Wo àwọn àìsàn tí o lè kó lásìkò tí o bá ń gé tàbí di irun rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn irun-ori fun awọn obinrin, ati irun-ori fun awọn ọkunrin, jẹ nnkan to ṣe koko - ti a si ka si ohun imọtoto, ilera, ati ibukun ẹwa.
Ni ọsẹsẹ, oṣooṣu, tabi kere ju bẹ lọ, eniyan gbọdọ ni akoko kan to fi ṣe itọju irun rẹ.
Ṣugbọn nigbamiran, ti a ko ba sọ ara wa. Igbesẹ yii le fa akoba nla.
Nitori awọn nnkan ti a n lo fun irun wa wọnyi, ti a ko ba ṣe wọn daada, awọn amoye sọ pe wọn jẹ awọn ọna lati ko tabi pin arun kaakiri.
Ni ọpọlọpọ igba, awọn eeyan ko ki n kọbi ara si ohun ti wọn fi n ba wọ ṣe iru wọn, dipo bẹẹ, ẹwa ti yoo jade ni wọn fẹ ri.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Botilẹjẹpe lode oni, ọpọ irinsẹ igbalode lo ti wa fun itọju irun, ṣugbọn ọpọ wọn lo n pi aarun kaakiri, fun apẹẹrẹ, awọ irinsẹ igbalode bii abẹ.
Ti awọn eeyan to ba n lo irinsẹ igbalode ko be ṣe imọtoto rẹ daada o ṣeeṣe ki wọ ko aarun fun awọn onibara wọn tabi fun ara wọn.
Nigba mii, awọn ipalara kekere to n maa waye nigba ti a ba n ṣe irun ti ọpọ ko si ni mọ jẹ ibi ti arun ma n gba wọle si ara.
Ẹwẹ, awọn amoye ilera sọ pe awọn ọgbẹ kekere wọnyi jẹ awọn ipa-ọna ti awọn arun ma fi n wọ inu ara, paapaa ti ohun elo ko ba mọ.
Ohun to ba ni lẹru ni pe awọn aami aisan ko han lẹsẹkẹsẹ. O ba n bẹrẹ pẹlu ara yuyu, ki ara ma wu ati bẹbẹ lọ, Dokita Sani Abubakar, oniwosan ilera ilera, sọ fun BBC.
Dokita Sani sọ pe "eyikeyi abẹ ti o ba ti kan ara , paapaa ti o ba ṣe eeyan lese, o le fa aisan."
Dokita ṣe akojọ awọn arun ti o le ṣe ni, ti eeyan le lugbadi ni ile iṣeru.
Wo awon aisan to le ko ti o ba lo abẹ to ni kokoro lara

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Hepatitis B
Gẹgẹ bi dokita ṣe ṣalaye, eeyan le ko aarun ẹdọ nipasẹ ẹjẹ.
"Ti a ba lo abẹ ti eeyan kan to ni aarun yii tẹlẹ, o daju pe eeya naa lo ni aisan jẹjẹrẹ naa" Dokita naa so.
- Hepatitis C
Bi Hepatitis B, aisan yii ni eeyan le lugbadi lati ibi ẹjẹ. Dokita ṣalaye siwaju pe ti eeyan ko ba parọ abẹ, tabi ba awọ kokoro to ti le so mọ abẹ, o ṣeeṣe ki eeyan ni aisan naa.
- HIV/AIDS
Botilẹjẹpe o sọ wọn, Dokita Sani o ṣeeṣe ki eeyan ko aarun HIV/AIDS lati bi irinsẹ igbalode ti wọn fi n ge iru lasiko yii.
- Louse
Eyi ni dokita ni o wọpọ laarin awọn ile iṣerun, pẹlu bi wọn se ti n lọ irinsẹ kaa fun ọpọ eeyan. O si tun le ṣe akoba fun awọn ọmọde pẹlu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bawo lo ṣe le dabobo ara rẹ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Nigba gbogbo lo abẹ tuntun tabi abẹfẹlẹ.
- Rii daju pe o nu abẹ to n fi ge irun tabi ko fi sinu omi to ba fẹ.
- Yẹra fun gige irun to ba ti ni ọgbẹ ni ori.
- Ki awọn obi ṣe amojuto ounjẹ ti awọn ọmọde n jẹ, paapaa awọn ọmọbirin.
- Pataki, nini irinsẹ igbaloge to n ge irun eeyan kan ṣe koko, to si le din kiko aarun ku.
























