Wo àwọn ohun tuntun tó wà nínú òfin ètò ìdìbò tí Ààrẹ buwọ́lù

Awọn oludibo n dibo ni Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ana ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Keji, ọdun 2026 ni Aarẹ Bola Tinubu buwọlu atunṣẹ si ofin idibo Naijiria.

Ọdun 2022 ni wọn ṣe atunṣe si ofin naa gbẹyin ṣaaju idibo 2023 ki wọn to tun ṣe atunṣe tuntun ti ọdun 2026 yii.

Ṣaaju ki Aarẹ to buwọlu atunṣe naa lawọn ọmọ Naijiria kan ti bẹrẹ si n sọ pe ko gbọdẹ ṣe bẹẹ nitori awọn nnkankan to wa ninu rẹ ti ko ni ṣe ọmọ Naijiria lanfani.

Amọ ṣa, ọpọ ọmọ Naijiria ni ko tilẹ mọ nnkan to wa ninu atunṣe ofin ọhun rara.

Iwọnyii ni awọn ohun tutun to wa ninu ofin eto idibo Naijiria ti Aarẹ buwọlu lẹyin ọpọ awuyewuye.

  • Iwe iforukọsilẹ oludibo: Awọn ohun mẹta pere lọmọ Naijiria nilo bayii lati forukọsilẹ gẹgẹ bii oludibo; awọn nnkan naa ni iwe ẹri ọjọ ibi, iwe irinna Naijiria ati nọmba idanimọ NIN.
  • Kaadi idibo ori ayelujara: Awọn oludibo yoo lanfani lati lọ soju opo INEC lati gba kaadi ibibo wọn sori ẹrọ ilewọn wọn tabi ori kọmputa wọn.
  • Pinpin esi ibo lori ayelujara: O ti di dandan lati maa fi esi ibo ransẹ lori ayelujara pẹlu ẹrọ IReV. Amọ ti eyii ba kuna, wọn le lo fọọmu EC8A lati fi esi ibo naa ranṣẹ.
  • Idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu: Ẹni ti yoo ṣoju ẹgbẹ oṣelu ni wọn gbọdọ yan ninu eto idibo abẹle taara tabi ki ẹni naa ma ni alatako kankan ninu ẹgbẹ oṣelu rẹ.
  • Pinpin owo fun ajọ INEC: Ijọba apapọ gbọdọ fi owo eto idibo ṣowọ si ajọ INEC ni oṣu mẹfa ṣaaju eto idibo ọhun.
  • Awọn ẹgbẹ oṣelu gbọdọ fi orukọ oludije wọn ranṣẹ si INEC: Ofin naa ni gbogbo ẹgbẹ oṣelu gbọdọ fi orukọ ẹni ti yoo du ipo lorukọ ẹgbẹ naa ṣọwọ si INEC ni oṣu mẹrin ṣaaju eto idibo ọhun.
  • Ikede orukọ awọn oludibo: INEC gbọdọ kede orukọ gbogbo oludibo ni oṣu meji ṣaaju eto idibo.

Ninu atẹjade kan loju opo Facebok rẹ, ọkan lara awọn aṣofin naa, Natasha Apoti Uduaghan sọ pe awọn aṣofin ti ṣe ojuṣe ti wọn, bẹẹ ni Aarẹ naa ti ṣe ojuṣe tirẹ, o wa ku sọwọ awọn ọmọ Naijiria bayii lati kan an nipa fun ajọ INEC ki oun naa ṣe ijuṣe irẹ.