Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin gba ìlànà lílo ẹ̀rọ àti fífi ẹnu kéde èsì ìdìbò lẹ́yìn ìfẹ̀hónúhàn ọmọ Naijiria

Oríṣun àwòrán, Nigerian Senate
Ile igbimọ aṣofin agba ti orilẹede Naijiria ti gba lati ṣe atunṣe lori ipe awọn araalu, ti wọn si ti gba ilana lilo ẹrọ ayelujara ati fifi ẹnu kede esi idibo to n bọ.
Awọn aṣofin kede eyi lẹyin ọpọ wakati ti wọn fi jokoo pajawiri lọjọ Iṣẹgun,
Lasiko ijokoo, Aarẹ ile igbimọ aṣofin, Godswill Akpabio fọwọ si ipe Sẹnetọ Tahir Mungono to pe fun lilo ẹrọ fun esi idibo ni ibudo eto idibo.
Labẹ ofin tuntun yi, lilo ẹrọ yoo jẹ ohun akọkọ ti ajọ eleto idibo yoo ma lo ṣugbọ wọn yoo ni anfani lati lo ọna miiran ti oju opo ayelujara be ṣe ṣegeṣege lasiko eto idibo.
Eyi fa ọpọ ariyanjiyan ati ipinya ni ijoko ile, ti Sẹnetọ Enyinnaya Abaribe si pe fun ibo ni ile igbimọ aṣofin ṣugbọn o pada wọgile.
Lẹyin eyi ni ile igbimọ aṣofin fẹnuko, ti wọn si yan igbimọ ẹlẹni mejila pe ki wọn ṣe iwadii lori ohun to yatọ ninu ofin eto idibo ati eyi ti ile igbimọ aṣoju-sofin.
Aarẹ ile igbimọ palaṣẹ fun igbimọ naa pe ki wọn bẹrẹ iṣẹ kiakia.
O ni wọn yoo fun Aarẹ Bola Tinubu ni esi iwadii ati ohun ti wọn fẹnuko si ninu oṣu keji.
Awọn igbimọ ẹlẹni mejila ree
- Sẹnetọ Simon Bako Lalong – Alaga
- Sẹnetọ Mohammed Tahir Monguno – Ọmọ Ẹgbẹ
- Sẹnetọ Adamu Aliero – Ọmọ Ẹgbẹ
- Sẹnetọ Orji Uzor Kalu – Ọmọ Ẹgbẹ
- Sẹnetọ Abba Moro – Ọmọ Ẹgbẹ
- Sẹnetọ Asuquo Ekpenyong – Ọmọ Ẹgbẹ
- Sẹnetọ Aminu Iya Abbas – Ọmọ Ẹgbẹ
- Sẹnetọ Tokunbo Abiru – Ọmọ Ẹgbẹ
- Sẹnetọ Niyi Adegbonmire (SAN) – Ọmọ Ẹgbẹ
- Sẹnetọ Jibrin Isah – Ọmọ Ẹgbẹ
- Sẹnetọ Ipalibo Banigo – Ọmọ Ẹgbẹ
- Sẹnetọ Onyekachi Nwebonyi – Ọmọ Ẹgbẹ
Iṣẹ wo gan an ni lilo ẹrọ ayelujara real-time electronic n ṣe lasiko eto idibo?
Lilo ẹrọ Real time electronic fun eto idibo tumọ si pe fifi esi ibo lati ibudo idibo, eyi ti wọn ti ṣe akọsilẹ sinu iwe Form EC8A ransẹ lati ori ayelujara si oju opo INEC (IReV) lẹsẹkẹsẹ ti idibo ba ti pari, ti wọn si ti ka gbogbo ibo tan, ti awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo si ti kede ẹni to bori ibo ni ibudo kọọkan.
Eyi tumọ si pe ko ni si anfani lati yi esi ibo ni ibudọ kankan, iye ibo ti wọn ba ṣe akọsilẹ rẹ ni wọn yoo fi ransẹ si oju opo ayelujara INEC ṣaaju ki wọn to gbe iwe ti wọn fi ṣe akọsilẹ lọ ọfisi INEC.
Igbesẹ yii yoo waye ni iwaju awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu, awọn oludibo to wa ni ibudo eto idibo.
