Ṣọ́ọ̀ṣì tó bá ṣe ìsìn kọ́ja aago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́ yóò fojú winá òfin- ìjọba Kogi kìlọ̀ nítorí ìkọlù agbébọn

Aworan ọkunrin kan to wọ aṣọ adura, to n rin lọ ninu ile ijọsin ti wọn jo nina

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Iṣu atẹnumọrọ ki i jona ni ijọba ipinlẹ Kogi n fi aabo ṣe bayii, pẹlu bi wọn ṣe ṣẹṣẹ tun kilọ fun awọn ṣọọṣi niluu naa lati maa pari isin gbogbo si aago mẹrin irọlẹ, ki wọn dẹkun isin ọwọ oru.

Gẹgẹ bi Kọmiṣanna eto iroyin ni Kogi, Kingsley Femi Fanwo, ṣe wi, ikilọ yii n waye lati dena ikọlu awon agbebọn fun awon olujọsin lasiko ti wọn ba n ṣe isin to pẹ ju lọwọ.

O ni iwadii fi han pe awọn agbebọn n gbero ikọlu ni Kogi.

Koda, awọn ile ijọsin to ba ṣesin kọja aago mẹrin irọlẹ yoo foju wina ofin bi wọn ṣe sọ.

Ikilọ yii lo n waye lẹyin ti ikọlu kan ti awọn agbebọn gbero rẹ si ṣọọṣi kan nijọba ibilẹ Ijumu, foriṣanpọn.

Ikọ alaabo lo di wọn lọwọ ikọlu naa nibuba wọn nigba ti awọn ẹṣọ naa yi ibẹ po lọpọ yanturu ti wọn si ko awọn nnkan ija wọn lọ, gẹgẹ bi Fanwo ṣe fidi ẹ mulẹ.

Ninu atẹjade ti Fanwo fi sita l'Ọjọru lo ti ṣalaye ikọlu ti wọn fẹẹ ṣe si ṣọọṣi naa ti ko pada bọ si i.

O ni ọrọ ti awọn agbebọn naa ba ara wọn sọ fi han pe wọn mọ pe ṣọọṣi naa ṣi n ṣe isin alẹ mọ oru, to le jẹ ki wọn wọle si wọn lara lojiji.

Fanwo sọ pe niṣe ni awon agbebọn naa n leri pe awọm yoo ri obitibiti owo gba bawọn ba ji awọn eeyan gbe ni ṣọọṣi naa, eyi ti i ṣe owo itusilẹ wọn.

" A ti ri i pe pẹlu gbogbo ikilọ ti a n sẹ, awọn ṣọọṣi kan ṣi n ṣe isin di oru. A ko fi aaye gba eyi pẹlu iṣoro aabo to n koju wa lọwọ."

Fanwo lo sọ bẹẹ.

"Ko si ṣọọṣi to gbọdọ ṣe isin kọja aago mẹrin irọlẹ mọ"

Ko si ṣọọṣi to gbọdọ ṣe isin kọja aago mẹrin irọlẹ mọ bi ijọba Kogi ṣe wi, awọn ti wọn ba si wa ninu igbo gbọdọ wa ṣọọṣi wọn sibomi-in ni.

Kọmiṣanna naa kilọ pe ṣọọṣi yowu to ba tapa si ofin yii, yoo jiya ofin , nitori ewu ni won fi n wu awọn olujọsin.

"A ko fi ipinnu yii dojusọ ẹsin kankan"

O fi kun un pe igbesẹ aabo to ṣe koko ni lati da aabo bo ẹmi, ki I ṣe pe ijọba n doju sọ ẹsin kankan.

"Erongba wa ni lati dena iwa ọdaran, ki i ṣe ka maa sa kaba-kaba kiri lati gba awọn ti won ba ji gbe silẹ."

Bakan naa lo ni igbesẹ yii ko tumọ si pe ojo ni ijọba ipinlẹ Kogi, mọja-mọsa la n mọ Akin logun ni.

