Ojodu accident: Ìjọba ti iléẹ̀kọ́ Ojodu pa, Ó ní àlàyé ohun tó ṣókùnkùn nípa ìjàmbà tírélà tó pa akẹ̀kọ̀ọ́ níbẹ̀ ńbọ̀ láipẹ̀

Ojodu accident

Ijọba ipinlẹ Eko ti gbe ileewe girama, Bab Fafunwa Millennium School, Ojodu ti pa di oṣu kini ọdun to n bọ.

Kọmiṣọna feto Ẹkọ, Fọlashade Adefisayọ lo kede eyi lasiko to ṣe abẹwo si ileewe naa lowurọ ọjọru.

Ọkọ tirela kan lo lọkọlu awọn akẹkọọ ileewe naa to si pa ninu wọn ti ọpọlọpọ si tun farapa yanayana.

Kọmiṣọnna, Adefisayọ ṣalaye pe ijọba yoo gbe atẹjade to kunna jade laipẹ ninu eyi ti iye awọn akẹkọọ to ku yoo ti jẹyọ ti yoo si tun ṣalaye awọn nnkan miran to ṣokunkun nipa iṣẹlẹ naa jade.

Iroyin sọ pe awọn oṣiṣẹ ajọ oju popo kan ni wọn n le awakọ tirela naa ki o to lọ kọlu awọn akẹkọọ naa, ṣugbọn ajọ ẹṣọ oju popo apapọ, FRSC ati ti ipinlẹ Eko LASTMA ni wọn ti jade lati sẹ kanlẹ pe awọn ko lọwọ ninu ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ buruku naa.

Àkọlé fídíò, Mama Deeper Life Ondo

Ọlọpaa ti sọ iye awọn akẹkọọ ti ijamba naa kan

Awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Eko ti sọ pe akẹkọọ meji lo ku ninu ijamba ọkọ tirela to kọlu awọn akẹkọọ ileẹ̀kọ́ girama lagbagbe Ojodu nilu Eko lọjọ Iṣẹgun.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Adekunle Ajiṣebutu ṣalaye pe awọn mejila ninu awọn akẹkọọ naa ni wọn farapa.

Ọga ọlọpaa Ajiṣebutu ṣalaye pe ijanu ọkọ tirela naa lo kọṣẹ silẹ ti ọkọ naa fi yawọ mọ awakọ rẹ lọwọ.

Àkọlé fídíò, FUTA First Class Twins

"Ijamba ọkọ naa ja si iku akẹkọọ ọkunrin meji loju ẹsẹ, akẹkọbinrin meje ati akẹkọọkunrin marun, to mu ki apapọ wọn jẹ mejila ni wọn farapa loniranran."

Akẹkọọ ileewe girama, Bab Fafunwa millennium school, Ojodu ti orukọ rẹ n jẹ Ojodu Grammar school tẹlẹ ni gbogbo awọn akẹkọọ ti ọrọ kan naa.

Amọ̀ṣa, awọn eeyan kan ti ọrọ naa ṣoju wọn n sọ pe iye awọn akẹkọọ to ba ijamba naa lọ to mẹtadinlogun.

Ara awon oko ti won baje

Oríṣun àwòrán, RRS Police

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ n kọlu àwọn ọkọ̀ nla ní Ojodu-Berger, nítorí àwọn akẹgbẹ́ wọn ti ọkọ̀ pa lánàá

Rogbodiyan tun ti bẹrẹ ni agbegbe Ojodu-Berger, nibi ti ọkọ akẹru ti kọlu awọn akẹkọọ lọjọ Iṣẹgun.

Ileeṣẹ ọlọpaa RRS sọ ninu ikede kan to fi si ori Facebook pe niṣe ni awsn akẹkọọ tu jade si opopona Ogunnusi nitosi ọfiisi ajọ FRSC, ti wọn si bẹrẹ si ni ba awọn ọkọ akẹru to n lọ jẹ.

Niṣe ni wọn n fọ awọn gilaasi awọn ọkọ nla to n kọja loju opopona ọhun.

