Ọkúnrin tó sọ ara rẹ̀ di obìnrin ni afurasí tó pa èèyàn mẹ́sàn-án ní Canada -Ọlọ́pàá kéde

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin ikọlu ibọn yinyin to pa eeyan mẹsan-an, ti mẹẹẹdọgbọn (25) si farapa ni British Columbia lorilẹede Canada lanaa Ọjọru, awọn ọlọpaa ilẹ naa ti fi orukọ ẹni to yinbọn ọhun lede.
Ẹni ọdun mejidinlogun (18) ni wọn pe ẹni naa, orukọ rẹ ti wọn si fi lede ni Jesse Van Rootselaar.
Tẹ o ba gbagbe, Rootselaar paapaa ku ninu ikọlu naa, wọn ni oun lo yinbọn mọ ara rẹ, amọ ko sẹni to mọ ohun to de to fi ṣe ikọlu yii.
Ninu alaye ọlọpaa nipa afurasi yii ni wọn ti sọ pe ìbí ọkunrin ni wọn bi i, amọ Van Rootselaar maa n pe ara rẹ ni obinrin.
"Mo le sọ pe wọn bi Jesse bii ọkunrin, ṣugbọn ni nnkan bii ọdun mẹfa ṣẹyin, o bẹrẹ igbesẹ sisọ ara rẹ di obinrin."
Dwayne McDonald, Igbakeji kọmiṣanna fun ileeṣẹ ọlọpaa Royal Canadian Mounted Police (RCMP) lo sọ bẹẹ.
Ile kan to wa nitosi lo ni o ti bẹrẹ ibọn yinyin naa, ko too pada sile ẹkọ Tumbler Ridge to ti rọjo ibọn si i.
Nipa awọn to lugbadi ibọn naa, olukọ-obinrin kan ti ọjọ ori rẹ jẹ mọkandinlogoji (39), akẹkọọ-binrin mẹta ti ọjọ ori wọn jẹ mejila ati akẹkọọ ọkunrin meji ti wọn jẹ ọmọ ọdun mejila ati mẹtala ni wọn pe e.
Gẹgẹ bi awọn alaṣẹ agbegbe naa ṣe wi, wọn ni awọn ko gbagbọ pe awọn ẹlomi-in tun wa ninu ikọlu yii.
"A ti de ile mọlẹbi afurasi naa lọpọ igba''
Alaye awọn ọlọpaa RCMP siwaju ni pe awọn ti kan si mọlẹbi Van Rootselaar lọpọ igba tẹlẹ.
Wọn ni o si ni i ṣe pẹlu iṣẹ ọpọlọ rẹ.
Wọn fi kun un pe awọn mọ afurasi Van Rootselaar, awọn si ti bẹrẹ igbesẹ lati kan si awọn eleto ilera lati mọ ohun to le ṣẹlẹ nipa ilera rẹ, gẹgẹ bi David Eby, Olootu British Columbia ṣe sọ lọjọ iṣẹlẹ naa.
Afurasi naa ni iwe aṣẹ ibọn yinyin, sugbọn o ti lejọ tipẹ, gẹgẹ bi McDonald ṣe sọ.
Bakan naa ni awọn ọlọpaa sọ pe Van Rootselaar ti fopin si ẹkọ rẹ nile ẹkọ Tumbler Ridge Secondary School lati ọdun mẹrin sẹyin, lai jẹ pe o pari ẹkọ rẹ nibẹ.
Awọn iṣẹlẹ ibọn yinyin to ti waye ni Canada ri
Ọkan lara awọn iṣẹlẹ ibọn yinyin to buru ju to waye ni Canada ri ni ti ọdun 2020.
Agbebọn kan deede bẹrẹ si I yinbọn, o si pa eeyan mejilelogun (22).
Iṣẹlẹ naa waye lagbegbe Nova Scotia.
Agbébọn yìnbọn pa èèyàn mẹ́sàn-án nílé ẹ̀kọ́ ní Canada, 25 farapa

