Ṣé àhámọ́ DSS tàbí ICPC ni El-Rufai wà báyìí lẹ́yìn tó kúrò ní àtìmọ́lé EFCC? Ohun tí a mọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Mallam Nasir El-Rufai/Facebook
Gomina ipinlẹ Kaduna tẹlẹ, Malam Nasir El-Rufai ti dero ahamọ ajọ ICPC lẹyin to kuro ni atimọle ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ajẹbanu lanaa Ọjọru ọjọ kejidinlogun oṣu Keji yii.
Ṣaaju ni iroyin kan jade wi pe ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti nawọ gan El-Rufai lẹyin to kuro ni ahamọ EFCC tan.
Ajọ DSS fẹsun iwa ọdaran kan gomina ipinlẹ Kaduna tẹlẹ lori wi pe o tọwọ bọ foonu oludamọran aarẹ lori eto aabo, Nuhu Ribadu lọna aitọ.
Nigba to ya ni ajọ ICPC kede wi pe El-Rufai ti wa ni ahamọ awọn.
Ọgbẹni J. Okor Odey to jẹ alukoro ajọ ICPC sọ pe lalẹ Ọjọru ni El-Rufai de ahamọ ajọ naa.
Odey ni ajọ ICPC ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lori El-Rufai, amọ, ko ṣalaye nnkan ti iwadii naa da lori.
Ọjọbọ ọsẹ to kọja ni ede-aid-yede bẹ silẹ ni papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe l'Abuja nigba ti awọn oṣiṣẹ eleto aabo fẹ fọwọ ofin mu El-Rufai.
Lẹyin naa ni gomina ipinlẹ Kaduna tẹlẹ sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe lori tẹlifisan Arise wi pe Ridadu lo ni ki ajọ DSS mu oun ni papakọ ofurufu l'Abuja.
Nigba ti atọkun eto naa beere lọwọ rẹ wi pe bawo lo ṣe mọ, ni o dahun pe ẹnikan lo gbọ ọrọ naa nigba ti Ribadu paṣẹ bẹẹ.
Ọrọ yii gan an lo jẹ ki ajọ DSS fẹsun iwa ọdaran onikoko mẹta kan El-Rufai, ti wọn si gbe e lọ si ile ẹjọ giga apapọ niluu Abuja.
Ajọ DSS ni El-Rufai ti ru ofin to de lilo itakun ayelujara ọdun 2024 ati ofin ibaraẹnisọrọ ọdun 2003.
Awọn ẹsu ti wọn fi kan El-Rufai
- Ẹsun kinni ni pe El-Rufai gba ọna ti ko ba ofin mu lati ti ọwọ bọ foonu Nuhu Ribadu, eyii to lodi si abala 12(1) ofin Naijiria ni ti wọn ṣe atunṣe rẹ lọdun 2024.
- Ẹsun keji ni pe El-Rufua sọ pe oun ṣiṣẹ pẹlu ẹnikan to tọwọ bọ foonu Nuhu Ribadu, eyii to lodi si abala 27(b) ti ofin ori ayelujara ti wọn ṣatunṣe rẹ lọdun 2024.
- Ẹsun kẹta ni pe Mallam Nasir El Rufai lo imọ ẹrọ lati ṣakoba fun araalu ati abo orilẹede Naijiria nipa bo ṣe tọwọ bọ foonu Ribadu, eyii to sọ funra ninu ifọrọwerọ kan lori ẹrọ amohunmaworan Arise lọjọ kẹtala, oṣu Keji, ọdun 2026.
- Wayi o, ṣaaju ipẹjọ yii ni awọn ọtẹmuyẹ DSS ti kọkọ gbiyanju lati fi panpẹ ofin mu afurasi naa ni papakọ ofurufu amọ to kọ jalẹ lati jẹ ki wọn mu oun.
- O sọ ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC lẹyin igbiyannu naa pe niṣe ni ijọba Naijiria n dunkoko mọ oun, eyii ti ko yẹ ko ri bẹẹ labẹ ijọba awarawa.
Ta ni El-Rufai?
Nasiru El-Rufai ni gomina ipinlẹ Kaduna laaarin ọdun 2015 si 2023.
2014 lo kọkọ bori ninu eto idibo abẹle ninu ẹgbẹ APC.
El Rufai ti ṣe minisita eto karakata lẹẹmeji.
O ṣe minisita ilu Abuja lati oṣu Keje 2003 titi de oṣu Karun-un 2007.
2025 to darapọ mọ SDP naa lo tun di ọmọ ẹgbẹ ADC, lati gbe ẹgbẹ ti yoo le Tinubu danu ni 2027 kalẹ.



