Àkọlé fídíò, Afeez Akintunde: Àwọn ẹbí Tula Oyo figbe tá pé kò ní ohunkohun ṣe pẹ̀lú Yoruba Nation

Ọwọ́ ọlọ́pàá ti tẹ awakọ̀ tírélà tó gbá akẹ́kọ̀ọ́ mérìnlá nílùú Eko

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti kede pe ọwọ awọn ti tẹ awakọ tirela to gba awọn akẹkọọ kan lagbegbe Ojodu lọjọ Iṣẹgun.

Ninu atẹjade ti alukoro ileeṣe naa l'Eko, Adekunle Ajisebutu fi ṣọwọ si awọn akọroyin lo ti kede bẹẹ.

Ajiṣebutu sọ pẹ akẹkọọ meji lo ku lẹsẹkẹsẹ ti ijamba ọkọ naa waye, ti awọn akẹkọọ mejila mii si farapa yanayana.

Atẹjade ọhun ni "Ọkọ tirela kan ti orukọ awakọ rẹ n jẹ Bolaji Kabiru ya bara, to si gba awọn ọmọ ile ẹkọ Bab Bafunwa Milenium School ti ọpọ mọ si Ojodu Grammar School ni nnkan bii aago meji abọ ọsan."

Àkọlé fídíò, Àwọn òṣìṣẹ́ Adedoyin jẹ́wọ́ fún wa pé àwọn pa àbúrò mi, ọ̀gá Adedoyin sì mọ̀ síi - Ẹ̀gbọ́n Timothy Adegoke

"Lẹṣe kan naa ti iṣẹlẹ naa wa ni akẹkọọ meji ti wọn jẹ okunrin gbẹmi mi, nigba ti awọn mejila miran, ti owọn jẹ binrin meje ati okunrin marun un farapa yanyana."

Àkọlé fídíò, Ṣé lọ́òtọ́ ọkọ àti ìyàwọ́ ní Mr & Mrs Kogberegbe? Àṣírí bí a ṣe ń ṣe ètò yìí rèé...

Ajisebutu sọ pe awọn oṣiṣẹ ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ri si irinajo oju popo lọ sibẹ ni kankan, wọn si ko oku awọn to jade laye lọ sile iwosan Mainland Hospital to wa ni Yaba, nigba ti wọn ko awọn to farapa lọ sile iwosan God's Apple City Hospital ati Michael Hospital to wa ni Ojodu, to fi mọ ile iwosan iṣẹlẹ pajawiri ti ijọba ipinlẹ Eko to wa ni Toll Gate.

Àkọlé fídíò, Mama Deeper Life Ondo

Bo tilẹ jẹ pe o ni awọn ti fi ṣikun ofin mu awakọ tirela naa, awọn akẹkọọ ti akẹgbẹ wọn ku atawọn araalu kan ti fi ibinu dana sun ọkọ tirela ọhun.

O fi kun pe awọn akẹkọọ naa atawọn janduku tun ṣakọlu si agọ ọlọpaa to wa ni Ojodu, nibi ti wọn ti ni ki awọn ọlọpaa yọnda awakọ naa fun awọn ki wọn le da seria fun.

Àkọlé fídíò, A kò tíì dẹ́kun àdúrà pé kí àṣírí àwọn tó jí ọmọ gbé tú - Bisola Alfa Sotitobire

Ajisebutu sọ pe awọn eeyan naa ba ọpọ dukia jẹ ninu agọ ọlọpaa ọhun, eyii to mu ki kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Akeem Odumosu paṣẹ ki wọn ko awọn ọlọpaa kogberegbe lọ sibẹ ki ohun gbogbo le pada bọ sipo.

Àkọlé fídíò, Murphy Afolabi: Kò dùn mí tí wọn bá ṣe yẹ̀yẹ́ mi torí mò fi sí pe ṣí, èdè Osogbo ìlú mi ni

Lẹyin naa lo parọwa si awọ araalu lati gba awọn ọlọpaa laye lati ṣe iṣẹ wọn ki awọn le ri idi iṣẹlẹ ọhun.