Fanwo ni ijọba Kogi n da oju koju iṣoro aabo bo ti tọ, awọn si n ṣe aṣeyọri lorii rẹ, ki gbogbo ẹ le daa nijọba n ṣe.

O rọ awọn olori ẹsin lati fọwọsowọpọ pẹlu awon ẹṣo eleto aabo, pẹlu idaniloju pe aabo ẹmi ati dukia yoo maa wa fun araalu.

Ìjọba Kogi ti ọjà àti ibùdọ́kọ̀ pa láti lé agbébọn jáde

Aworan ibudokọ ti ko si eeyan ati ọkọ pupọ nibẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lojuna ati so okun aabo le ju ti tẹlẹ lọ, ijọba ipinlẹ Kogi ti paṣẹ pe kawọn ọja ati ibudọkọ kan wa ni titipa fun asiko diẹ naa, lati le awọn agbesunmọmi, agbebọn ati bẹẹ bẹẹ lọ to ba n fara ṣoko jade.

Atẹjade ti Kọmiṣanna fun iroyin nipinlẹ Kogi, Kingsley Fanwo, fi lede lanaa ọjọ kẹjọ, oṣu Keji ọdun 2026 yii lo kede bẹẹ.

Gẹgẹ bi atẹjade naa ti ẹka iroyin Punch Metro fi royin igbesẹ yii ṣe wi, awon apa ibi kan nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Kogi ati agbegbe rẹ ni titipa naa yoo kan.

O kede pe igbesẹ yii n waye lati dena awọn oniṣẹ ibi ki wọn ma le raye wọle, ra ounjẹ tabi gba iranlọwọ nipa lilọ bibọ lọwọ awọn to n ṣe agbodegba fun wọn.

Atẹjade naa fi kun un pe ọfiisi Oludamọran pataki fun eto aabo ni Naijiria (Office of the National Security Adviser) mọ si igbesẹ yii, bẹẹ ni ko ṣẹyin awọn olori ẹka aabo ipinlẹ Kogi.

"Titipa fun asiko diẹ yii wa lati dena awọn ọdaran ki wọn ma wọle, ki wọn ma si ri awọn nnkan eelo lo bi eto naa ṣe n lọ."

Bẹẹ ni Kọmiṣanna eto iroyin ipinlẹ Kogi wi.

Awọn agbegbe wo ni titipa ọja ati gareeji naa yoo kan?

Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, ijọba ibilẹ meje ni titi ọja ati gareeji pa naa yoo kan.

Ni Lokoja ti I ṣe olu ilu Kogi, awọn ibi ti won ni yoo kan ni:

Ọja ati ibudokọ Oshokoshoko, Jakura, Ogbagbon, Agbaja, Atsawa, Obajana, Apata, Abugi, Amomi, Ebee ati Budon.

Nijọba ibilẹ Kabba-Bunu, yoo kan Ike Bunu, Aba Marian (Isado), Ofere, Abaa Dola (Ihale Bunu), Aiyede, Oke Offin, Aiyegunle Bunu, Okebukun, Odo Ape Bunu, Agbadu Bunu ati Agbede Apa Bunu.

Ni ijọba ibilẹ Iwọ-OorunYagba, yoo kan Okoloke, Isanlu Esa, Okunran, Ogbe, Ejiba, Odo Eri, Igbaruku, Iyamerin, Ogga, Omi, Odo Ara ati Oke Ere.

Ni Ila-Oorun Yagba, yoo kan Irunda Ile, Iyeh Ilotin, Gada, Odogbe ati Ilafin.

Nijọba ibilẹ Kogi, yoo kan ọja irẹsi to wa ni Adingere, Koton Karfe, Okpareke ati Girinya; ọja ila to wa ni Opanda ati ọja nnkan jijẹ to wa ni Edeha.

Awọn ọja ati gareeji Otafun Amuro, Oroke Amuro, Takete Ide Amuro, Okeagi, Illai, Ilemo ati Ijagbe nijọba ibilẹ Mopamuro naa fara gba a.

