Bí a ṣe máa kojú ìṣòro ààbò - Kókó ohun tí Tinubu sọ níbi àpérò ìgbìmọ̀ alásẹ

Tinubu wọ aṣọ olómi aro, ó wọ ìgò ojú, gbohùngbohùn wà níwájú rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Tinubu ti kéde pé orílẹ̀ èdè Nàìjíríà máa borí ìgbéṣùmọ̀mí àtàwọn agbébọn, bí ó ṣe ní ìpèníjà ètò ààbò tó ń wáyé lọ́wọ́ yìí kìí ṣe ohun tó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà.

Tinubu sọ èyí níbi àpérò ìgbìmọ̀ aláṣẹ lórí ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà, National Economic Council, NEC, tó wáyé lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹsàn-án, oṣù Kejì, ọdún 2026.

Ààrẹ sọ àrídájú rẹ̀ fáwọn ọmọ Nàìjíríà pé ìṣèjọba òun ń sa gbogbo ipá láti ri pé ètò ààbò tó péye padà sípò ní gbogbo àwọn agbègbè tí ètò ààbò ti mẹ́hẹ.

Ó sọ pé gbogbo èèyàn ni ìpeníjà ààbò ń kọ lóminú ṣùgbọ́n ó sọ àrídájú rẹ̀ pé àwọn máa borí ìpèníjà náà.

Tinubu sọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí àwọn afurasí Boko Haram ṣèkọlù sí ìlú Woro, ìjọba ìbílẹ̀ Kaiama ní ìpínlẹ̀ Kwara níbi tí wọ́n ti pa èèyàn tó lé ní àádọ́rin.

Láìpẹ̀ yìí ni Nàìjíríà ti ń kojú ìkọlù àwọn agbéṣùmọ̀mí ní ẹkùn ààrin gbùngbùn àríwá Nàìjíríà.

Láti bíi ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn ni àwọn agbébọn àti agbéṣùmọ̀mí Boko Haram ti ń ṣèkọlù ní ẹkùn ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn àríwá Nàìjíríà ṣùgbọ́n wọ́n ti ń tàn káàkiri Nàìjíríà tó fi mọ́ ìpínlẹ̀ Kwara àti Niger níbi tí ìkọlù ti ń wáyé lọ́kan-ò-jọ̀kan.

Ààrẹ júwe ìkọlù ìpèníjà ààbò náà bí ohun tó ń ṣe ìfàsẹ́yìn fún ọrọ̀ ajé àti pé gbogbo èèyàn gbọdọ̀ fọwọ́sowọ́pọ̀ láti wá ojútùú sí ìṣòro yìí.

Ìpàdé àpérò yìí jẹ́ àpérò ọlọ́jọ́ méjì èyí tí igbákejì ààrẹ, Kashim Shettima, àwọn gómìnà, àwọn aṣòfin àtàwọn olórí lẹ́ka aládàni péjú síbẹ̀.

Ètò ọrọ̀ ajé

Ààrẹ Tinubu tún sọ pé gbogbo àwọn ètò tí wọ́n gbé kalẹ̀ láti fi mú àtúntò bá ètò ọrọ̀ ajé ti ń so èso rere, bí ètò ọrọ̀ ajé ṣe ti ń bọ̀ sípò padà.

"Mo fẹ́ ṣe ìtẹnumọ́ rẹ̀ pé àwọn àtúntò tí ìṣèjọba wat g ń gùnlé ti ń so èso rere, tí wọ́n sì ti ń rí èrè rẹ̀ káàkiri gbogbo àgbáyé."

Ó kan sáárá sí ilé ìfowópamọ́ àgbà Nàìjíríà lábẹ́ gómìnà Yemi Cardoso fún mímú ìrúgọ́gọ́ bá owó náírà

Ó sọ pé ìṣèjọba ohun mú ìdàgbàsókè àwọn ohun amáyédẹrùn ní òkúnkúndùn káàkiri ètò ìrìnnà, ohun àmúṣagbára, ibùgbé, àtàwọn ẹ̀ka míì.

Bákan náà ló fi kun pé àwọn ètò láti fi mú ìrúgọ́gọ́ bá àwọn ètò tí yóò mú ìgbéga bá ìgbáayé àwọn èèyàn.

Tinubu tún wòye pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ tó wà níwájú àwọn lágbára díẹ̀ síbẹ̀ kìí ṣe ohun tí wọn kò lè kojú.

Ó fi ìgboyà hàn pé ìfẹnukò tó bá wáyé níbi àpérò náà yóò so èso rere pàápàá lẹ́ka ètò ọ̀gbìn.