Coronavirus in Nigeria: Àwọn ìpéjọpọ̀ ṣọ́ọ́ṣì àti ayẹyẹ nlá tí kò ní wáyé nítorí coronavirus

Oríṣun àwòrán, Twitter/rccg
Lẹyin ti ajọ eleto ilera agabye WHO ti kede arun Coronavirus gẹgẹ bi ajakalẹ arun, ọpọ awọn apero, ipade ati awọn ayẹyẹ miran to yẹ ko waye ni wọn ti gbe ṣegbẹ kan.
Bi ọrọ naa ṣe kan ọmọde lo kan agba, bo ṣe kan irinajo okeere naa lo kan ile iwe atawọn ile ijọsin.
Wọnyi ni awọn ipejọpọ nla mẹta to yẹ ko waye ni opin ọsẹ yii ni ipinlẹ Oyo, Ogun ati Eko, ṣugbọn ti awọn alamojuto wọn ti wọgile nitori arun Coronavirus.
Ayẹyẹ ọdun awọn ọmọ bibi ilu Ibadan

Oríṣun àwòrán, IbadanCity ANNOUNCER
Lẹyin awuyewuye to tẹle ipade ita gbangba ti ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe nilu Ibadan, ni ẹgbẹ ọmọ bibi ilu Ibadan, CCII, wọgile aṣekagba ayẹyẹ ilu ibadan ti wọn pinnu lati ṣe tẹlẹ.
Ayẹyẹ naa ti wọn pe ni 'Ibadan Week Celebration' ni wọn ti sun siwaju bayii nitori arun Coronavirus ọhun.
Ninu atẹjade kan ni ẹgbẹ CCII ti sọ pe awọn kọkọ n gbero lati ṣe ayẹyẹ naa pẹlu titẹle amọran awọn eleto ilera, ṣugbọn wọn yi ọkan wọn pada lẹyin apero laarin awọn adari ẹgbẹ naa, botilẹjẹ pe "wọn ti ra nkan ipawọ apakokoro, iboju ati irinṣẹ ayẹwo ilera".
Ipade adura ijọ Irapada Kristi (RCCG)

Oríṣun àwòrán, Twitter/rccghq
Alufaa agba ijọ Irapada Kristi l'agbaye, Pasitọ E.A Adeboye ti sun ipade adura nla kan to yẹ ko waye lọjọ Satide, ogunjọ oṣu kẹta ọdun 2020 siwaju.
Ọdọọdun ni ipade adura naa, ti wọn pe ni 'Emerge2020' maa n waye ni gbagede Tafawa Balewa Square nilu Eko.
Ninu atẹjade kan ni pasitọ Adeboye ti sọ pe "Ijọ gbọdọ tẹle ofin ti ijọba fi sita".
Ijọba ipinlẹ Eko sọ pe ki awọn eniyan o yago fun ipejọpọ to ba ti le ni aadọta eniyan.
Eto isin itusilẹ ijọ MFM
Eto itusilẹ yii ni ijọ Mountain of fire and miracles, MFM lero ati gbe ṣe ni opin ọsẹ yii tẹlẹ. Igba kan ni wọn si maa n ṣe laarin oṣu kan.

Oríṣun àwòrán, @Newsmongerng/Twitter
Ti oṣu kẹta yẹ ko waye ni ogunjs oṣu kẹta si ọjọ kejilelogun oṣu ọhun ṣugbọn nitori ajakalẹ arun Coronavirus bayii, wọn ti sun un siwaju.












