A lọ ya owó ni Báńkì àti lọ́wọ́ ará ìlú kí a tó rí owó ìtúsílẹ̀ Funke aya Aṣọgbó tí wọn pa ni Kwara san

Oríṣun àwòrán, Others
Funke Ogunrinde, aya Aṣọ́gbó tí agbébọn pa ní Kwara gba ìtúsílẹ̀ lẹ́yìn òbítíbitì owó
Arabinrin Funke Ogunrinde ti awọn agbebọn ji gbe ni ilu Ọba-Isin ni ijọba ibilẹ Isin ni Ipinlẹ Kwara ti gba ominira bayii.
Lọjọru, ọjọ kọkanla, osu Keji, ọdun ti a wa yii ni awọn agbebọn ya wọ ilu Ọba-Isin, ti wọn pa ọkọ arabinrin naa, Raheem Ogunrinde, ki wọn to wa ji iyawo gbe sa lọ.
Isẹlẹ yii lo sọ gbogbo ilu sinu laasigbo ti wọn si n sa kaakiri lati doola iyawo oloogbe naa.
Ṣaaju ni awọn agbebọn naa ti pe, ti wọn si bere fun ọgọrun un milliọnu naira gẹgẹ bii owo itusilẹ, ṣugbọn wọn pada din-in ku si ogoji milliọnu naira nigba ti ipa ilu ko ka iye ti wọn kọkọ bere.
Ǹjẹ́ N40 milliọnu ni ìlú padà san láti dóòlà Funke Ogunrinde?
BBC News Yoruba kan si ọkan lara awọn araalu Ọba Isin to n sa gbogbo ipa lati ri pe arabinrin naa pada sile laaye.
Arakunrin naa to bẹbẹ ki a fi orukọ bo oun lasiri sọ pe, lotitọ lawọn san owo fun awọn ajinigbe ọhun.
"Owo ti a san ko to ogoji miliọnu, N3.5miliọnu naira la san lẹyin ọpọlọpọ ẹjọ ati ẹbẹ.
"Bi a ṣe ri owo naa ko rọrun rara, a lọ ya owo ni banki, A tun ya a kaakiri lọwọ awọn eeyan ko to di pe o pe.
"Iriri to ni agbara ni, A o si gbadura ki eru rẹ waye mọ ninu ilu wa."
"Ohun ti oju mi ri ninu igbo"
Ṣe ni arabinrin naa ṣalaye bi wọn ṣe na oun ati bi wọn ṣe fi iya jẹ oun nigba to wa lakata wọn.
Funke ni ọpọ igba ni wọn maa n na oun nigba ti oun wa ni ibuba wọn.
Ọkunrin to ba BBC sọrọ ni "Koda bi o ṣe wọ inu ilu ni awọn ọmọ rẹ ti wa gbe e kuro niluu fun itọju to peye.
Ọkunrin naa wa rọ ijọba ki wọn pese eto aabo to nipọn ni awọn igberiko ki awọn araalu le maa sun ni ayabalẹ ọkan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Agbébọn ń bèèrè N40m owó ìtúsílẹ̀ fún ìyàwó asọ́gbó tí wọ́n jígbé lẹ́yìn tí wọ́n pa ọkọ rẹ̀ ní Kwara
Awọn agbebọn ti wọn pa ẹṣọ aṣogbo ni ilu Oba-Isin, nipinlẹ Kwara ti wọn si ji iyawo rẹ gbe lọ lẹyin eyi ti n beere fun owo ti ko din ni ogoji miliọnu naira (N40m) bayii gẹgẹ bii owo itusilẹ obinrin naa.
Tẹ o ba gbagbe, irọlẹ Ọjọru, ọjọ kọkanla osu Keji ọdun 2026 yii ni awọn agbebọn ya wọ ilu Oba Isin, nijoba ibilẹ Isin, ti wọn si ko araalu sinu ipayinkeke.
Ikọlu ti wọn se si ilu yii lọjọ naa lo yọri si bi wọn ṣe pa ẹsọ asọgbo kan, Raheem Ogunrinde, wọn si ji iyawo rẹ, Funkẹ Ogunrinde gbe sa lọ.
Lẹyin rẹ lo di pe awọn araalu Oba Isin bẹrẹ si i fi ilu silẹ, wọn n sa lọ sawọn ilu to wa lagbegbe, nitori Ibẹrubojo.
Kí ni aráàlú sọ?