Ilé Igbìmọ Aṣofin Naijiria bẹ̀rẹ̀ ìpádé pàjáwìrì lórí ìyìpadà òfin ètò ìdìbò 2027

Awọn ọmọ ile Igbimọ Asofin agba ni Abuja ti bẹrẹ ipade pajawiri nile igbimọ asofin ni Abuja lori ọrọ igbesẹ eto idibo ti awon eeyan n ṣe iwọde le lori.eyi waye saaju
Wọn ni koko ipade naa ni lati ṣatunṣe si awọn abadofin eto idibo ni eyi ti awọn kan ti yari fun wọn pe ki wọn buwọlu lilo ẹrọ ayarabiasa kọmputa lati fi geb esi idibo jade bi wọn se n kaa tan lọdun 2027.
Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti fariga pe awọn ko fara mọ ọrọ Godswill Akpabio to jẹ Adari ile igbimọ aṣofin ni Naijiria to ti sọ pe wọn ko ni le lo awọn ẹrọ kọmputa lati maa gbe esi idibo jade ni wọọdu kọọkan bi wọn ba ṣe n ka a tan nitori pe ko si ayelujara to ja geere ni awọn ilu, ileto, abule kọọkan ni ipinlẹ mẹsan an ni Naijiria.
Lọjọ ru to kọja ni awọn ile igbimọ ti sun ipade wọn siwaju ni Abuja titi di ọsẹ meji siwaju sii ṣugbọn wọn nilati ṣe ipade pajawiri loni bayii nitori awuyewuye to n lọ lọwọ nigboro to si ti fa iwọde bayii ni Abuja.
Emmanuel Odo to jẹ akowe agba ile igbimọ aṣofin lo buwolu iwe ipade pajawiri naa bayii.
Koko ti wọn fẹ gbe yẹwo ni ti ori ọrọ gbigbe esi idibo jade ni ọdun 2027 ni kete ti wọn ba ti ka a tan nipa lilo ẹrọ ayarabiaṣa kọmputa.
Iwode n tẹsiwjau loni ọjọ keji ni Abuja
Iwode to bẹrẹ ni ana, ọjọ Aje, ọjọ kẹsana n, osu keji, ọdun 2026 lori ọrọ owo ori ni Naijiria ati aifẹlo ẹrọ kọmputa fi geb esi eto idibo jade n tẹsiwaju loni ni ile igbimọ asofin nilu abuja .
Oni lo pe ọjọ keji ti iwọde yii ti bẹrẹ bayii.
Peter Obi to dije dupo aarẹ lọdun 2023 pẹlu Bola Tinubu naa ti yọju sibi iwọde naa pe oun naa faramọ iwọde ohun.
O ni oun naa fẹ ki wọn maa gbe esi dibo jade bo ba ṣe ka a tan ni a\won ibudo idibo ni nipa lilo ẹ\ro kọmputa ayelujara.
'A maá lo ẹ̀rọ ayélujára fún èsì ìdìbò, ẹ má jà wá lólè'
Awọn olufẹhonuhan ti wọn pejọ si Ile igbimọ aṣofin agba orilẹede Naijiria ti ke gbajare si awọn asofin to wa niluu Abuja pe ki wọn faye gba gbigbe esi idibo sori ayelujara lorilẹ-ede Naijiria.
Bakan naa ni wọn ṣalaye pe lati wọọdu ni ki wọn ti ma gbe esi ibo si ori ẹrọ ayelujara.
Iwọde ọhun to waye niluu Abuja, ni ọpọ awọn ẹgbẹ korawọnjọ si, ti wọn si wọde lọ si iwaju ile igbimọ aṣofin lọjọ Aje.
Ṣaaju ni ile igbimọ asofin ti sọ pe ajọ eleto idibo iyen Independent National Electoral Commission (INEC) lo le sọrọ lori gbigbe esi idibo sita, ti wọn yoo si gbe esi ibo sita lọna to ba rọrun fun wọn.
Awọn ọmọ ẹgbẹ to ba awọn akọroyin sọrọ ṣalaye pe awọn olufẹhonuhan ko ni erongba lati wọle sinu gbọngan ile igbimọ aṣofin, to si jẹ ita ile igbimọ aṣofin ni wọn gbero lati ṣe ẹhonu wọn, to si jẹ ibẹ ni wọ ti ṣe.
Awọn oluwọde bẹrẹ iwọde lati ileeṣẹ ijọba, ti wọn si morile ẹnu abawọle ile igbimọ aṣofin.
Olujide sipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi darapọ awọn oluwọde naa.
Obi, ẹni to ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC), ni ile igbimọ aṣofin gbọdọ ri daju pe irufẹ aṣise to waye lasiko eto idibo ọdun 2023 ko tun gbọdọ waye lasiko eto idibo to n bọ.