Ni ijọba ibilẹ Ijumu, yoo kan Ayegunle Gbedde, Iyah Gbedde, Ayetoro Gbedde, Ayeh Gbedde, Iluhagba, Odokoro ati Okoro.

Nigba ti wọn n ṣalaye igbesẹ yii siwaju, ijọba Kogi sọ pe ki I

ṣe pe awọn ọja ati gareeji naa yoo wa ni titipa titi aye, bi ko ṣe pe wọn yoo di ṣiṣi pada lẹyin eto aabo ti ijọba n so okun rẹ le dan-in-dan-in.

Tẹ o ba gbagbe, ọkan lara awọn agbegbe tawọn agbebọn ti n ṣoro lorilẹede Naijiria ni ipinlẹ Kogi pẹlu, ọlọkan-o-jọkan ikọlu lo si ti waye nibẹ ri.

Kí ló dé tí ìjọba ìpínlẹ̀ Kogi fi ti gbogbo ilé ẹ̀kọ́ pa fún ọ̀ṣẹ̀ méjì?

Aworan Gomina ipinlẹ Kogi, Usman Ahmed Ododo

Oríṣun àwòrán, ipinlẹ Kogi

Ijọba ipinlẹ Kogi ti palaṣẹ pe ki gbogbo ile ẹkọ to w ani ipinlẹ naa jẹ titi pa lẹyin ti wọn gba ipe lori aabo.

Kọmisana fun eto iroyin nipinlẹ naa, Kingsley Fanwo lo kede igbesẹ naa lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ ni olu ilu ipinlẹ naa, Lokoja.

Fanwo ṣalaye pe igbesẹ yii da lori pe ẹtọ ijọba ni pe ki wọn da aabo bo awọn akẹkọọ ati olukọ lọwọ ikọku .

"A ko gbe igbesẹ nitori pe a jẹ ojo ṣugbọn tori pe ojuṣe wa ni,: Fanwo sọ. " A pinnu lati gbe igbesẹ yii nitori o ṣe koko ki a wa ọna lati ri pe iṣẹlẹ buruku ko waye."

O ni Gomina Ahmed Ododo ti sọ fun gbogbo awon ileeṣẹ ijọba ti ọrọ kan lati ṣe ohun to yẹ lati ma jẹ ki igbesẹ naa da eto ẹkọ run aa.

"Gomina Ahmed Ododo ti palaṣẹ pe ki awọn ileeṣẹ ijọba gbe igbesẹ lati ri pe eto ẹkọ pada ni asiko to yẹ," Fanwo ṣalaye.

Ki ni idi ti ijọba fi gbe igbesẹ yii?

Kọmisana ni idi pataki ti ijọba fi gbe igbesẹ yii lo da lori iroyin ti awọn eleto aabo fi ransẹ si ijọba.

Fanwo tẹsiwaju pe awọn eleto aabo ti n gbe igbesẹ lati ṣawari awọn ọdaran to fẹ da laafia ilu naa lamu.

O fikun, " Aabo awọn ọmọ wa, awọn olukọ ati ile ẹkọ wa jẹ wa logun pupọ. Ijọba to wa lode yii kudun dida aabo ẹmi ati dukia lọpọlọpọ."

Bakan naa ni ijọba tun rọ awọn ile ẹkọ aladani pe ki wọn tẹle aṣẹ ijọba ipinlẹ Kogi.

Alaga fun awọn ile ẹkọ aladani nipinlẹ Kogi, Reuben Jimoh, ti wa palaṣẹ fun awọn ile ẹkọ aladani pe ki awọn naa ṣe atunsẹ to yẹ.

"Isinmi aarẹ fun awọn ile ẹkọ ni yoo tete waye ti a o si pada si ile ẹkọ ni Ọjọ kẹrindinlogun oṣu keji ọdun 2026," Jimoh sọ ninu atẹjisẹ to fi ransẹ si awọn oludasilẹ ile ẹkọ aladani.