Lonii ọjọ Ẹti, ọjọ kẹtala, oṣu Keji odun 2026 yii, BBC News Yoruba kan si ọkan lara awọn ẹsọ alaabo ilu naa, lati mọ ibi ti nnkan de duro.
Ẹsọ alaabo naa to bẹbẹ pe ka ma darukọ oun nitori aabo rẹ, sọ pe awọn ajinigbe naa ti pe awọn.
"Wọn ti pe, wọn beere fun owo itusilẹ N100m, sugbọn a bẹ wọn pe a ko ni owo to to bẹẹ yẹn lọwọ.
"Wọn tun pe pada ni aarọ oni to jẹ ọjọ kẹtala osu Keji, ọdun ti a wa yii, wọn ni awọn ti din-in ku si N40 million.
"Wọn ni ti a ba fẹ ri Funkẹ Ogunrinde laaye, a gbọdọ tete san N40 million.
"Owo ni a n wa kiri bayii o, ki Olorun saanu fun wa.''
Arakunrin naa fi kun ọrọ rẹ pe awọn ti awọn jẹ fijilante nikan lawọn ku niluu bayii, o ni awọn fọn ara awọn sinu ilu lati daabo bo awọn eneyan.
Bakan naa lo ni awọn ko ri awọn ọmọ ogun tabi ẹṣọ alaabo kankan.
Àwọn agbébọn tún kọ lu Ọba-Isin ni Kwara, pa ẹ̀sọ́ asọ́gbó kan, jí ìyàwó rẹ̀ gbé lọ
Ohun ibanujẹ nla lo jẹ fun awọn ara ilu Ọba-Isin ni ijọba ibilẹ Isin ni Ipinlẹ Kwara lori bi awọn agbebọn ṣe tun ṣekọlu si ilu naa, ti wọn si tun pa ẹsọ asọgbo kan tiise Raheem Ogunrinde ti ọpọ mọ si Baba Ibeji
Lẹyin ti wọn pa Ogunrinde tan, ṣe ni wọn tun ji iyawo rẹ gbe sa lọ inu igbo.
Lọjọru ọjọ kọkanla, osu keji ọdun ti a wa yii ni iṣẹlẹ laabi to sọ awọn araalu ọun si siba-sibo waye.
Àlàyéé lórí bí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀ún ṣe wáyé
BBC News Yoruba ba araalu Ọba-Isin kan to ni ki a ma darukọ oun nitori aabo ara rẹ sọrọ lori ago, o si salaye lori bíi iṣẹlẹ naa se waye.
Ọkunrin naa sọ pe, awọn ọrẹ mẹrin to fi mọ oloogbe Ogunrinde ni wọn jọ joko niwaju ile tẹ, ti wọn n jiroro.
"Akoko naa jẹ nnkan bi aago meje alẹ, lojiji ni awọn onisẹ ibi yii ṣẹ yọ wọn sins ibọn bolẹ.
"Lẹyin naa ni wọn doju kọ Ogunrinde, wọn si dabọn boo.
"Bi wọn ṣe paa tan ni wọn gbe iyawo rẹ, sa wọ inu igbo lọ.
"Ohun ti o yanilẹnu ni pe, Ogunrinde nikan ni wọn pa.
"O da bii pe Ogunrinde ga-an ni wọn diidi wa pa nitori pe, lẹhin rẹ, wọn pa ẹnikankan mọ.
"Emi woye pe wọn ṣe eyi nitori pe, o jẹ akinkanju ẹsọ asọgbo, wọn si tete mu un kuro lọnaa, ko ma baa di wọn lọwọ isẹ wọn.
A kan si alukoro ileesẹ ọlọpaa ni Kwara, Ejire-Adeyemi Adetoun, sugbọn ko tii fesi titi igba ti a ko iroyin yii jọ.
Ẹ̀ẹkejì lèyí tí wọn yóò pa ẹ̀sọ́ asọ́gbó láàárín ọjọ́ márùn-ún - Ìwádìí
Eleyi lo jẹ ẹẹkeji ti awọn agbebọn yoo seku pa ẹsọ asọgbo laaarin ọjọ marun-un.
Tẹ o ba gbagbe, ni ọjọ Aiku, ọjọ kẹjọ, osu keji ọdun yii, awọn agbebọn sekọlu si ilu Koro nijọba ibilẹ Ekiti ni Ipinlẹ Kwara bakan naa, wọn si pa ẹsọ asọgbo kan.



























