Èèwọ̀ ni fún ẹnikẹ́ni láti daran jẹko ní ìta gbangba nílẹ̀ Ibadan - Olubadan

Olubadan ilẹ̀ Ibadan, Oba Ladoja wọ agbádá, kó ìlẹ̀kẹ̀ sọ́rùn, ó ń rẹ́rìn-ín sí ẹ̀rọ ayàwòrán

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Olubadan ti ilẹ̀ Ibadan, Oba Rashidi Ladoja ti kọminú lórí bí àwọn darandaran ṣe ń da ẹran jẹko ní ìta gbangba káàkiri ìlú Ibadan.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ Olubadan, Olóyè Ayoade Olugbemiga fi léde sọ pé Olubadan fi àìdunnú rẹ̀ hàn lórí dída ẹran ní ìta gbangba níbi ìpàdé ìgbìmọ̀ àwọn aláṣẹ ìlú Ibadan àtàwọn ẹgbẹ́ Ijaye Farm Settlers Association tó wáyé ní ààfin Olubadan, Oke-Aremo lọ́jọ́ Ajé.

Olubadan sọ níbi ìpàdé náà pé yàtọ̀ sí pé ohun tó lòdì sófin ìpínlẹ̀ Oyo ni dída ẹran ní ìta gbangba, ó fi kun pé ó lòdì sófin ìlú Ibadan.

Ó wà ṣèkìlọ̀ fáwọn darandaran káàkiri ìpínlẹ̀ náà láti jáwọ́ nínú dída ẹran jẹko ní ìta gbangba tí wọn kò bá fẹ́ kojú ìgbẹ́jọ́ ilé ẹjọ́.

Ó fi kun pé ẹnikẹ́ni tí ọwọ́ bá tẹ̀ ni wọ́n máa fi kélé òfin gbé, tí wọ́n sì máa fojú winá òfin.

"A ò ní káwọ́ lẹ́rán káwọn Fulani darandaran máa pa àwọn àgbẹ̀, àwọn ọmọdé, kí wọ́n máa fi tipátipá bá àwọn obìnrin lájọṣepọ̀, kí wọ́n sì máa ba oko tó jẹ́ ohun táwọn èèyàn fi ń jẹun jẹ́."

Oba Ladoja tún rán àwọn Mọ́gàjí, Baálẹ̀ àtàwọn olóyè àdúgbò kọ̀ọ̀kan létí láti wà ní ojú lalákàn fi ń ṣọ́rí, kí wọ́n ṣe àmójútó ètò ààbò tó péye ní agbègbè kóówá wọn lójúnà àti dá ààbò ẹ̀mí àti dúkìá àwọn èèyàn wọn.

Bákan náà ló rọ àwọn aráàlú láti tètè máa fi tó àwọn agbófinró létí nígbà tí wọ́n bá kẹ́fín tàbí gbúròó pé àwọn Fulani darandaran, àwọn ajínigbé tàbí àwọn ọ̀daràn ní agbègbè wọn.

Ṣáájú ni alága Ijaye Farm Settlers Association, Pásítọ̀ David Olatunji ti kọminú lórí bí àwọn Fulani darandaran ṣe ń ṣèkọlù, tí wọ́n sì ń pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn, ba ọ̀pọ̀ èrè oko jẹ́.

Ó ní gbogbo ìgbìyànjú àwọn láti dá ààbò bo oko àtàwọn èrè oko ló ń já sí pàbó nítorí ọwọ́ kò tẹ ẹnikẹ́ni lára àwọn oníṣẹ́ ibi náà pẹ̀lú gbogbo bí wọ́n ṣe ń lọ fi ẹjọ́ wọn sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá tó.

Pásítọ̀ Olatunji wá rọ Olubadan àti ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo láti dá ààbò bo àwọn àgbl lọ́wọ́ ìkọlù gbogbo ìgbà náà.

Àwọn àgbààgbà olóyè ìlú Ibadan ló kópa níbi ìpàdé náà.