Afenifere korò ojú sí bí agbébọn ṣe gbẹ̀mí Kabiesi l'Ondo, ọlọ́pàá ṣèlérí ìdájọ́ òdodo

Oríṣun àwòrán, Molebi
Ẹgbẹ to n ja fun ẹtọ ọmọ Yoruba, Afenifere ti bu ẹnu atẹ lu bi agbebọn ṣe ṣekupa ori ade kan nipinlẹ Ondo, Alagamo tilu Agemo, Ọba Kehinde Falodun.
Ninu atẹjade kan ti akọwe ẹgbẹ naa, Jare Ajayi fi lede, o ni jẹ ohun ibanujẹ bi wọn ṣe lọ gbẹmi ọba naa ninu aafin rẹ.
Afenifere sọ pe asiko ti to bayii fun ijọba apapọ lati mu ọrọ idasilẹ ọlọpaa agbegbe lọkunkundun.
O ni bi awọn agbesunmọmi ṣe n gbẹmi eeyan ni Kwara, Kogi, Niger, Benue, Plateau, Kaduna, Katsina, atawọn ipinlẹ mii ni Naijiria jẹ ohun ti ijọba ko gbọdọ kawọ gbera lori rẹ.
Atẹjade naa sọ pe "Asiko ti to bayii fun idaslẹ ọlọpaa ipinlẹ, asiko ti to fun awọn ori ade atawọn adari lati ronu jinlẹ, asiko ti to fun awọn eleto aabo lati ji giri si iṣẹ wọn.
"Iṣẹlẹ yii kan wa gbọngbọn gẹgẹ bii Afenifere gẹgẹ bo ṣe kan ọmọ ilẹ Yoruba lapapọ.
"Idi ree ti a fi kesi ijọba ko tete wa nnkan ṣe si ọrọ naa ki awọn agbesunmọmi to sọ agbegbe wa di ibuba wọn.
A maa wa awọn to ṣiṣẹ naa ri ki wọn le foju wina ofin – Agbofinro
Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo atawọn agbofinro to ku ti ṣeleri lati ṣawari awọn to gbẹmi kabiesi ọhun.
Kọmiṣọna ọlọpaa ipinẹ Ondo, Adebowale Lawal lo sọ ọrọ naa lasiko to ṣabẹwo si ilu ti iṣẹlẹ ọhun ti waye.
Lawa tun ba awọn ẹbi oloogbe naa kẹdun pẹlu ileri pe idajọ ododo yoo waye lori iku rẹ.
Èèmọ́ rèé o, àwọn agbébọn ya wọ ààfin, ṣekúpa Ọba l'Ondo
Inu iberubojo ati ibanujẹ nla ni awọn araalu Agamo nijọba ibilẹ Ariwa Akure wa, bi awọn agbebọn ṣe sekupa ọba ilu naa Alagamo tilu Agemo, Ọba Kehinde Falodun.
Iṣẹlẹ yii waye ni asalẹ ọjọ Isẹgun ọsẹ yi, ọjọ kẹrindinlogun oṣu keji ọdun 2026 ni Afin ọba naa.
Awọn ẹbi Kabiyesi naa sọ pe awọn agbebọn naa ti wọn to mẹwaa ya wọ aafin ori ade naa ti wọn si pa si iwaju aafin rẹ.
Báwo ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé?
Awọn mọlẹbi ọba naa salaye pe awọn agbebọn yii wa pẹlu erongba lati ji Kabiyesi naa gbe, sugbọn ori ade ọun kọ jalẹ lati yọnda ara rẹ fun ijinigbe.
Ṣugbọn lẹyin eyi, wọn yin ibọn sì ọba naa, ni ọpọlọpọ ìgbà, ti ko wọle sì lara gẹgẹ bii a
se ti ri gbọ lati ọdọ awọn mọlẹbi ọba.
Igbesẹ yii lo mu ki wọn fi ikan miran gba ọba Falodun eyi to yọri si iku rẹ.
Wọn salaye pe ede Hausa ni awọn to ṣe ikọlu naa n sọ lasiko ti wọn wa sekupa ori ade naa.
Awọn mọlẹbi Kabiyesi wa rọ ijọba ati awọn esọ alaabo lati ri daju pe wọn sawari awọn to sọsẹ yii, ki wọn si fi panpẹ ọba mu wọn.
Kí ni Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá sọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà?
Ileeṣẹ Ọlọpaa Ipinlẹ Ondo ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, bi wọn ṣe sọ di mimọ pe, deedee ago meje kọja isẹju mẹwa ni asalẹ ni awọn agbebọn naa yabo Afin ọba Kehinde Jacob Falodun lati sekupa.
Ninu atejade latọwọ agbẹnusọ ileeṣẹ naa,Jimoh Abayomi salaye pe iroyin ti ọkan lara oloye ilu naa, Ajewole Clement fi to wọn leti sọ di mimọ pe awọn agbebọn bi mẹfa lo fi ipa wọ Afin naa ti wọn si mu ori ade ọhun kuro ni ayika Afin rẹ.
Wọn salaye pe lẹyin isẹju diẹ ni wọn ri oku ọba naa bi iwọn bata ẹsẹ diẹ si Afin naa pẹlu ọgbẹ ibọn lara rẹ.
Abayomi salaye siwaju pe kete ti iṣẹlẹ yii waye awọn ikọ ọlọpaa, Amọtẹkun ati awọn esọ alaabo miran yabo awọn igbo to wa ni ayika ilu naa lati sawari awọn amokuseka yi.
O fikun pe awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati sawari awọn to ṣe akọlu naa pẹlu ileri pe laipe lai jina ọwọ yoo ba wọn, wọn yoo si fi wọn jofin.
Abayomi wa fi ọkan araalu balẹ pe, Kọmisọna Ọlọpaa Adebowale Lawal ti saaju awọn esọ alaabo miran lati ṣe abewo si ilu Agamo ti iṣẹlẹ naa ti waye lati le ba awọn mọlẹbi ọba Falodun ati gbogbo ilu naa kẹdun.
Awọn to kọwọ rin pẹlu rẹ ni ọga agba 32 Brigade Artillery ikọ ologun orileede yi, Ọga agba ajọ NSCDC ati awọn ọga agba ajọ DSS lati le foju gan ni ohun ti o sẹlẹ n'ilu naa.
Ọga agba Ọlọpaa naa seleri pe gbogbo awọn esọ alaabo naa ni yoo fọwọsowọpọ lati ri daju pe ọwọ tẹ awọn to ṣe akọlu naa.



























