Adájọ́ sọ Iliasu Ibrahim, Ṣọla Muse àti Adesẹmọwọ Adegogo sí àhámọ́ lórí ẹ̀sùn bí ba ẹ̀gbọ́n Gómìnà Kwara lórúkọ jẹ́

Oríṣun àwòrán, Credit trove
Lórí ẹ̀sùn bí ba ẹ̀gbọ́n Gómìnà lórúkọ jẹ́, ilé ẹjọ́ ju Bàbá àgbàlagbà ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin àti àwọn méjì míì sí àhámọ́ ni Kwara.
Lana Ọjọ Iṣẹgun, Ọjọ Kẹtadinlogun, Osu yii Ile ẹjọ giga Ijọba ipinlẹ Kwara ni ilu Ilọrin, olu ilu ipinlẹ Kwara ti ju awọn mẹta si ahamọ lori ẹsun bi ba ẹgbọn Gomina ipinlẹ Kwara lorukọ jẹ.
Awọn mẹtẹẹta ti ile ẹjọ ju si ahamọ ni, Ọnọrabu Iliasu Ibrahim, Ṣọla Muse ati Adesẹmọwọ Adegogo to jẹ gbajugbaja sọrọsọrọ ori Radio ni ipinlé Kwara.
Adajọ ile ẹjọ giga ipinlẹ yii, Onidajọ Baba Muhammed lo paṣẹ pe ki wọn si wa ni ahamọ.
Ẹsun ti ile ẹjọ fikan wọn ni pe, wọn ba ẹgbọn Gomina ipinlẹ Kwara Dr Abdurazak Alimi lorukọ jẹ lori Radio ati lori ẹrọ ayelujara.
*Kini ohun to ṣẹlẹ tẹlẹ*
Losu kejila ọdun 2025 ni ile ẹjọ giga ipinlẹ Kwara ti ṣaaju fi iwe ipẹjọ ṣọwọ sawọn mẹtẹẹta lori ẹsun pe, wọn ba ẹgbọn Gomina ipinlẹ Kwara Dr Abdulrazaq Alimi ti n ṣe Mutawali ilu Ilọrin lorukọ jẹ.
Ile ẹjọ fẹsun kan awọn eeyan naa pe, wọn lọ ile iṣẹ Radio SBS 96.9FM Ọlọjẹ ni Ilu Ilọrin nibi ti wọn ti ba ẹgbọn Gomina lorukọ jẹ pe, o gba iṣẹ akanṣe ọgọrun un mẹjọ mílíọ̀nù dọla lọdọ aburo rẹ ti ṣe Gomina Abdulrahman Abdulrazaq.
Awọn eeyan naa ko tete yọju si ile ẹjọ lati dahun ẹsun ti wọn fi kan wọn, niwaju ile ẹjọ.
Ẹẹmeji ọtọtọ ni ile ẹjọ ti pasẹ fun wọn lati yọju si Ile ẹjọ ṣugbọn agbẹjọro wọn lo soju wọn ni ile ẹjọ.
Losu Kinni ọdun yii ni ile ẹjọ pasẹ fifi iwe aṣẹ imuni mu wọn ni tipatipa, paapaa ju lọ Ọnọrebu Iliasu Ibrahim to kọ ti ko yọju si ile ẹjọ.
Ile ẹjọ pasẹ pe, wọn gbọdọ farahan ni ile ẹjọ lana ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtadinlogun, osu yii latari bi wọn o ṣe tete yọju si ile ẹjọ lasiko.
*Ki lo ṣẹlẹ ni ile ẹjọ lana*.
Adajọ ile ẹjọ giga ipinlẹ Kwara Onidajọ Baba Muhammed paṣẹ fifi awọn eeyan naa si ahamọ.
Ninu awọn eeyan naa lati ri Baba agbalagba ẹni ọdun mẹtalelọgọrin to je Onorebu Iliasu Ibrahim to ti fi igba kan ri jẹ ọmọ ile aṣofin ipinlẹ Kwara.
Ile ẹjọ pasẹ si sun igbẹjọ siwaju di ọjọ Kẹẹdọgbọn, oṣu keji, ọdun yii fun itẹsiwaju igbẹjọ naa..
