Ìfẹ̀hónúhàn bẹ̀rẹ̀ l'Abuja lórí bí ilé aṣòfin àgbà ṣe fagilé lilo ẹ̀rọ kọ̀mpútà fún èsì ìdìbò àti lórí òfin owó ori tuntun

Agbarijọpọ ẹgbẹ alatako bẹrẹ ifẹhonuhan lonii niluu Abuja tako bi ile aṣofin agba ṣe wọgile lilo ẹrọ kọmputa fun akojọpọ ati ikede esi idibo lọsẹ to kọja.
Ifẹhonuhan ọhun tun da lori ofin owo ori tuntun to ti gberasọ lati ọjọ kinni oṣu Kinni ọdun 2026 yii.
Awọn oluwọde naa ti wọn ti kepe ọpọ eeyan lati darapọ mọ wọn peju si iwaju ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja lati aidiunnu wọn han.
Awọn ẹgbẹ alatako atawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ fẹsun kan ile igbimọ aṣofin agba wi pe wọn o fẹ ki eto ijọba awarawa dagba pẹlu bi wọn fagile lilo ẹrọ kọmputa fun akojọpọ ati ikede esi idibo lẹsẹ kẹsẹ ni Naijiria.
Awuyewuye bẹrẹ nigba ti awọn aṣofin fagile lilo ẹrọ kọmputa fun akojọpọ ati ikede esi idibo lẹsẹ kẹsẹ lati awọn ibudo idibo lọ sori ẹrọ IRev ti gbogbo eeyan yoo ti maa ri i.
Ọpọ eeyan ti sọ pe atunṣe ofin eto idibo ti awọn aṣofin ṣe naa yoo faye gbe eeru to ti n ṣẹlẹ tipẹ tipẹ ninu eto idibo Naijiria si i.
Awọn alatako ti ṣapejuwe igbesẹ awọn sẹnẹtọ gẹgẹ bii eyi ti ko ni jẹ ki araalu ni igboya ninu wọn tabi jẹri wọn.
Wọn ni ọna lati jẹ ki eeru tawọn oloṣelu ti n ṣe tipẹ tipẹ ninu eto idibo Naijiria tẹsiwaju ni awọn aṣofin n wa pẹlu atunṣe ti wọn ṣe.
Ọpọ eeyan lo ti n kọminu pe ifẹhonuhan naa le ran de awọn ipinlẹ mii kaakiri Naijiria
Bo tilẹ jẹ pe awọn oluwọde naa peju siwaju ile aṣofin agba l'Abuja, ọpọ eeyan lo ti n kọminu pe ifẹhonuhan naa le ran de awọn ipinlẹ mii kaakiri orilẹede Naijiria.
Nnkan ti ọpọ ẹgbẹ alatako n sọ ni pe lilo ẹrọ kọmputa fun akojọpọ ati ikede esi idibo lo le wa ojutuu si gbogbo kudiẹ-kudiẹ to maa n jẹyọ ninu esi idibo ni orilẹede Naijiria.
Awọn ẹgbẹ alatako ni nnkan tawọn ile igbimọ aṣofin ṣe tumọ si pe wọn ṣe ikọlu si ijọba awarawa.
Apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC naa ti sọ pe awọn yoo gunle iyanṣẹlodi ti ile aṣofin agba ko ba yi ipinnu wọn pada lori bi wọn ti fagile lilo ẹrọ kọmputa fun akojọpọ ati fifi esi idibo ranṣẹ si ori atẹ IRev ti gbogbo eeyan yoo ti maa ri.
Wọn ni ko si bi eto idibo ṣe maa lọ daadaa lai si eeru lai lo ẹrọ kọmputa fun akojọpọ esi idibo lẹsẹ kẹsẹ.
Lilo ẹrọ kọmputa fun akojọpọ esi idibo ko ni fawọn to ba fẹ yi esi idibo laye lati ṣe nnkan ti wọn ba fẹ ṣe
Ajọ eleto idibo INEC ti lo ẹrọ komputa ri ninu eto idibo Naijiria, amọ, kudiẹ-kudiẹ saba maa n wa nibẹ.
Ẹwẹ, ọpọ eeyan naa ti sọ pe lilo ẹrọ kọmputa fun akojọpọ esi idibo le ma kẹsẹjari tori awọn ipinlẹ kan wa ti awọn ẹrọ kọmputa ko ti ni ṣiṣẹ daadaa.
Ile aṣofin agba naa ti pe ipade pajawiri eyi ti yoo waye lọjọ kẹwaa oṣu Kinni yii, lẹyin ti ọpọ eeyan bu ẹnu ẹtẹ lu bi ile aṣofin ṣe fagile lilo ẹrọ kọmputa fun akojọpọ esi ibo ni Naijiria.



























