Àlàyé lórí ohun tó ṣekúpa awakusà tó lé ní 30 lẹ́nu iṣẹ́

Awọn ero to n kẹdun awọn awakusa to ku.
    • Author, Mansur Abubakar
    • Reporting from, Abuja
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

O kere tan, awakusa mẹtalelọgbọn ni a gbọ pe kẹmika carbon-monoxide ti pa nibi ti wọn ti n wa nnkan alumọni lead ati Zinc ni ipinlẹ Plateau.

Awọn oṣoju-mi-koro ṣalaye fun BBC wi pe iṣẹlẹ ọhun naa waye ni bii iyalẹta lẹyin odi ilu Wase nipinlẹ Plateau.

Gaasi to lewu fun agọ ara ni a gbọ pe o ti ṣodo sinu ilẹ eyi to jẹ kawọn awakusa naa ṣubu sinu ilẹ lasiko ti wọn ti fẹ ṣiwọ iṣẹ alẹ.

Awọn to wọ iṣẹ laaarọ ọjọ keji ni wọn ri awọn to ti ku naa atawọn mii to le logun ti ẹmi ko tii bọ lara wọn.

Awọn to bẹrẹ iṣẹ ni aarọ naa lo gbe awọn ti ko tii ku lọ sile iwosan fun itọju.

Ẹwẹ, awọn ẹṣọ eleto aabo ti ta okun yika ibi iwakusa naa to to igba kilomita si ilu Jos tii ṣe olu ilu ipinlẹ Plateau.

Iwadii si ti bẹrẹ lori nnkan to ṣokunfa bi kẹmika naa ṣe jo sinu ilẹ to fi pada ṣakoba fawọn to n wa kusa.

Ohun ti a tun gbọ ni pe ijọba ipinlẹ naa ko tii ṣabẹwo sibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Agbegbe naa wa lara awọn agbegbe tawọn janduku agbebọn ti n ṣọṣẹ fun ọpọlọpọ ọdun ni ipinlẹ Plateau.

Safiyanu Haruna to jẹ ọkan lara awọn to ri oku awọn awakusa naa sọ pe awọn kan ti ilẹ ya lu moribọ, wọn si ti gbe wọn lọ sile iwosan.

''Kẹmika carbon-monoxide lo pawọn awakusa to ku''

Haruna ṣalaye wi pe ni nnkan bi ago mẹfa aabọ ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ nibi ti eeyan mẹtadinlogoji ti ku.

O ni lẹyin tawọn awakusa naa kirun tan laaarọ ti wọn pada sibi ti wọn ti n ṣisẹ ni iṣẹlẹ ọhun waye.

Ijọba Plateau ti sọ ṣaaju ninu atẹjade kan to fi sita pe eeyan mẹtalelọgbọn lo ku nibi iṣẹlẹ naa.

Amọ, awọn oṣiṣẹ awakusa to wa nibẹ sọ pe ọrọ ko ri bẹẹ rara.

Haruna ni ''kẹmika carbon-monoxide to n jo lo pawọn.

Ko si ẹni to le doola wọn nigba naa tori awọn to n bọ wa gba iṣẹ ko tii de.

O bani lọkan jẹ pe eeyan mẹtadinlogoji ti wọn n wa nnkan ti wọn fẹ jẹ pade iku ojiji.''

Awọn awakusa ọhun ti ọjọ ori wọn ko ju ogun ọdun si ogoji ọdun lọ ni wọn sin oku wọn ni ilana aṣa awọn eeyan agbegbe naa.

Iṣẹlẹ iku awọn awakusa maa n waye loorekoore lorilẹede Naijiria.

Ni nnkan bi ọdun meji sẹyin lawọn awakusa kan ku lẹyin ti ilẹ ya lu wọn mọlẹ nibi ti wọn ti n wa kusa nipinlẹ Niger.