede pe awọn yoo ti awọn ojun naa ka pa fun nnkan bii wakati mẹrin lasiko ti Aarẹ yoo fi wa l'Eko.
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ naa fi sita, wọn ni awọn yoo dari irinna ọkọ lati Ahmadu Bello Way si Adeola Odeku, to fi mọ Adetokunbo Ademola lati aago mẹjọ aarọ si aago meji ọsan.
Kọmiṣona eto irinna, Federic Oladenhinde ṣalaye pe awọn yoo dari awọn ọkọ to yẹ ko gba awọn oju ọna ọhun si awọn agbegbe miran.
O fi da awọn olugbe ilu eko loju pe awọn yoo gbiyanju lati ri pe ko si sunkẹre-fakẹrẹ ọkọ lasiko abẹwo Aarẹ.















