Andrew Mountbatten-Windsor dèrò àgọ́ ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn àṣìlò ipò

Andrew Mountbatten-Windsor

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe ọlọpaa ilẹ Gẹẹsi ti mu Andrew Mountbatten-Windsor lori ẹsun aṣilo ipo.

Ọlọpaa ni aburo Ọba Charles ilẹ Gẹẹsi naa ti wa lakata awọn, ọlọpaa si ti n yẹ ile rẹ wo ni Berkshire ati Norfolk.

Awọn aworan kan lori ayelujara ṣafihan bi awọn ọkọ naa ṣe de sile rẹ ni Sandringham Estate to wa ni Norfolk.

Eyii lo waye lẹyin ti ọlọpaa Thames Valley ni awọn ṣagbeyẹwo ẹsun ti wọn fi kan an lori pinpin awọn ohun ti ko yẹ ni pinpin toun ti Jeffrye Espstein, to jẹ ẹni to wu iwa ipa nipa ibalopọ.

Wọn ni iwadii ti bẹrẹ lori ọrọ naa.

Andrew to pe ẹni ọdun mẹrindinlaadọrin loke eepẹ lonii ti sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.

Dal Babu, to ti fi igba kan ri jẹ ọlọpaa sọ pe lati ọsẹ to kọja ni wọn ti wa lori ọrọ naa ki wọn to fi panpẹ ofin mu lonii.

Gẹgẹ bo sẹ sọ, ni bayi ti wọn ti fi ṣikun ofin mu, aye ti wa fun ọlọpaa lati lọ yẹ ori ẹrọ kọmputa rẹ wo fun aworan atawọn ẹri mii.

O fi kun pe ọlọpaa ṣi le lọ ṣayẹwo ile rẹ atawọn dukia mii to wa ni ikawọ rẹ ninu iwadii wọn.

Ofin gbọdọ fẹsẹ mulẹ - Ọba Charles

Lẹyin ti wọn mu tan ni Ọba ilẹ Gẹẹsi, Charles fi atẹjade kan lede lori bi ọlọpaa ṣe mu aburo rẹ Andrew.

O ni "O jẹ ohun to bu omi tutu si ọkan mi lati gbọ iroyin nipa Andrew Mountbatten-Windsor ati ẹsun aṣilo ipo.

"Gẹgẹ bi mo ṣe ṣo tẹlẹ, awọn agbofinro yoo ri atilẹyin ati ifọwọsowọpọ.

"Ki n sọ ni gbangba bayii: ofin gbọdọ fẹsẹ mulẹ lori ọrọ yii.

"Bi ọrọ yii ṣe n tẹsiwaju, ko ni tọ fun mi lati sọ ọrọ mii nipa rẹ mọ.

"Ẹwẹ, emi ati mọlẹbi mi yoo tẹsiwaju lati maa ṣe ojuṣe wa fun gbogbo yin.