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ko din ni eeyan mẹsan-an to ti di oloogbe bayii, ti mẹẹẹdọgbọn mi-in si tun fara gba ọta ibọn lasiko ti ẹnikan bẹrẹ si i yinbọn nile ẹkọ ati nile kan ni British Columbia, Iwọ -Oorun orilẹede Canada.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, oku mẹfa ni wọn ri nile ẹkọ ti iṣẹlẹ naa ti waye ti i ṣe Tumbler Ridge Secondary School, ẹni keje ku lasiko ti wọn n gbe e lọ sile iwosan.
Bakan naa ni wọn tun ri oku eeyan meji mi-in nile kan to wa nitosi.
Eyi ni awọn ọlọpaa fi ni awọn gbagbọ pe ibọn yinyin to pa awọn eeyan yii jọ pe wọn jọra wọn, bo tilẹ jẹ pe wọn ko le fidi rẹ mulẹ.
Nipa afurasi ti wọn lo yinbọn ọhun, wọn ri oku rẹ naa pẹlu àpá ti wọn ni oun lo da a sira ẹ lara ninu ile ẹkọ yii.
Awọn alaṣẹ sọ pe awọn mọ ẹni to ṣekọlu naa, amọ wọn ko ti i kede orukọ tabi boya ọkunrin ni tabi obinrin.
Amọ ṣaaju ni ikede kan ti ṣapejuwe ẹni naa bii obinrin kan to wọ kaba, ti irun rẹ si pupa.
Wọn ko ti I kede awọn eeyan ti ikọlu naa kan, bẹẹ ni a ko le sọ boya onka awon to di oloogbe yoo ṣi lekun si i.
Ṣugbọn awọn ọlọpaa sọ pe awọn yoo maa tẹsiwaju lati wo awọn ile to wa nitosi ikọlu naa wo.
"A ki i tilẹkun wa nibi, ikọlu yii ya wa lẹnu gan-an''

Kansilọ agbegbe naa, Chris Norbury, sọ fun BBC pe ikọlu yii ya oun lẹnu gan-an.
O ni awọn eeyan agbegbe Tumbler Ridge ki I tilẹkun, nitori aabo wa fun wọn.
"A ki I tilẹkun wa nibi, agbegbe ti aabo to peye wa ni. A ki I daamu ọkan wa rara lori iwa ọdaran nibi.
"A ni mọto ọlọpaa mẹta niluu wa, agbegbe wa kere gan-an. A da ara wa mọ, a si mọ awọn ti ikọlu yii kan. Ọrẹ wa ni wọn, ati awọn ọmọ ọrẹ wa.
"O ṣe ni laanu gan-an, ọfọ nla leyi."
Bẹẹ ni Chris Norbury wi.
Olootu ijọba Canada, Mark Carney, ṣapejuwe iṣẹlẹ yii bii eyi to bani lọkan jẹ.
Bakan naa ni Olootu British Columbia; David Eby, sọ pe bi awọn agbofinro ṣe tete dide si ikọlu naa lo dena rẹ ti ko fi buru ju bẹẹ lọ.
Akẹkọọ kan nile ẹkọ Tumbler Ridge, sọ fun ẹka iroyin CBC pe, tabili ni oun atawọn akẹgbẹ oun fi di ẹnu ọna pa lasiko ti ojo ibọn naa n rọ.
Titipa ni wọn yoo ṣi ti ile ẹkọ naa fun asiko yii bi wọn ṣe wi.
Bawo lo ṣe ṣẹlẹ?
Ni nnkan bii aago mẹsan-an kọja ogun iṣẹju ni awọn ọlọpaa gba ipe, pe ẹnikan n yinbọn lakọlakọ nile ẹkọ Tumbler Ridge Secondary School, British Columbia, ni Canada.
Akẹkọọ kan ṣalaye pe oun deede bẹrẹ si i gbọ iro kan to n dun bii aago nigba toun de yara ikawe, ti aago naa n sọ pe kawọn ti ilẹkun pa, pe wọn fẹ ti ile ẹkọ naa.
Laaarin iṣẹju meji, ọlọpaa de sile ẹkọ naa, gẹgẹ bi Nina Krieger, Minisita fun aabo awujọ ni British Columbia ṣe wi.
Lẹyin rẹ ni awọn ọlọpaa Royal Canadian Mounted Police. (RCMP) fi atẹjiṣẹ to n ta awọn eeyan lolobo ranṣẹ sori foonu, wọn ni obinrin ni ẹni to n ṣekọlu naa, o si ni irun pupa.
Nigba to tun ti ṣe diẹ ni wọn pa atẹjiṣẹ naa rẹ, nigba ti wọn ni ko ti I si afurasi gboogi kan.
Ọga ọlọpaa RCMP, Ken Floyd, pada sọ pe eeyan mẹwaa lo ti ku latari ikọlu ọhun, ti a ba ka ẹni to yinbọn naa mọ.
O ni eeyan 25 lo si ti farapa.
Floyd tun fidi ẹ mulẹ, pe aaye meji ọtọọtọ ni ibọn yinyin naa ti waye, ati pe oku eeyan meji ni wọn ri nile kan to wa nitosi.


























